Abakaliki hotel suspected gang rape: Ìwádìí bẹ̀rẹ̀ láti mọ àwọn tó fipá bá Ulochi sùn tó fi kú ní Abakaliki

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Kọ́ńdọ̀ọ̀mù méjìlá lá rí ní iyàrá ilé ìtura tí wọ́n ti fípa bá arábìnrin Ulochi lòpọ̀- Olọ́pàá
Ileesẹ ọlọpaa ni agbegbe ila oorun Guusu Naijiria ti kede pe awọn n wa awọn to korajọ fipa ba arabinrin kan lopọ doju iku.
Loveth Oda to jẹ alukoro ọ́lọpaa ni ipinlẹ Ebonyi sọ pe nise lawọn ba ti wọn de ọwọ ati ẹsẹ arabinrin yi ti wọn si fi oku rẹ silẹ.
Ileesẹ ọlọpaa darukọ arabinrin naa gẹgẹ bi Ugochi Nworie ati pe isẹlẹ naa waye ni Abakaliki, ipinlẹ Ebonyi .
Sugbọn ko daju boya wọn ti fi to awọn mọlẹbi arabinrin yi leti nipa isẹlẹ yi nigba ti a fi n se akojọpọ iroyin yi.
- 'Ètò ayẹ́yẹ́ ìsìnkú Oba Lamidi Adeyemi kòí tíì wáyé, àfọ̀mọ́ Aàfin ń lọ lọ́wọ́'
- Ó pé ọdún 35 tí Obafemi Awolowo kú, wo àwọn nkan mánigbàgbé tí o kò gbọ́ rí nípa rẹ̀
- Èsì àyẹ̀wò ohun tó ṣekú pa gbajúmọ̀ akọrin ẹ̀mí, Osinachi Nwachukwu ti jáde
- Gomina Yahaya Bello ra fọ́ọ̀mù N100m láti gba iṣẹ́ lọ́wọ́ Ààrẹ Buhari
- Àwọn ológun pa ikọ̀ Boko Haram ogún, wọ́n dóòlà àwọn obìnrin tó wà ní ìgbèkùn
- Mo ti gbà báyìí pé ohun gbogbo tó n dán kọ́ ni wúrà - Olori Badirat Adeyemi
- Lukman gbẹ̀yín ẹbí lọ bẹ́ orí ìkókó ti wọ́n sìn ní Abeokuta, àṣírí tú bó ṣe fẹ́ tàá
- Ẹ dáríjìn mí ọmọdé ló ń ṣe mí, mo kábàmọ́ ìwà tí mo wú - Akẹ́kọ̀ọ́ Chrisland Schools
Bawo ni o se sẹlẹ?
Isẹlẹ aburu yi waye lọjọ Abamẹta to kọja sugbọn ni ọjọ Aje ni iroyin yi to jade.
Adugbo Ngbowo lo si ti sẹlẹ ni ilu Abakaliki gẹgẹ bi awọn akọroyin ti se sọ lagbegbe naa.
Nise ni ọrọ yi mu kawọn ọlọpaa gbe nilẹ keke ti o de eti igbọ ẹka ileesẹ ọlọpaa Kpirikpiri to wa ni Abakaliki.
Amọ arabinrin kan to sọ pe oun jẹ ọrẹ Ugochi sọ fun BBC pe awọn lọ si ode kan ni alẹ ọjọ Abamẹta ati pe nibẹ lawọn eeyan kan ti wa ba awọn.
"A fẹ kuro ni ile itura naa ni awọn arakunrin kan nipe ka wa se faaji pẹlu awọn sugbọn emi ko tẹle wọn''.
"Lẹyin igba naa ni a gbọ pe Ugochi ti ku ."
- Ó pé ọdún 35 tí Obafemi Awolowo kú, wo àwọn nkan mánigbàgbé tí o kò gbọ́ rí nípa rẹ̀
- Ẹ kò gbọdò lo 'Make Up'; ya 'tatoo'; fi kún èékánná tàbí kun àtíkè níta mọ́ lábẹ́ òfin wa- Iran
- Ọwọ́ pálábá NDLEA tẹ aláboyún méjì, 'barber' kan àti àwọn afurasí mí tó gbé egbòogi
- Ṣé Christiano Ronaldo yóò dúró tàbí kò ní dúró n'Manchester United fún sáà líìgì tó ń bọ̀?
