Blasphemy Deborah Killed: A ṣe lòdì sí bí wọ́n ṣe pa Deborah ní Sokoto nítorí pé wọ́n ni ó sọ̀rọ̀ lódì sí Anabi Muhammed- ẹgbẹ́ Musulumi

Deborah Samuel

Oríṣun àwòrán, other

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Àwọn ènìyàn faraya lórí ìṣekúpani Deborah lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sín ní Sokoto

Lẹ́yin ti awọn akẹkọọ akẹgbẹ Deborah to n kẹkọ nile ẹkọ ikọni niṣẹ olukọ ni Sokoto dana sun tan ni ero awọn ọmọ Naijiria ti ṣotọọtọ lori ikọlu naa.

Ọpọlópó lo bu ẹni ẹtẹ lu iwa ika ti awọn ọdọ naa hu nitori pe wọn ni pe Deborah sọrọ to lodi si Anabi Muhammed ni wọn ba na an, ti wón si sọ okuta lu u pa, ti wọn si dana sun un titi to fi ku ninu ọgba ileẹkọ wọn ni ipinlẹ Sokoto ni ariwa Naijiria.

Lara awọn to ti tabuku iwa ipa yii ni ẹgbẹ akọroyin fun Musulumi ni Naijiria.

Wọn ṣapejuwe iwa naa ni eyi to buru jai ti ko si yẹ ọmọluwabi rara.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Bakan naa ni wọn kesi ijóba Naijria lati da seria to yẹ fun awọn to n kigbe Allahu Akbar ti wọn si n pa ọmọnikeji wọn gẹgẹ bi oju wọn ṣe hande ninu fọnran fidio to gba ori ay=elujara kan naa.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Àkọlé fídíò, Wo àwọn ohun tí BBC fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nípa ohun tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ IPOB ń gbé sorí ayélujára

Mr Macaroni, Serap, Oby Ezekwesili, Amnesty International faraya lórí Deborah tí wọ́n pa ní Sokoto lórí ẹ̀sùn pé ó sọ̀rọ̀ lódì sí Ànọ́bì

Ori ẹrọ ayelujara ni Naijiria n gbona janyin-janyin ni lẹyin iṣekupani akẹkọbinrin, Deborah Samuel ni ileẹkọ Shehu Shagari College of Education lori ẹsun pe o sọ ọrọ odi si ẹsin Islam.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni arabinrin naa tabuku orukọ adari ẹsin Islam.

Nitori naa ni awọn akẹẹkọ kan ni ileẹkọ naa wa wọ jade ninu yara igbele ni ileẹkọ to wa, ti wọn si bẹrẹ si ni ju okuta lu, ti wọn si n naa pẹlu igi.

Lẹyin naa ni wọn pa a ti wọn si dana sun ara rẹ.

Awọn wo lo ti sọrọsoke lori iku Deborah?

Lara awọn eniyan to fesi si iṣẹlẹ naa lori ayelujara ni gbajugbaja adẹrinpoṣonu, Mr Macaroni to ni iwa iṣekupani naa burujai, ti ko si yẹ ko ṣẹlẹ ni awujọ eniyan.

Mr Macaroni kesi ijọba lati ji kuro ninu oorun wọn nitori bi wọn ṣe n dakẹ si ohun gbogbo lai jẹ ki idajọ ododo leke lo fa iru iṣẹlẹ naa.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Àkọlé fídíò, Iyabo Anisulowo:Ẹ̀yin ọ̀dọ́ Nàìjíríà, ẹ má bínú, kò rọrùn fún ọ̀dọ́ láti dìde nínú ìṣèlú

Bakan naa lo kesi gomina ipinlẹ Sokoto lati sọrọ soke lori iṣẹlẹ naa nitori ki awọn eniyan le ni igbagbọ ninu rẹ saaju idibo ọdun to n bọ.

