PDP zoning: Ìgbákejì akọ̀wé ìkéde fún PDP sọ pé ẹkùn mẹ́fẹ́ẹ̀fà Naijiria ló ní ẹ̀tọ́ láti jẹ́ olùdíje ẹgbẹ́ fún ipò ààrẹ̀

Oríṣun àwòrán, KOLA OLOGBODIYAN / FACEBOOK
Lati Ọjọru ti ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, ti kede pe oun ko ni yan oludije kankan ni pọsin, ni awuyewuye ti n waye.
Ṣugbọn ninu ọrọ to ba BBC sọ, Ibrahim Abdullahi, to jẹ igbakeji akọwe ikede fun PDP, sọ pe ẹgbẹ gbe igbesẹ naa nitori pe dọgba-dọgba ni gbogbo ọmọ ẹgbẹ.
O ni lasiko ipade kan pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ naa ni Ila oorun Gusu, ni awọn ẹya Igbo ti beere fun pe ki ipo oludije fun ipo aarẹ bọ sọwọ wọn.
Ọgbẹni Abdullahi sọ pe amọ awọn ọmọ igbimọ oludari ẹgbẹ kọ̀, pẹlu alaye pe ẹkùn mẹfa lo wa ni orilẹ-ede Naijiria, gbogbo wọn lo si ni ẹtọ lati fa oludije kalẹ.
"Alaga ẹgbẹ wa nigba kan, Okwesilieze Nwodo, sọ pe lootọ ni awọn ẹya Igbo ṣatilẹyin fun ẹgbẹ, amọ ẹya naa lo yẹ ki anfaani lati dupo aarẹ bọ si lọwọ.
"To si bẹbẹ pe ki ẹgbẹ yọnda tikẹẹti fun wọn."
- Kìí ṣe àwọn mínísítà tó fẹ́ dupò nìkan ní Buhari ní kó fi iṣẹ́ sílẹ̀ , wo àwọn tó tún kàn
- Ọ̀rọ̀ pátà dídọ̀tí tún rúná sí ìjà láàrin Nkechi Blessing àti ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ tẹ́lẹ̀, Falegan
- Ṣé lóòtọ́ ni Jonathan ti gbẹ̀yìn darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ APC? Nkan tí PDP àti APC sọ rèé
- Wo àwọn mínísítà ìjọba Nàìjíríà tó ti kọ̀wé fipò sílẹ̀ nítorí àṣẹ Ààrẹ Buhari
- Ṣé lóòtọ́ ní Makinde gbà tíkẹ̀ẹ̀tì Sẹ́nétọ̀ lọ́wọ́ Kola Balogun fún Joseph Tegbe?
- ASUU Strike 2022: Ìjíròrò lórí ìyanṣẹ́lódì ASUU ń tẹ̀síwájú lónìí pẹ̀lú ìjọba àpapọ̀
- Mọ̀ síi nípa IPOB tó ń gbé orí ayélujára dá rúgúdú sílẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ Biafra
Abdullahi sọ pe nkan to ṣoro lati ṣe fun igbimọ alamojuto ẹgbẹ ni nkan ti Nwodo beere fun, nitori pe gbogbo ẹgbẹ ti fẹnuko pe wọn ko ni yọ ẹkun kankan silẹ.
O ni amọ o ṣe e ṣe lọjọ iwaju, ṣaaju ki idibo to waye, ti ẹgbẹ ba woye pe ki awọn eeyan kan jawọ ninu idije fun ẹnikan.
"Amọ, eyi yoo jẹ nkan ti gbogbo awọn oludije fi ara mọ."
O salaye pe lilo ẹya tabi ẹkun ti eeyan ti wa, lati fun wọn ni tikẹẹti oludije, ko si ninu ofin ati ilana ẹgbẹ oṣelu PDP.
"Bi eeyan ba ṣe gbajumọ si, lowo lọwọ, ati ifọwọ si gbogbo ẹgbẹ, la n lo."