- Wo àwọn òjé tí àwọn olóṣèlú máa fi ń jẹ àwọn ènìyàn bí ètò ìdìbò bá ti ń súnmọ́lé
- Èmi ò gbé'ṣẹ́ rán ẹnikẹ́ni láti ra fọ́ọ̀mù ìdíje ààrẹ fún mi o, ẹ máà kóbá mi -Ààrẹ tẹ́lẹ̀ Goodluck Jonathan fún Miyetti Allah lésì
- FIFA ní kí àjọ bọ́ọ̀lù ní Nàìjíríà, NFF ó san N156m owó gbà máà bínú fún Gernot Rohr
''A ba kọndọọmu mejila ninu iyara ile itura''- Oro ileeṣẹ ọlọpaa
Ileesẹ ọlọpaa Abakaliki sọ pe iwadii ibẹrẹ awọn fi han pe isẹlẹ ifipabanilopọ ni isẹlẹ naa.
Alukoro ọlọpaa Oda sọ pe awọn ko le sọ ni pato iye eeyan to hu iwa yi sugbọn awọn ba rọba idaabobo kọndọọmu mejila ni iyara ile itura ti iwa buruku yi ti waye.
O ni pe nise ni ọga ọlọpaa agọ ti wọn mu ẹjọ yi wa sọ pe awọn ri ẹri naa nigba tawọn n kaakiri lati mọ nkan to sẹlẹ ni ile itura naa ni.
O ni nigba naa lawọn ri iyara kan ti wọn ko le sọ awọn to wa ninu rẹ.
''Lẹyin igba naa ni ọga ọlọpaa DPO naa beere lọwọ osisẹ ile itura naa pe awọn wo lo wa ni iyara naa to si ni oun ko mọ awọn to wa nibẹ.''
Igbesẹ wo ni wọn ti gbe?
Igbiyanju wọn lati si iyara naa ja si pabo afi igba to ni ki wọn mu kọkọrọ alekun iyara naa wa.
Nigba naa ni wọn wa ba oku arabinrin yi ni ihoho ọmọluabi ti wọn si so ọwọ ati ẹsẹ rẹ mọ ibusun to wa ninu iyara naa.
Ọga ọlọpaa naa sọ pe awọn ti gbe oku rẹ lọ si ile igbokupamọ si.
Iwadii fi han pe ọmọ bibi ijọba ibilẹ Ikwo ni ipinlẹ Ebonyi ni Ugochi Nworie jẹ.
A ko mọ isẹ to n se tabi boya akẹkọọ si ni.
Araalu ni o seese ki wọn fi se oogun owo ni
Awọn ileesẹ iroyin kan to wa ni agbegbe naa sọ pe awọn ẹya ara Ugochi kan ti dawati nigba ti wọn ri oku rẹ.
Igbagbọ si ni pe wọn fi se oogun ọla ni sugbọn ileesẹ ọlọpaa ko ti fidi ọrọ yi mulẹ.
Isẹlẹ ka maa fi eeyan dan isẹ oogun ọla wo jẹ nkan to wọpọ lẹnu ọjọ mẹta yi lorileede Naijria.
Eleyi si mu kawọn ileesẹ agbofinro mu ọpọ to lọwọ ninu iwa aburu yi lawujọ.
Laipẹ yi lawọn ọdọmọkunrin mẹta kan ni ipinlẹ Ogun ko si panpẹ awọn ọlọpaa lẹyin ti wọn bẹ ori ọrẹbinrin ọkan ninu wọn.
Iwadii fi han pe wọn lawọn fẹ fi se oogun owo ni.
Ọjọ ori awọn ọdọkunrin ko kọja ogun ọdun.
Bẹẹ, iroyin to tẹwa lọwọ lati ọdọ awọn alasẹ ni ninu isẹlẹ awọn to sọnu tabi ti wọn n wa to de eti igbọ awọn, pupọ lo nise pẹlu isẹlẹ ipaniyan lati fi soogun owo .


















