Oyo Politics: Sẹ́nétọ̀ gúúsù Oyo fi ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sílẹ̀, darapọ̀ mọ́ APC

Joseph Tegbe ati Kola Balogun

Oríṣun àwòrán, Others

Ṣe lootọ ni Makinde gba Tikẹẹti sẹnetọ lọwọ Kọla Balogun fun Joseph Tegbe?

Lẹnu ọjọ mẹta yii ni iroyin bẹrẹ sini ja ranyinranyin wi pe Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun Guusu Ọyọ nile igbimọ aṣofin agba fun ẹgbẹ oṣelu PDP, Kọla Balogun ko ni lanfani lati ṣe saa ikeji.

Won sọ pe nitori pe Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde ti fi han gbangba wi pe ọkan lara awọn oludije si ipo gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹri ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Joseph Tegbe ni oun yoo fun ni anfani lati dije du ipo sẹnetọ ẹkun Guusu ipinlẹ Ọyọ ninu gbẹ oṣelu PDP.

Ọ jọ gate ko jọ gate...

Lẹyin ọjọ diẹ ti iroyin yii gbode ni Sẹnetọ Kola Balogun kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ti o si lọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC, gẹgẹ bi Joseph Tegbe ti o jẹ oludije si ipo gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹri naa ṣe n kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APC lati lọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP.

Alaye ti Kọla Balogun ṣe ni pe iwa imọ tara ẹni nikan lo kun ọwọ gomina Seyi Makinde ati pe ifẹ inu lasan lo n fi iṣejọba rẹ pe kii ṣe ti ara ilu.

Àkọlé fídíò, Iyabo Anisulowo:Ẹ̀yin ọ̀dọ́ Nàìjíríà, ẹ má bínú, kò rọrùn fún ọ̀dọ́ láti dìde nínú ìṣèlú

Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ pe ile ni oun pada si nitori inu ẹgbẹ oṣelu APC ni oun ti ya lọ sinu ẹgbẹ oṣelu PDP ati pe aja oun ti fori komi o si ti ṣẹri pada sile.

Saaju asiko yii, Kọla Balogun nikan ni Sẹnetọ to n ṣoju fun ẹgbẹ oṣelu PDP ipinlẹ Ọyọ nile igbimọ aṣofin agba l'Abuja.

Àkọlé fídíò, Osun spider man: Mo ń ṣe ìtanijí láti gbógunti ìdọ̀tí láwùjọ ló sún mi dé ìdí 'Spider man'

Bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan ti n ri Joseph Tegbe ti o jẹ ọkan lara awọn Mogaji ilẹ Ibadan pẹlu Gomina Ṣeyi Makinde lẹyin ti o darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP lati du ipo Sẹnetọ ẹkun Guusu ipinlẹ Ọyọ.

Ariwo kan ti o tun ṣu yọ l'ọjọ Iṣẹgun ni bi apapọ awọn Mọgaji ilẹ Ibadan ṣe n jiyan iroyin to lu sita wi pe gbogbo wọn n gbe sẹyin Tegbe lati jẹ Sẹnetọ.

Àkọlé fídíò, Adewole Quyum: Ọdún10 ni mo ti ń kọ́ 'welder' mo ti ṣe ọ̀kadà tó ń lo 'generator'

Aarẹ ẹgbẹ awọn Mọgaji ilẹ Ibadan, Mọgaji Asimiyu Ariori ṣe alaye ọrọ ninu atẹjade ti wọn fi lede lọjọ Iṣẹgun wi pe gbogbo awọn ọmọ ilẹ Ibadan to n du ipo oṣẹlu ni awọn n ṣe atilẹyin dipo iroyin to gbode pe wọn ti da ẹnikan ya sọtọ.

Àkọlé fídíò, Ó yẹ kí a wádìí ikú tó pa Oba Lamidi Adeyemi, Baba gbọ́dọ̀ padà- Sat Guru Maharaj-ji

Mọgaji Ariori fi idi ọrọ mulẹ pe ọkan lara awọn ni Joseph Tegbe lootọ, ṣugbọn awọn ko ti i fa ọwọ rẹ soke gẹgẹ bi oludije ti ẹgbẹ naa n ṣe atilẹyin fun.

Nibi ti nnkan de duro bayii, bi Kọla Balogun ba ni anfani lati dije gẹgẹ bi i Sẹnetọ ti yoo ṣoju ẹkun Guusu ipinlẹ Ọyọ fun ẹgbẹ oṣelu APC nile igbimọ aṣofin agba ninu eto idibo apapọ to n bọ lọna, a jẹ wi pe oun ati Joseph Tegbe to jẹ aṣoju fun ẹgbẹ oṣelu PDP ni yoo jọ ta kangbọn.

Awọn oloṣelu

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Kola Balogun ju ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sílẹ̀, darapọ̀ mọ́ APC

Sẹ́nétọ̀ tó ń ṣojú ẹkùn gúúsù Oyo ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà ní Abuja, Kola Balogun ti ju ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party (PDP) sílẹ̀ bí àmukù ọsàn.