- Kìí ṣe àwọn mínísítà tó fẹ́ dupò nìkan ní Buhari ní kó fi iṣẹ́ sílẹ̀ , wo àwọn tó tún kàn
- Ọ̀rọ̀ pátà dídọ̀tí tún rúná sí ìjà láàrin Nkechi Blessing àti ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ tẹ́lẹ̀, Falegan
- Èèyàn 60 l'erin ti pa láàrín ọdún yìí nìkan lórílẹ̀èdè Zimbabwe
- Ẹ má torí ìyansẹ́lódì ASUU dá ètò òṣèlú rú- Ààrẹ ilé aṣòfin àgbà sì ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ NANS
- Ọwọ́ tẹ afurasí ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ní ilé ìtura, wo nǹkan tí ọlọ́pàá ká mọ lọ́wọ́
- Ẹ múra o, ọ̀wọ́n gógó bẹntiró ń rúgbó bọ̀- IPMAN ṣèkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Nàìjíríà
- Ṣé lóòtọ́ ní Makinde gbà tíkẹ̀ẹ̀tì Sẹ́nétọ̀ lọ́wọ́ Kola Balogun fún Joseph Tegbe?
O ni ọna ti ẹgbẹ naa yoo fi yọ Naijiria kuro ni inu wahala ti ẹgbẹ oṣelu APC ju u si, lo n bi gbogbo igbesẹ ti awọn n gbe lati yan ẹni ti yoo dije fun ipo aarẹ.
Ọjọru ni awọn alaṣẹ ẹgbẹ PDP kede pe awọn ko ni lo ilana 'zoning' lati yan oludije sipo aarẹ.

Oríṣun àwòrán, Pdp/ twitter
PDP ṣílẹ̀kùn ìdíje fún ipò ààrẹ gbayawu, Ó ní ẹnikẹ́ni tó bá nífẹ́ síi lè díje
Ẹgbẹ oṣelu PDP ni Naijiria ti wọgile lilo eto jẹ ki n jẹ lati fi yan oludije fun ipo aarẹ labẹ aṣia rẹ ju danu.
Igbimọ iṣakoso to ga julọ lẹgbẹ oṣelu PDP gbe igbesẹ yii nibi ipade rẹ ẹlẹkẹrindinlọgọrun iru ẹ to waye ni olu ileeṣẹ ẹgbẹ oṣelu naa ni ojule Wadata Plaza nilu Abuja; lẹyin to ṣe agbeyẹwo abajade igbimọ ti wọn gbe kalẹ lori ọrọ eto jẹ ki n jẹ lẹgbẹ oṣelu naa.
- Àwọn olùfẹ̀hónúhàn dáná sun dúkìá bí ìwọ́de ṣe ń le si
- Ọwọ́ tẹ afurasí ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ní ilé ìtura, wo nǹkan tí ọlọ́pàá ká mọ lọ́wọ́
- Àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga gbogbonìṣe Poly ní Nàìjíríà , ASUP bẹ́rẹ́ ìyanṣẹ́lódì, wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀
- Ẹ má torí ìyansẹ́lódì ASUU dá ètò òṣèlú rú- Ààrẹ ilé aṣòfin àgbà sì ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ NANS
- Buhari kò ní fi oṣù mẹ́fà kún ìjọba rẹ̀ bí àwọn kan ṣe ń bèrè - Ìjọba àpapọ̀̀̀
- Ṣé lóòtọ́ ni Jonathan ti gbẹ̀yìn darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ APC? Nkan tí PDP àti APC sọ rèé
- Wo àwọn tó ra fọ́ọ̀mù ipò Ààrẹ ẹgbẹ́ òṣèlú APC
Gẹgẹ bi alaye ti alukoro apapọ ẹgbẹ oṣelu PDP, Debọ Ologunagba ṣe, igbimọ alakoso to ga julọ ti fọwọ si ṣiṣi ilẹkun idije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu naa silẹ gbaragada.
Bakan naa lo tun ọ ọ siwaju pe ẹgbẹ oṣelu naa n sa ipa lati rii pe oludije alafẹnuko, ti oyinbo n pe ni "Consensus candidate" ni wọn yan dipo didibo.
O ni igbimọ akoso naa tun ti yan aarẹ tẹlẹ fun ile aṣofin agba Naijiria, Sẹnetọ David Mark lati jẹ alaga ipade itagbangba lati yan oludije ipo aarẹ wọn.
