Beard Woman: Irungbọ̀n mi máa ń dójú tì mí láti jáde lọ ra nǹkan ní ọ̀sán gangan

Aworan Theresia Mumbi

Njẹ ẹyin ti ni iriri eleyi ti awọn agbofinro sọ pe ki ẹ bọra silẹ lati le e ri aridaju pe lootọ obinrin ni yin?

Obinrin kan to n se kọndọ lẹyin ọkọ lorilẹede Kenya to si ni irungbọn bi ọkunrin, ti n sọ ohun ti oju rẹ ri lọwọ awọn ọlọpaa.

Theresia Mumbi sọ fun BBC pe, awọn ọlọpaa to n dari ọkọ ni Nairobi mu oun, ti wọn si ni ki oun bọra silẹ ki awọn ba le mọ boya lootọ obinrin loun.

Theresia ni wọn fi oun si ahamọ pẹlu awọn obinrin miran.

''Awọn ọlọpaa meji wa, ti wọn si ni ki n bọ aṣọ mi. Lẹyin igba naa ni wọn yẹ ara mi wo finifini. Mi o mọ nkan ti wọn ri ṣugban wọn ni ki n pada si ahamọ''.

Àkọlé fídíò, Mothers day: Lẹ́yìn Olorun, Ìyá mi ló kù- Papa Ajasco, Abiodun Ayeyinka

O ṣalaye pe, n ṣe ni oun maa n ranti iṣẹlẹ naa to waye ni ọdun 2018 lori pe wọn fẹ ri iwe ẹri oun.

O ni oun fi iwe han wọn, ti wọn si ni ki oun maa lọ.

Iriri yii lo mu ki arabinrin Mumbi di agbẹnusọ ati ajafẹtọ fawọn obinrin, ti wọn ko foju jọ obinrin tabi ti wọn ni aleebu lara.

Àkọlé fídíò, Wo àwọn ohun tí BBC fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nípa ohun tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ IPOB ń gbé sorí ayélujára

O ni oun n sọ iriri oun lati pe kiyesi awọn eeyan si ohun to n ṣẹlẹ, ati ki awọn obinrin miran ba le sọrọ sita lori ohun ti wọn koju nigba ti wọn ba dunkoko ma wọn.

Ayẹwọ awọn dokita lo ṣafihan pe, arabinrin Mumbi ni awọn eroja ara homoonu kan lara rẹ, eyi to mu ko ni irungbọn bi ọkunrin.

O ni oun a ma saba fa irungbọn yii, to si maa n mu ki ara maa ja oun jẹ.

''Ni nkan bi ọdun melo kan sẹyin, mo nilati pa asa fifa irungbọn mi ti, nitori pe o ma n yun mi, ti awọn oju irun ti mo fa a si ma di egbo''

Àkọlé fídíò, Alaafin stool: Wo ẹni tó ṣeẹṣe pé kí Aláàfin kàn lẹ́yìn ìpapòdà Oba Lamidi Adeyemi

Irungbọn naa bẹrẹ si ni hu, ti eleyi si mu ko maa le jade lọsan lati lọ ra nkan, bi kii ṣe lalẹ.

O ni nigba ti atijẹ atimu fẹ ma nira loun ba bẹrẹ si ni ṣe iṣẹ kọndọ.

Àkọlé fídíò, Èmi nìkan ni ikú Alaafin dùn jù ní gbogbo ayé yìí torí èmi nìkàn ṣoṣo ni mo mọ̀ ǹkan ... - Baba Kekere

Nibi iṣẹ rẹ lo ti ṣalabapade awọn obinrin mii, tawọn naa n koju iru ipenija yii, to si ma n gba wọn niyanju.

O jẹ ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ obinrin to ni irungbọn ni Kenya, ti wọn a si ma ba awọn obinrin sọrọ nibi ipade wọn.

Àkọlé fídíò, Ó gbé owó fún mi, ó tún ra fóònù ńlá fún mi - Bàbá Onílù Ibadan sọ bó ṣe pàde Àgùnbánirọ̀ tó dáa lọ́lá