Inú ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC ni Kola Balogun ta kọ́sọ́ sí ní ọjọ́ ìṣẹ́gun, ọjọ́ kẹwàá, oṣù karùn-ún, ọdún 2022 tí wọ́n sì tẹ́wọ́ gbàá ní oríkò ilé ẹgbẹ́ APC tó wà ní Oke Ado ní Ibadan.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe sọ, Kola Balogun darapọ̀ mọ ẹgbẹ oṣelu APC nitori aawọ to n waye laaarin oun ati gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde lori tikẹẹti lati pada sile igbimọ aṣofin lọdun 2023 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP.

Seyi Makinde ni wọn ni o kọ lati gba wi pe ki Kola Balogun pada si ile igbimọ aṣofin agba nibi eto idibo gbogbogboo to n bọ lọna.

Alaga ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ Oyo, Isaac Omodewu ati gbogbo igbimọ alaṣẹ lo tẹwọ gba Kola Balogun nigba to ya lọ sinu ẹgbẹ naa.

Àkọlé fídíò, Basorun Akinade Ayoola Yusuf: Ìsìnkú Aláàfin Oyo àti Ooni Ile Ife yàtọ̀ nílẹ̀ Oodua

Kola Balogun ni imọ tara ẹni nikan n damu Seyi Makinde

Kola Balogun nigba to n sọrọ ni iwa imọ tara ẹni nikan lo kun ọwọ gomina Seyi Makinde ati pe ifẹ inu lasan lo n fi iṣejọba rẹ ṣe kii ṣe ti ara ilu.

Bakan naa lo fi kun wi pe oun pada wa sile nitori inu ẹgbẹ oṣelu APC ni oun ti ya lọ sinu ẹgbẹ oṣelu PDP ati pe aja oun ti fori komi o si ti ṣẹri pada sile.

Alaaga fun ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Oyo, Moses Omodewu, nigba ti o n ki Balogun kaabọ si ẹgbẹ oṣelu APC, ni ẹgbẹ APC n gbeeru si ni ipinlẹ naa ni ojoojumọ.

O ni bi o tilẹ jẹ pe awọn ni gbun gbun gbun laaarin ara awọn ninu ẹgbẹ tẹlẹ, imọ awọn ti ṣe ọkan bayii ti awọn yoo si pada si ile ijọba ni Agodi lọdun 2023.

Bakan naa lo ni inu oun dun wi pe ẹgbẹ oṣelu APC lo ni sẹnetọ mẹtẹẹta to wa ni ipinlẹ Oyo bayii, ti awọn si ti se tan lati gba ijọba lọwọ ẹgbẹ oṣelu PDP.

Adebayo Adelabu

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Adelabu kéde èròńgbà rẹ̀ láti jẹ gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo

Bí gbèdéke ọjọ́ kẹta, oṣù Kẹfà tí àjọ elétò ìdìbò ilẹ̀ Nàìjíríà, INEC, fún àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú láti fi ṣètò ìdìbò abẹ́nú ṣe ń súnmọ́ etílé.

Olùdíje sípò gómìnà lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC ní ọdún 2019 ní ìpínlẹ̀ Oyo, Adebayo Adelabu tún ti fi èròńgbà rẹ̀ láti dupò gómìnà ìpínlẹ̀ náà níbi ètò ìdìbò gbogbogboò ọdún 2023 hàn.

Níbi àpérò tí Adelabu ṣe pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyìn ní gbọ̀ngán Jericho ní ìlú Ibadan ló ti fi èròńgbà rẹ̀ hàn lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹsàn-án, oṣù Karùn-ún, ọdún 2022.

Ìgbà àkọ́kọ́ kọ̀ nìyí tí Adelabu yóò dupò gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo

Ẹ ó rántí pé Adelabu àti Seyi Makinde ti ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP, dìjọ wàákò níbi ètò ìdìbò ọdún 2019 kí ó tó jámọ́ Seyi Makinde lọ́wọ́.

Adelabu ní ìṣèjọba Makinde ti kùnà láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Oyo jẹ mùkúndùn ìjọba àwaarawa, tí àwọn ọmọ gàǹfé sì ń fi ojoojúmọ́ pọ̀ si ní ìpínlẹ̀ Oyo.

Àkọlé fídíò, Agbẹjọ́rò Abdullateef Lanre Abdullahi sọ pàtàkì ìbálòpọ̀ àti ìmọ́tótó láàrin lọ́kọláya

Ó ní ìwà ipá ni àwọn ọ̀dọ́ ìpínlẹ̀ Oyo ń ṣe báyìí nítorí ọwọ́ wọn tó dilẹ̀ jù àti pé ìjọba kò mójútó wọn.

Adelabu, tó ti fi ìgbà kan jẹ́ igbákejì gómìnà ilé ìfowópamọ́ àgbà Nàìjíríà ní òun fìdí rẹmi níbi ètò ìdìbò ọdún 2019 nítorí àwọn kùdìẹkudiẹ kan.

Ó ní òun ní gbogbo àmúyẹ tó yẹ láti fi to ìpínlẹ̀ Oyo ju bí ó ṣe wà báyìí lọ.