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

Ajọ Ajafẹtọ ọmọniyan SERAP naa kesi Aarẹ Buhari pe ko polongo ni gbangba pe nkan ti awọn apaniyan naa ṣe ko dara

Ko si ri pe gbogbo awọn to lọwọ ninu iṣẹlẹ naa lo foju wina ofin nitori ipaniyan nitori ẹsin buru jai lorilẹede Naijiria to si tapa si ẹtọ ọmọniyan.

Skip X post, 5
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 5

Oby Ezekwesili ninu ọrọ tirẹ ni gbogbo awọn alaṣẹ ileẹkọ ni wọn ni ẹjọ lati ro nitori kini wọn n wo ti awọn akẹkọọ ṣe lu, ti wọn si dana sun akẹkọọ, ti ko si si ẹnikẹni to ri nkan ṣe si titi doju iku.

Ezekwesili ni awọn wọnyii ni ẹjọ lati dahun titi idajọ otitọ yoo fi jọba lori iṣẹlẹ naa.

Skip X post, 6
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 6

Bakan naa ni Ajọ Amnesty International bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa, ti wọn si kesi ijọba Naijiria lati ri pe ipaniyan bi iru eyi dopin ni Naijiria.

Skip X post, 7
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 7

Awọn ajafẹtọ miran to tun fi ero wọn han da ẹbi ru awọn alaṣẹ ileẹkọ to n wo lai ṣe ohunkohun lasiko ti wọn fi pa akẹkọọ naa.

Skip X post, 8
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 8

Àkọlé fídíò, 'Mo fara da ìsòro gan láwùjọ́ torí àwọn òbí mi di létí'
Skip X post, 9
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 9

Shehu Sanni naa ti sọrọ soke lori iṣẹlẹ naa, o gbe iṣẹ le awọn oṣiṣẹ eleto aabo Sokoto lọwọ pe iwadii to munadoko lo ku lasiko yii.

Àkọlé fídíò, 'Ọ̀gá ni ooru Nàìjíríà lẹ́gbẹ́ orílẹ̀èdè ti mo ti wálé; Bí mo ṣe parí iṣẹ́ 'AC' tó ń ló iná òòrùn rèé'
Skip X post, 10
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 10

Awọn miran tun woye pe eto ẹkọ paapaa eto idajọ ni Naijiria ti bajẹ patapata ki iru iṣẹlẹ yii fi le waye ni ọgba ileẹkọ.

Skip X post, 11
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 11

Ni bayii, ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ti fi panpẹ ọba mu eniyan meji ti wọn fi ẹsun kan pe o lọwọ si iṣẹlẹ naa, to si wa nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.

aworan Deborah Samuel ati abawọle ile ẹkọ rẹ

Oríṣun àwòrán, other

Ohun tí a mọ̀ nìyí nípa bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣe sọ̀kò pa Deborah ní Sokoto, wọ́n ní ó 'sọ̀rọ̀ òdì sí Ànọ́bì Muhammed'

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sọ̀kò pa Deborah ní Sokoto, wọ́n ní ó 'sọ̀rọ̀ òdì sí Ànọ́bì Muhammed', ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ méjì

Ko tii si ẹni lee sọ ni pato, ohun to wa ninu akasilẹ ohun naa, ọrọ nipa iṣẹlẹ yii si ti di eyi ti wọn n gba bi ẹni gba igba ọti.

Àkọlé fídíò, Èmi nìkan ni ikú Alaafin dùn jù ní gbogbo ayé yìí torí èmi nìkàn ṣoṣo ni mo mọ̀ ǹkan ... - Baba Kekere

Ijọba ipinlẹ Sokoto ti gbe ileẹkọ ẹkọṣẹ olukọ, Shehu Shagari College of Education to wa nilu Sokoto ti pa lẹyin ti awọn awọn akẹkọọ kan pa akẹkọọbinrin kan nileẹkọ naa lọjọbọ.

