World Most Dangerous Road: Kí ló le ṣe okùnfà kí ènìyàn ṣe ìrìnàjò lórí ọ̀nà ikú?

Ọ̀nà ikú

Àìrìn jìnà ni a ò rí abuké ọ̀kẹ́rẹ́, onírúurú àrà ń bẹ lókè eèpẹ̀.

Ní orílẹ̀ èdè Bolivia, tó wà ní ẹkùn gúúsù Amẹ́ríkà, ọ̀nà kan wà tí wọ́n ń pè ní ọ̀nà ikú nítorí bí ó ṣe tóóró tó àti wí pé kò gba ọkọ̀ méjì papọ̀ lẹ́yìn ọkọ̀ kan tó bá ń rìn lórí rẹ̀.

Ọ̀nà márosẹ̀ náà tó jẹ́ kílómítà mẹ́rìnlélọ́gọ́ta ni fífẹ̀ rẹ̀ kò ju mítà mẹ́ta lọ pẹ̀lú àwọn kọ̀rọ̀ àti ìyànà lóríṣiríṣi.

Àwọn ẹlẹ́wọ̀n Paraguay, lẹ́yìn ogun Chaco tó wáyé láàárín ọdún 1932 sí 1935, ló la ọ̀nà náà.

Ọ̀nà ọ̀hún tí ilé ìfowópamọ́ ìdàgbàsókè ilẹ̀ Amẹ́ríkà pè ní ọ̀nà tó léwu jùlọ ní àgbáyé ló gbẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1990.

Àkọlé fídíò, 'Gbogbo àgbáyé kódà America ló ń bọ̀ wá sí Omuo-Ekiti láti wá forí balẹ̀ ní Ààfin ńlá tí yóò sọ̀kalẹ̀ látọ̀run'

Kò dín ní ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún kan mítà tí ọ̀nà náà fi ga sí ilẹ̀ tó sì ṣe tóóró tó jẹ́ wí pé agbára káká ni ọ̀kadà tàbí kẹ̀kẹ́ yóò fi kọjá lára ọkọ̀ lójú ọ̀nà náà láì kọlu ọkọ̀ ọ̀hún.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà yìí léwu púpọ̀, ó jẹ́ ọ̀nà tó máa ń wu àwọn ènìyàn tó bá fẹ́ràn ìnàjú láti lọ nítorí àwọn ohun mèremère tó kún ojú ọ̀nà náà.

Ọ̀nà ikú

Kí ló le mú ènìyàn láti gbé ọkọ̀ sórí ọ̀nà ikú?

Ọ̀nà yìí ló já sí ẹkùn Yunga níbi tí wúrà àti coca sodo sí.

Tí ènìyàn bá ti rin ìrìn wákàtí méjì gbáko pẹ̀lú ọkọ̀ lórí ọ̀nà ikú yìí, Coroico ni ènìyàn yóò já sí tó jẹ́ ibi tí wọ́n ti ń wà wúrà (góòlù) ní ìgbà kan rí.

Ona iku

Coroico jẹ́ ibìkan tí kò ní wu ènìyàn láti kúrò níbẹ̀ nítorí gbogbo àwọn ohun ìgbafẹ́ tó wà níbẹ̀.

Àyè wà ní ojú ọ̀nà náà láti jẹ, mu àti láti sùn, tí ó sì ti ko ipa nínú ìdàgbàsókè tó ti bá orílẹ̀ èdè Bolivia báyìí.

Àkọlé fídíò, 'Ọ̀gá ni ooru Nàìjíríà lẹ́gbẹ́ orílẹ̀èdè ti mo ti wálé; Bí mo ṣe parí iṣẹ́ 'AC' tó ń ló iná òòrùn rèé'

Coca jẹ́ ohun tó pàtàkì sí àṣà ẹkùn gúúsù Amẹ́ríkà

Nítorí ilẹ̀ ọlọ́ràá tí Yunga àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ òjò tó máa ń rọ̀ níbẹ̀ ti sọ́ di agbègbè tó jẹ́ mímọ̀ fún ètò ọ̀gbìn.

Ó jẹ́ ibi tí àawọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀yà bíi Tiwanaku àti Inca tí máa ń gbin oúnjẹ bíi kọfí, ọ̀gẹ̀dẹ̀, ọsàn, ẹ̀gẹ́, coca àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Láti ọjọ́ pípẹ́ ni coca ti jẹ́ ohun èlò pàtàkì fún àṣà gúúsù Amẹ́ríkà, tí Bolivia sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀ èdè tó ń pèsè rẹ̀ lọ́pọ̀ yanturu.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀ ni Bolivia fi jin gbígbin coca, tí ìdá méjì nínú mẹ́ta rẹ̀ sì wà ní Yunga.

Àkọlé fídíò, Ó gbé owó fún mi, ó tún ra fóònù ńlá fún mi - Bàbá Onílù Ibadan sọ bó ṣe pàde Àgùnbánirọ̀ tó dáa lọ́lá

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ àwọn ẹ̀yà Spain dẹ́yẹ sí lílo coca, ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n ti mọ ìwúlò rẹ̀ fún ìwòsàn, oúnjẹ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ní lò ó.

Láti bí ọdún ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́jọ báyìí ni wọ́n ti ń lò ó níbi ayẹyẹ ètò ẹ̀sìn, gẹ́gẹ́ bí owó, òògùn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.