Genevieve Nnaji fi fídíò sí Instagram, lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí ìròyìn sọ pé ó ní àrùn ọpọlọ

Oríṣun àwòrán, other
Gbajugbaja oṣerebinrin, Genevieve Nnaji, ti fi fidio kan si ori ayelujara Instagram rẹ, lẹyin wakati diẹ ti iroyin sọ pe o wa nileesowan awọn alarun ọpọlọ.
Ṣaaju ki iroyin naa to jade lọjọ Iṣẹgun, ni Arabinrin Nnaji, yọ gbogbo aworan ati fidio to ti fi si ori ayelujara ibanidọrẹ Instagram rẹ, lati igba to ti n lo, kuro ni ọjọ Aje.
Ninu fidio to fi sita ni owurọ Ọjọru, lori Instagram stories, la ti ri i to n ya aworan pẹlu ọ̀dà, niwaju ile kan.
Botilẹ jẹ pe ko sọ ọrọ kankan ninu fidio naa, o kọ akọle si pe oun n ṣe arojinlẹ, #mindfulness.
Ọpọ lo si tun ti n sọrọ nipa fidio naa pe o ṣe e sẹ ko jọ ileewosan itọju aarun ọpọlọ lo wa lootọ, nitori iru aworan to n kùn ni ọda.
Yatọ si pe o yọ gbogbo awọn nkan to wa ni ori Instagram rẹ, oṣu Kinni, ọdun yii, lo ti 'unfollow' gbogbo awọn to n ba dọrẹ tẹlẹ lori ayelujara naa.
Ọpọ eeyan lo bu ẹnu ẹtẹ lu u nigba naa pe, igberaga lo mu ko ṣe bẹẹ.
Kini iroyin sọ nipa ilera Genevieve Nnaji?
Ọjọru ni agbohunsafẹfẹ ori ayelujara kan, fi iroyin sita pe ki awọn ololufẹ oṣerebinrin, Genevieve Nnaji, o gbohun adura soke fun, nitori ilera ọpọlọ rẹ.
Iroyin naa ti BBC ko tii ri ifidimulẹ rẹ sọ pe oṣere naa ti n gba itọju ni ileewosan itọju aarun ọpọlọ kan nilu Houston Texas, lorilẹ-ede America. Lati bi oṣu diẹ.
- Olùkọ́ Chrisland College mẹ́rin fojú balé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn ìbálòpọ̀
- Irọ́ ni, irọ́ kọ́ Toyin Adegbola àti àwọn míì sọ̀rọ̀ nípa fídíò Biola àti Olùdarí ere tí wọ́n jọ ní gbólóhùn asọ̀
- Apostle Jonhson Suleiman sọ̀rọ̀ sókè lórí ẹ̀sùn tí Stephanie Otobo fi kàn án
- Wo àwọn obìnrin mẹ́wàá tí ipa wọn kò ṣe fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn ní ààfin Oyo
Ṣaaju ninu oṣu Kẹta, ni awọn eeyan kan ti n fura pe o ṣeeṣe ki Arabinrin Nnaji o ma la awọn iriri kan kọja, nitori ọrọ kan to kọ si ori ayelujara nipa ilera ọpọlọ.
O ni "Nini ilera ọpọlọ to pe nii ṣe pẹlu igbe aye ẹmi, ju nkan to ṣe e fi oju ri. Yọnda aye rẹ fun Ọlọrun to n sin. Ko si pada ṣe iribọmi."
Yatọ si ọrọ yii, oṣu Kẹwaa, ọdun to kọja, lo fi nkan si ori ayelujara Facebook kẹhin.
Bakan naa, ninu oṣu Kinni, ọdun 2022, o fi si ori ayelujara Twitter pe "ọpọ igba la n gbe agbara wọ awọn ihuwai to n dari wa;... ibinu, inu fufu, gbigba ẹsan, ijakulẹ, igberaga, ati bẹẹ bẹẹ lọ, debi pe a n sọ wọn di ọlọrun, ti a si kuna lati fun Ọlọrun tootọ kan ṣoṣo, to n tọ iṣiṣẹ wa, to si n daabo bo gbogbo irin wa, ni ọ̀wọ̀."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
- Báwo ni ọ̀rọ̀ ilé ṣe fa Gbas-gbos láàrín Mercy Aigbe, ìyáále rẹ̀ àti ọkọ rẹ̀?
- Human Rights Watch fẹ̀sùn àìbìkítà kan ìjọba Naijiria lẹ́yìn ikú awọn olùwọ́de lásìkò ìwọ́de EndSARS
- Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ Uche Igwe di èrò iléẹjọ́ lórí ẹ̀sùn pínpín fídíò ìbálòpọ̀ ọmọdé
- Kọ́ńdọ̀ọ̀mù méjìlá lá rí ní iyàrá ilé ìtura tí wọ́n ti fípa bá arábìnrin Ulochi lòpọ̀- Olọ́pàá
- Èmi ò gbé'ṣẹ́ rán ẹnikẹ́ni láti ra fọ́ọ̀mù ìdíje ààrẹ fún mi o, ẹ máà kóbá mi -Ààrẹ tẹ́lẹ̀ Goodluck Jonathan fún Miyetti Allah lésì
- Wo àwọn òjé tí àwọn olóṣèlú máa fi ń jẹ àwọn ènìyàn bí ètò ìdìbò bá ti ń súnmọ́lé
- Ìpapòda Aláàfin kò ní dá ètò ìfinijoyè Gbajabiamila dúró- Ọyọmesi
- Ó pé ọdún 35 tí Obafemi Awolowo kú, wo àwọn nkan mánigbàgbé tí o kò gbọ́ rí nípa rẹ̀
Nkan to yẹ ki o mọ nipa Genevieve Nnaji
Ọkan pataki lara awọn gbajumọ osẹre ede Gẹẹsi ni Naijiria ni arabinrin Nnaji.
Ọmọ ọdun mẹjọ lo ti bẹrẹ ere ṣiṣe, nigba to kopa ninu ere ori amohunmaworan, Ripples.
O si ti kopa ninu fiimu to le ni ọgọrin.
Yatọ si ere ṣiṣe, o gbe awo orin kan jade to pe ni "One Logologo Line".
O si tun jẹ oludari ere.










