Political gimmicks: Wo àwọn òjé tí àwọn olóṣèlú máa fi ń jẹ àwọn ènìyàn bí ètò ìdìbò bá ti ń súnmọ́lé

Atiku àti Omisore

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Bí ètò ìdìbò gbogbogboò ọdún 2023 ṣe ti ń súnmọ́ ètilè, a ṣe àgbéyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn ìwà àti àwọn òjé tí àwọn olóṣèlú ti ṣe rí lásìkò tí ètò ìdìbò ń bọ̀

Bí àwòràn gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Ekiti, Ayodele Fayose, níbi tó ti ń jẹ àmàlà ní búkà kan nílùú Abuja lẹ́yìn tó gba fọ́ọ̀mù láti díje sípò Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà gba orí ẹ̀rọ ayélujára mú ìrántí gbogbo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó máa ń wáyé lásìkò tí ètò ìdìbò máa ń súnmọ́.

Ní agbègbè Wuye ní Abuja ni Fayose mórílé lẹ́yìn tó gba fọ́ọ̀mù tań láti lọ jẹ àmàlà pẹ̀lú oríṣiríṣi nǹkan inú ẹran gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà láti fi hàn wí pé òun ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ènìyàn òun.

Ọ̀pọ̀ ènìyàn, lórí ayélujára ní ìwà tí Fayose hù yìí kìí ṣe àkọ́kọ́ rẹ̀ nítorí láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2000 ni Fayose ti ń ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tó ń díje sípò gómìnà lọ́dún 2003.

Tí ètò ìdìbò bá ti ń bọ̀ lọ́nà, pàápàá tó bá ti ku bí ọdún kan tàbí oṣù díẹ̀, lára ohun tí àwọn olóṣèlú máa ń ṣe ni kí wọ́n máa ra àgbàdo jẹ ní ẹsẹ̀ títì, wọ ilé onídìrí lọ láti máa bá àwọn ènìyàn ṣerun, gun ọ̀kadà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Àkọlé fídíò, Agbẹjọ́rò Abdullateef Lanre Abdullahi sọ pàtàkì ìbálòpọ̀ àti ìmọ́tótó láàrin lọ́kọláya

Àwọn irúfẹ́ ìwà yìí máa ń fa awuyewuye lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà tó jẹ́ wí pé tí àwọn kan máa ń sọ wí pé ẹ̀tàn lásán ni wọ́n ń fi gbogbo àwọn olóṣèlú máa ń fi ìwà bẹ́ẹ̀ ṣe.

Bí ètò ìdìbò gbogbogboò ọdún 2023 ṣe ti ń súnmọ́ ètilè, a ní ká ṣe àgbéyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn ìwà àti àwọn òjé tí àwọn olóṣèlú ti ṣe rí lásìkò tí ètò ìdìbò ń bọ̀.

Adam Oshiomhole, Godwin Obaseki

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Obaseki àti Oshiomhole jẹ àgbàdo lórí ìrìn

Níbi ètò ìpolongo sí ìdìbò tó gbé gómìnà ìpínlẹ̀ Edo, Godwin Obaseki wọlé ní sáà àkọ́kọ́ rẹ̀ lọ́dún 2016 ní Obaseki àti bàbá ìsàlẹ̀ rẹ̀, tó tún jẹ́ èèkàn nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Adams Oshiomhole ra àgbàdo lójú ọ̀nà.

Ní ojú ọ̀nà yẹn náà ni wọ́n ti ń ya àgbàdo jẹ ní ẹsẹ̀ títì ní ìlú Benin tí ń ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Edo láti fi han àwọn alátìlẹyìn wọn, gẹ́gẹ́ bí èrò wọn wí pé kò sí ìyàtọ̀ láàárín àwọn.

AdamsOshiomhole

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Oshiomhole tún padà sí yíya àgbàdo jẹ

Bí ètò ìdìbò ọdún 2020 sí ìbò gómìnà tún ṣe tún ń bọ̀ lọ́nà ní ìpínlẹ̀ Edo ní ọdún 2020, Oshiomhole àti Obaseki ti pín gààrí, àwọn méjéèjì ti ṣe lọ́tọ́ọ̀tọ̀ tó mú Obaseki fi fi ẹgbẹ́ APC sílẹ̀ bọ́ sí PDP.

Fọ́nrán Oshiomhole kan gba orí ayélujára kan níbi tó ti ń jẹ àgbàdo tí àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ sì ń sàá.

Lẹ́yìn ò rẹyìn, Obaseki padà fi fọ́nrán tó jẹ́ wí pé òun àti Oshiomhole ti ṣe irú rẹ̀ sẹ́yìn fi bu pé kò ní ọ̀wọ̀ kankan fún àwọn ènìyàn àti pé àwọn ènìyàn kìí ṣe adìẹ tí yóò máa sáré tẹ̀lé àgbàdo kiri.