Deborah Samuel jẹ ọkan lara awọn akẹkọọ ileẹkọ ẹkọṣẹ olukọ naa, ipele keji lo ṣi wa; ṣugbọn lọjọbọ lawọn akẹgbẹ rẹ gbẹmi rẹ lọgba ileẹkọ naa.

Awọn akẹgbẹ rẹ ni o sọrọ odi si Muhammed to jẹ aṣiwaju ẹsin Islam.

Obitibiti agbofinro lo ti wa kaakiri ileẹkọ naa bayii, ti awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa si ti ni ki gbogbo awọn akẹkọọ o gba ile obi wọn lọ.

Akọroyin kan ni ilu Sokoto ṣalaye fun BBC pe wahala naa bẹ silẹ lẹyin ti akasilẹ ohun kan ti Deborah ṣe bọ si oju opo ajumọni Whatsapp group kan.

"Akasilẹ ohun yii ti wọn ni o 'sọrọ odi'si aṣiwaju ẹsin Islam lo wa lu sita"

Ko tii si ẹni lee sọ ni pato, ohun to wa ninu akasilẹ ohun naa, ọrọ nipa iṣẹlẹ yii si ti di eyi ti wọn n gba bi ẹni gba igba ọti.

A

Oríṣun àwòrán, Others

Bawo ni iṣẹlẹ yii ṣe ṣẹlẹ gan?

Ohun ti akọroyin to fi ilu Sokoto ṣe ibudo ṣalaye fun BBC ni pe ni nnkan bii agogo mẹsan owurọ ni wahala naa bẹrẹ lẹyin ti wọn ni ọkan lara awọn akẹkọbinrin ile ẹkọ naasọ̀rọ alufansa si aṣiwaju ẹsin Islam.

Eyi lo gbodi lọkan awọn akẹkọọ kan nibẹ ti wọn fi wọ ọ jade nileegbe awọn akẹkọọ to wa ti wọn si bẹrẹ si nii sọ ọ lokuta, igi atawọn nnkan ọṣẹ miran titi ti ẹmi fi bọ lara rẹ.

Lẹyin ti wọn paa tan ni wọn da ina sun oku rẹ.

Àkọlé fídíò, 'Ọ̀gá ni ooru Nàìjíríà lẹ́gbẹ́ orílẹ̀èdè ti mo ti wálé; Bí mo ṣe parí iṣẹ́ 'AC' tó ń ló iná òòrùn rèé'

Akọroyin yii ti orukọ rẹ njẹ Abubakar Imam, ni oju opo abanidọrẹ Whatsapp ni ikanni alajumọ ni Whatsapp group kan ti awọn akẹkọọ ile ẹkọ naa gbe kalẹ lati maa fi ọrọ jomitoto ọrọ lori eto ẹkọ wọn ni iṣẹlẹ naa ti ṣẹ.

"Wọn ni akẹkọọ kan gbe ọrọ kan kalẹ to nii ṣe pẹlu ẹsin loju ikanni naa."

"Ohun to sọ yii ni akẹkọọbinrin yii wa fesi si, ninu ọrọ rẹ lo ti wa sọ awọn ọrọ kan tawọn akẹkọọ kanfoju wo gẹgẹ bi ọrọ odi si aṣiwaju ẹsin wọn."

Atẹjade Sultan

Oríṣun àwòrán, other

Ki ni Sultan sọ lori iṣẹlẹ naa?

Igbimọ to n ba Sultan ilu Sokoto jiroro ti a mọ si Sultane council ti bu ẹnu atẹ lu bi awọn akẹkọọ kan ṣe pa Debora.

Igbimọ naa wa rọ awọn agbofinro pe ki wọn ṣiṣẹ wọn bi iṣẹ lati lee ri pe awọn to wa nidi iṣẹlẹ naa fi imu kata ofin.

