Emefiele presidency ambition: Emefele kò lè ní kí INEC má bẹ́gi dínà èróngbà òun láti díje du ipò Ààre gẹ́gẹ́ bíi gómìnà CBN - Ilé ẹjọ́

Emefiele

Oríṣun àwòrán, @Emefiele

Emefele kò lè ní kí INEC má bẹ́gi dínà èróngbà òun láti díje du ipò Ààre gẹ́gẹ́ bíi gómìnà CBN - Ilé ẹjọ́

Ile ẹjọ giga kan niluu Abuja ti kọ ẹbẹ gomina CBN, Godwin Emefiele, lati dẹkun ajọ eleto idibo, INEC, ati adajọ agba Naijiria, Abubakar Malami, lẹyin ti wọn gbe igbesẹ lati bẹgi dina ilepa rẹ lati dije du ipo Aarẹ Naijiria lai kọkọ fi ipo silẹ gẹgẹ bii gomina CBN.

Emefiele sọ fun ile ẹjọ naa lọjọ Aje pe oun lẹtọ lati dije du ipo Aarẹ Naijiria lai kọkọ fi ipo silẹ gẹgẹ bii gomina banki apapọ, CBN.

Kini o ṣẹlẹ nile ẹjọ́?

Agbẹjọro Emefiele, Mike Ozekhome, sọ fun ile ẹjọ naa pe abala 84 (12) iwe ofin eto idibo "electoral act," ti wọn ṣe agbeyẹwo rẹ lọdun 2022 yii ko tako erongba onibara oun lati dije du ipo niwọn igba to jẹ pe oṣiṣẹ ijọba ni, kii ṣe ẹni ti wọn yan sipo nipasẹ oṣelu.

Nigba to n ṣedajọ rẹ, ile ẹjọ giga naa ni ki adajọ agba Naijiria ati ajọ INEC yọju siwaju oun lọjọ kejila oṣu Karun un, lati wa ṣalaye eredi ti Emefiele ko fi le dije du ipo.

Àkọlé fídíò, Agbẹjọ́rò Abdullateef Lanre Abdullahi sọ pàtàkì ìbálòpọ̀ àti ìmọ́tótó láàrin lọ́kọláya

Emefiele ni oun n fẹ ki ile ẹjọ naa kede pe o tọ si oun lati dije du ipo Aarẹ lai fi ipo silẹ.

Ẹbẹ naa jẹ ọkan gboogi lara awọn ẹbẹ meje to gbe lọ siwaju ile ẹjọ ọhun.

Yatọ si eyii, gomina CBN naa tun n fẹ ki ile ẹjọ kede pe oun lẹtọ labẹ ofin lati dibo fun ẹni ọkan oun ba n fẹ lọjọ idibo, yatọ si pe oun funra oun le dije du ipo.

Àkọlé fídíò, 'Mo fara da ìsòro gan láwùjọ́ torí àwọn òbí mi di létí'

Emefiele tun n fẹ ki ile ẹjọ kede pe oun le kopa ninu ipade awọn oloṣelu ati lati kopa ninu eto ibibo abẹle wọn.

Ẹwẹ, abala kẹsan an opfin CBN ti ọdun 2007 sọ pe gomina CBN ko gbọdọ ṣe iṣẹ miran lasiko to ba ṣi wa lori ipo gẹgẹ bii gomina CBN.

Emefiele

Oríṣun àwòrán, central bank of Nigeria

Gómìnà báǹkì CBN, Emefiele ń lọ sí ilé ẹjọ́ lórí ilépa rẹ̀ láti di ààrẹ

Gomina Banki apapọ Naijiria, Godwin Emefiele ti gba ile ẹjọ lọ fun ile ẹjọ lati tumọ ofin to de e gẹgẹ bi gomina Banki naa ati ilepa rẹ lati dije fun ipo aarẹ lorilẹede Naijiria.

Laipẹ yii ni awọn eeyan kan ko ara wọn jọ lati ra fọọmu ọlọgọrun miliọnu Naijiria fun Emefiele lati dije fun ipo aarẹ labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC.

Iroyin n sọ pe ile ẹjọ giga apapọ Naijiria to wa nilu Abuja ni wọn gbe ẹjọ naa lọ.

Oniruuru iha lawọn eeyan ti fihan si ipinnu gomina Banki apapọ Naijiria naa lati dije fun ipo aarẹ.

Bi awọn kan ṣe n pariwo pe igbesẹ naa tako ilakalẹ ofin, paapaajulọ ofin ilana ihuwasi fun oṣiṣẹ ijọba lorilẹede Naijiria; ti wọn si n ke si Emefiele pe ko kọwe fipo rẹ silẹ bi o ba nifẹ si didu ipo aarẹ, tabi ki aarẹ Buhari funrarẹ o yọọ nipo.

Àkọlé fídíò, Agbẹjọ́rò Abdullateef Lanre Abdullahi sọ pàtàkì ìbálòpọ̀ àti ìmọ́tótó láàrin lọ́kọláya

Iwe iroyin ojojumọ The Punch lorilẹede Naijiria fi iroyin kan sita pe alaga wọọdu kẹfa ni ijọba ibilẹ Ika South nipinlẹ Delta, nibi ti Emefiele ti ṣẹ wa ṣalaye pe fun awọn pe lootọ ati lododo ni gomina Banki apapọ Naijiria naa ti wa fi orukọ silẹ gẹgẹbi ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ni wọọdu naa.

Àkọlé fídíò, Osun spider man: Mo ń ṣe ìtanijí láti gbógunti ìdọ̀tí láwùjọ ló sún mi dé ìdí 'Spider man'

"Bẹẹni, lati oṣu keji ọdun 2021 lo ti fi orukọ silẹ gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ. Nitorina, ọmọ ẹgbẹ oṣelu wa ni.

Ni ọjọ Satide ni gomina Banki apapọ naa ti fi sita loju ewe Twitter rẹ pe oun n reti itọni Ọlọrun lati mọ boya ki oun dije tabi ki oun wawọro.

O ni oun yoo funra oun ra fọọmu ọlọgọrun miliọnu Nairati oun yoo fi dije.