Àwọn iléeṣẹ́ bàlúù ní Nàìjíríà yí ohùn padà lórí wíwọ́gié ìrìnnà òfúrufú nítórí owó epo bàlúù, wọ́n ní àwọn ti da ọ̀rọ̀ náà rò

Baluu kan fẹ fo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹgbẹ awọn onileeṣẹ baluu lorilẹede Naijiria, "Airline Operators of Nigeria, AON, ti so ipinnu rẹ lati woṣẹniran kaakiri gbogbo papakọ ofurufu to wa lorilẹede naa lọjọ Aje rọ na.

Igbesẹ ati maṣe tẹsiwaju pẹlu iyanṣẹlodi naa n waye lẹyin nnkan bii wakati mẹrinlelogun ti wọn kede pe awọn fẹ so gbogbo iṣẹ to nii ṣe pẹlu igbokegbodo kọ baluu awọn rọ nitori owo gegele to gun ori epo baluu.

Gẹgẹ bi ohun ti wọn ṣe lalaye, Naira aadọwaa ni wọn n ra jala epo baluu tẹlẹ, ṣugbọn bayii o ti gbẹnusoke di ẹẹdẹgbẹrin Naira, eleyi ti wọn ni o n mu inira ba owo wọn.

Ẹgbẹ awọn onileeṣẹ baluu lorilẹede Naijiria, "Airline Operators of Nigeria, AON, wa ṣalaye ninu atẹjade kan ti wọn fi sita lalẹ ọjọ Aiku pe fun anfani ọrọ Aje orilẹede Naijiria ati ọrọ abo ni awọn fi tun ero awọn pa lori rẹ.

Àkọlé fídíò, Ó gbé owó fún mi, ó tún ra fóònù ńlá fún mi - Bàbá Onílù Ibadan sọ bó ṣe pàde Àgùnbánirọ̀ tó dáa lọ́lá

Lara awọn lọgalọga ileeṣẹ baluu ni Naijiria to buwọlu atẹjade naa ni Abdulmunaf Sarina, oludari agba ileeṣẹ baluu Azman Air; Shehu Wada, oludari agba ileeṣẹ baluu Max Air; oludari agba ileeṣẹ baluu, Obiora Okonkwo, oludari agba ileeṣẹ baluu, United Nigeria Airlines.

Àkọlé fídíò, Osun spider man: Mo ń ṣe ìtanijí láti gbógunti ìdọ̀tí láwùjọ ló sún mi dé ìdí 'Spider man'

Awọn miran to tun buwọlu atẹjade naa ni, Roy Ilegbodu oludari agba ileeṣẹ baluu, Arik Air; Abdullahi Mahmood, oludari agba ileeṣẹ baluu Aero Contractors; pẹluu Allen Onyema to jẹ oludari agba ileeṣẹ baluu Air Peace.

Àkọlé fídíò, 'Mo fara da ìsòro gan láwùjọ́ torí àwọn òbí mi di létí'

Ṣaaju ni ileeṣẹ ijọba apapọ Naijiria to n ṣe kokaari ọrọ irinna ofurufu ti kọkọ fi ọkan awọn ọmọ Naijiria balẹ pe awọn n jiroro lori ọrọ naa ki irinna ofurufu ma baa dagun lọjọ Aje ọjọ kẹsan an oṣu karun un ọdun 2022.

O fi kun un pe ileeṣẹ baluu Ibom Air, Green Africa Airlines, Arik air, Dana Air, atawọn miran bẹẹ yoo ṣi maa ba iṣẹ wọn lọ.

Baluu kan fẹ fo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Kí nìdí táwọn iléeṣẹ́ bàlúù ní Nàìjíríà ṣe fẹ́ wọ́gilé ìrìnnà òfúrufú ní Nàìjíríà lọ́jọ́ Ajé?

Ẹgbẹ awọn ileeṣẹ to n ṣe owo irinna ofurufu lorilẹede Naijiria, Airline operators of Naijiria ti faake kọri pe gbogbo igbokegbodo ọkọ ofurufu lawọn yoo bẹgi le lọjọ Aje ti ko si ni si baluu kankan ti yoo lanfani ati ṣiṣẹ jakejado orilẹede Naijiria.