Wọn ni ohun ti ko bojumu patapata gba a ni, ti wọn si n ke sawọn olugbe ilu ati ipinlẹ Sokoto lati gba alaafia laaye.

Sultan ilu Sokoto, Saád Abubakar ni pipa ti wọn pa akẹkọọ naa jẹ iyalẹnu gba a.

Atẹjade ile ẹkọ Shehu Shagari pẹlu atẹjade ijọba ipinlẹ Sokoto

Oríṣun àwòrán, other

Gbogbo akẹkọọ gbọdọ fi ọgba ile ẹkọ naa silẹ lẹyẹ o ṣọka - Ijọba ipinlẹ Sokoto

Gomina ipinlẹ Sokoto, Aminu Tambuwal ti paṣẹ ki wọn ti ile ẹkọ ẹkọṣẹ olukọni Shehu Shagari College of Education naa pa

Gomina Tambuwal si tun pa a laṣẹ l'Ọjọbọ pe ki ileeṣẹ ijọba to n mojuto ọrọ ile ẹkọ giga nipinlẹ naa o tete bẹrẹ iwadii ni kanmọkanmọ lori bi wọn ṣe ṣeku pa Deborah.

Bakan naa ni gomina ipinlẹ Sokoto tun ke si gbogbo awọn ileeṣẹ agbofinro gbogbo lati ṣewadii iku rẹ ki wọn si tete jabọ fun ijọba nibẹ.

Àkọlé fídíò, Osun spider man: Mo ń ṣe ìtanijí láti gbógunti ìdọ̀tí láwùjọ ló sún mi dé ìdí 'Spider man'

Ọwọ ti tẹ afurasi meji ni awọn to ṣeku pa Deborah Samuel?

Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Sokoto fi sita, wọn ni awọn ti bẹrẹ si ni ṣe iwadii iku Deborah Samuel ati pe ọwọ ti tẹ afurasi meji ninu wọn.

Atẹjade naa ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Sokoto, ASP Sanusi Abubakar fọwọ si lorukọ kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ naa Kamaldeen Kọla Okunlọla, ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ti gbe igbesẹ lati rii pe abo to peye wa lagbegbe naa ti awọn si n ṣe iwadi to yẹ.

Atẹjade Ẹniọwọ Kukah

Oríṣun àwòrán, Twitter / father Kukah

Bi wọn ṣe pa Deborah kii ṣe ọrọ ẹsin, iwa buruku ni, awọn to ṣee si gbọdọ rugi oyin- Farger Matthew Kukah, CAN

Ninu atẹjade kan to fi sita lori rẹ, olori ijọ Aguda lẹkun Sokoto, Ẹniọwọ Matthew Hassan Kukah ti sọrọ.

O ni ojuṣe kan ṣoṣo ti orilẹede Naijiria jẹ Deborah Samuel, awọn ẹni rẹ atawọn akẹkọọ to ku nile ẹkọ naa ni lati rii daju pe gbogbo awọn to mọ si iku rẹ ko lọ laijiya.

Àkọlé fídíò, Babalawo, Ọ̀pẹ̀lẹ̀ ni wọ́n fi ń yan Ọba fún wa, kí ló dé tẹ́ẹ fẹ́ wo owó yan Soun fún wa? - Ọmọ ìdílé òyè l'Ogbomoso

"Eyi ko lohunkohun ṣe pẹlu ẹsin, awọn Kristẹni atawọn musulumi alabagbe wọn ti n gbe ni irẹpọ fun igba pipẹ ni ipinlẹ Sokoto. Nitori naa, oju iwa ọdaran ni a gbọdọ fi wo ọrọ yii, ofin si gbọdọ ṣiṣẹ."

Bakan naa ni ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin kristi, Can nipinlẹ naa ke si awọn kristẹni ni Sokoto ati lagbaye lati wolẹ adura fun Deborah ki Ọlọrun tẹẹ si afẹfẹ rere.