Omisore pẹ̀lú àgbàdo lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Omisore náà fi àwòrán ibi tó ti ń jẹ àgbàdo sórí ayélujára

Kò sí bí ènìyàn kò ní fẹ́ rín ẹ̀rín àríntàkìtì nígbà tó bá kọ́kọ́ rí àwòrán olóyè Iyiola Omisore níbi tó ti mú àgbàdo méjì sí ọwọ́ stún rẹ̀ méjéèjì bí ẹni wí pé ẹ̀rù ń bàá láti jẹ́.

Àkọlé fídíò, 'Mo fara da ìsòro gan láwùjọ́ torí àwọn òbí mi di létí'

Ọ̀pọ̀ ènìyàn tilẹ̀ sọ nígbà náà wí pé yóò rí bẹ̀ nítorí kìí ṣe ìfẹ́ àwọn ara ìlú ló mu fi ra àgbàdo nírònà bíkòṣe nítorí pé àwòrán tó fẹ́ fi yà.

Yàtọ̀ sí àwòrán yìí, àwọn ìgbà mìíràn ni Omisore ti ya àwòrán ara rẹ̀ lórí ọ̀kadà, ra gúgúrú lẹ́sẹ̀ títì, gbé ṣíbí ìrẹsì dání lórí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Sanwo-Olu ń ra bọ̀ọ̀lì

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Sanwo-Olu

Ṣaájú ọjọ́ ìdìbò tó gbé gómìnà ìpínlẹ̀ Eko, Babajide Sanwo-Olu wọlé ọ̀kan-ò-jọ̀kan àwọ̀ ni Sanwo-Olu gbéwọ̀ bí ọ̀gà.

Lára àwọn àwòrán ohun tí Sanwo-Olu ṣe nígbà náà tó fẹ́rẹ̀ fa orí ayélujára ya ni ìgbà tí òun àti igbákejì rẹ̀ Obafemi Hamzat ń dirun fún obìnrin kan ní agbègbè Computer Village, Ikeja.

Àkọlé fídíò, Banji Akitoye: Yoruba Nation nìkan ni 'Only Solution' lásìkò yíì, A kò kórira ẹ̀yà tó kù

Àwòrán míì ni èyí tó fi ìgbà tí àti igbákejì rẹ̀ ń kọ́ṣẹ́ bí ènìyàn ṣe le tún fóònù ṣe, ìgbà tí wọ́n ṣe àbẹ̀wò sí ṣọ́ọ̀bù Mẹkáníìkì kan tí wọ́n sì ń ba pààrọ̀ ọ́ìlì ọkọ̀. Gbogbo rẹ̀ láti fa ojú àwọn ènìyàn mọ́ra láti dìbò fún wọn.

Nígbà tí àwòrán Sanwo-Olu mìíràn níbi tó ti ń ra bọ̀ọ̀lì tún lu orí ayélujára nínú oṣù kejì ọdún 2021, àwọn ènìyàn ní ó padà sí ẹsẹ̀ àárọ̀ rẹ̀ ni.

Dino Melaye ń kiri ẹ̀pà

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Melaye kiri ọjà

Ní ọdún 2016 tí àwòrán Dino Melaye níbi tó ti gbé àtẹ ẹ̀pà lórí bí ẹni tó ń kiri ọjà gba orí ayélujára ni àwọn ènìyàn kó ẹnu bòó wí pé ẹ̀tàn lásán ni.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àdúgbò tí Melaye ti ya àwòrán náà kìí ṣe ọjà, Melaye ní òun kìí ṣe ẹlẹ́tàn nítorí òun kiri ọjà dáadáa nígbà tí òun wà ní kékeré.

Osinbajo nínú ọkọ̀ BRT

Oríṣun àwòrán, TWITTER

Osinbajo nínú ọkọ̀ BRT

Nínú oṣù kejìlá, ọdún 2014, Ọ̀jọ̀gbọ́n Yemi Osinbajo tó jẹ́ olùdíje sípò igbákejì Ààrẹ orílẹ̀ èdè yìí gbé àwòrán ibi tó ti wọ ọkọ̀ BRT tó sì ń bá àwọn ènìyàn tàkurọ̀sọ sórí ayélujára Twitter rẹ̀.

Àkọlé fídíò, Kò sí ńkan ti ọkùnrin ń ṣe tí obìnrin kò le ṣe- Afusat Adeniyi tó ń tún 'Pumping Machine'

Mélòó la fẹ́ kà nínú eyín adípèlé ni ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀kan-ò-jọ̀kan ìwà tí àwọn olóṣèlú máa ń wù lásìkò tí ètò ìdìbò bá ń bọ̀.

Bí ètò ìdÌbò gbogbogboò ọdún 2023 ṣe ń súnmọ́ etílé ẹyẹ àdán BBC doríkodò ó ń wòṣe ẹyẹ àwọn olóṣèlú lórí itú tí wọ́n yóò tún pa àti wí pé ǹjẹ́ àwọn òjé yìí yóò tún jẹ àwọn ọmọ Nàìjíríà.

Àkọlé fídíò, Adewole Quyum: Ọdún10 ni mo ti ń kọ́ 'welder' mo ti ṣe ọ̀kadà tó ń lo 'generator'