Ẹgbẹ naa ni gbogbo ẹbẹ ti ijọba apapọ n bẹ lori ọrọ naa ko lee wọle bẹẹ ni igbesẹ igbẹyinbẹbọ jẹ ti ileeṣẹ ọkọ baluu Ibomair.

Ẹgbẹ awọn ileeṣẹ to n ṣe owo irinna ofurufu lorilẹede Naijiria naa ni bi owo epo baluu ti wọn mọ si JetA1 ṣe gbowolori lati naira aadọwa , (N190) ti wọn n ra a tẹlẹ si ẹẹdẹgbẹrin naira, (N700) bayii lo wa igbesẹ ẹhonu wọn naa.

Lati ọjọ Ẹti ni ẹgbẹ ọhun ti fi ọrọ ẹdun ọkan wọn ranṣẹ si ijọba lorilẹede Naijiria ati gbogbo awọn alẹnulọrọ lori rẹ pe ki wọn wọn tete wa nnkan ṣe si nitori owo epo naa to n fojojumọ gọbọi sii ti fẹ gbẹmi ileeṣẹ awọn.

Baluu kan fẹ fo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileeṣẹ Ibom Air ni awọn ko lee kọ ẹyin si awọn onibara to ti sanwo iṣẹ fun awọn

Ileeṣẹ baluu Ibom Air ni tirẹ ti sọ pe awọn ko ni lee kopa ninu iyanṣẹlodi naa nitori pe awọn ko lee kọ̀ ẹyin si awọn onibara to ti sanwo iṣẹ fun awọn.

Àkọlé fídíò, Ọdún 20 ni ìran ti jáde pé kí n di ààrẹ!'Wàláhì láàrín ọdún kan péré tí mo bá dé Aso Rock, ẹ wo ǹkan tí ...'

Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ baluu IbomAir fi sita lọjọ Satide, o niawọn onibara awọn kan ti san asansilẹ owo fun irinna wọn lọjọ ti iyanṣẹlodi naa fẹ waye ti awọn ko si lee ja wọn ni tanmọn-ọn ki awọn ma baa lugbadi ẹipẹjọ wọn.

Ileeṣẹ baluu naa ni eyi ko sọ pe awọn naa ko mọ bi epo irnna baluu ṣe wọn gogo yii lara o tabi wa ni iṣọkan pẹlawọn akẹgbẹ wọn lori ohun ti wọn n ja a fun.

Buhari, Aarẹ NAijiria gun Baluu ijọba kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Arowa ti ijọba apapọ pa sawọn ileeṣẹ baluu ni Naijiria.

Ijọba apapọ pẹlu ti kọ si awọn onileeṣẹ baluu ni Naijiria naa lati bu omi suuru mu ki wọn si dakundabọ fi iye denu lori iyanṣẹlodi wọn naa.

Ijọba apapọ ni igbesẹ ti n lọ labẹnu lati yanji ẹhonu wọn.

Àkọlé fídíò, 'Gbogbo àgbáyé kódà America ló ń bọ̀ wá sí Omuo-Ekiti láti wá forí balẹ̀ ní Ààfin ńlá tí yóò sọ̀kalẹ̀ látọ̀run'

Minisita feto irinna ofurufu ni nIajiria, Hadi Sirika ninu atẹjade kan ti amugbalẹgbẹ fun un lori ọrọ ibaṣepọ pẹlu araalu, James Odaudu fi sita ṣọ pe, "Nigba ti igbesẹ lati yanju ẹdun wọn n lọ lọwọ, a n rawọ ẹbẹ sawọn ileeṣẹ baluu naa lati ro ti ọpọlọpọ wahala ati inira ti igbesẹ wọn naa le e mu ba awọn arinrinajo lati Naijiria ati oke okun."

Àkọlé fídíò, Banji Akitoye: Yoruba Nation nìkan ni 'Only Solution' lásìkò yíì, A kò kórira ẹ̀yà tó kù