Ki lawọn ohun ti igbimọ akoso to ga julọ ni PDP gbe yẹwo fi pinnu ?
"Igbimọ alakoso NEC gba amọran igbimọ ti wọn gbe kalẹ lori ilana jẹ ki n jẹ lẹgbẹ oṣelu naa wọle pe nitori ilana apapro kan ko ga jukan lọ, ki ẹgbẹ oṣelu naa o fọgbọn ṣe e lori ọrọ ilana jẹ ki n jẹ o ko ma baa fa wahala lẹyin o rẹyin."
Bakan naa ni wọn tun kede pe ọjọ kejidinlọgbọn ati ikọkandinlọgbọn oṣu karun un ọdun 2022 lawọn yoo ṣe eto ipade itagbangba apapọ wọn ati ipade lati yan oludije fun ipo aarẹ nilu Abuja.
Awọn agbofinro gbọdọ gbe Emefiele lọ sile ẹjọ - PDP
Amọṣa ẹgbẹ oṣelu PDP ko ṣai tun tẹnumọ ipe to ti kọkọ pe lopin ṣẹ to kọja pe ki awọn agbofinro fi panpẹ ofin gbe gomina banki apapọ Naijiria, Godwin Emefiele ti wọn ni o gba iwe ati dije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC lai jẹpe o kọwe fi ipo rẹ silẹ.
Ẹgbẹ oṣelu PDP ni nṣe ni Emefiele fi juujuu bo orilẹede Naijiria loju ko da wọn fi ẹsun ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu kan pe o lọwọ ninu bi eto ọrọ aje Naijiria ṣe dẹnukọlẹ.
- Mo dúpẹ́ ó! Mo bẹ́ orí fún gbogbo àgbẹ̀ àti olùfọkànsìn tó ń dáwó fọ́ọ̀mù Ààrẹ fún mi àmọ́ ẹ jẹ́ n lo óògùn ara mi - Emefiele
- Ẹ gba ìpínlẹ̀ Eko kúrò lọ́wọ́ àwọn àjòjì - Atiku sí Bode George
- Ẹ má ṣe bẹ̀rù ọ̀rọ̀ Ẹ̀sìn tó gbalẹ̀ kan l'Ekiti, a ti f'òfin bọ ọ̀rọ̀ Pasito Ade Abraham - Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá Ekiti
- Bí Jibrin ṣe kúrò ní ẹgbẹ̀ òṣèlú APC kò níi ṣe pẹ̀lú Bola Tinubu- Agbẹnusọ ìpolongo
- Èsì ìdánwò UTME abala àkọ́kọ́ yóò jáde lọ́sẹ̀ yìí- Àjọ JAMB
- Iṣẹ́ Ọlọ́run tí mo gbé dáni kọjá ipò Ààrẹ Nàìjíríà – Bíṣọ̀ọ̀bù David Oyedepo
- Irọ́ ni pé Bola Tinubu fẹ́ kúrò ní ẹgbẹ́ òṣèlú APC- Agbẹnusọ Aṣíwájú
- INEC lẹ́tọ̀ọ́ láti bẹ́gi dínà èróngbà Emefiele láti díje du ipò Ààrẹ- Ilé ẹjọ́
Alukoro ẹgbẹ oṣelu PDP, Debọ Ologunagba ṣalaye siwaju sii pe igbimọ akoso to ga julọ ni ẹgbẹ oṣelu PDP "tako bi gomina banki apapọ Naijiria, Gọdwin Emefiele ṣi ṣe wa nipo lẹyin to ti gba kaadi gẹgẹbi ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC."
Wọn ni gẹgẹ bi alabojuto gbogbo awọn ohun elo ẹlẹgẹ ti ajọ INEC fi n ṣeto idibo rẹ gbogbo, to si tun ti wa fidimulẹ pe ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ni bayii, Ọgbẹni Emefiele ko ṣee fi ọkan tan mọ lati wa ni iṣakoso awọn ohun elo idibo ẹlẹgẹ naa nitori ati lee ṣeto idibo ti ko lẹjambakan ninu rara mọ.


















