Ekiti man to die by hanging: Wọ́n ṣèdájọ́ ikú fún ẹni ọdún 42 l'Ekiti lẹ́yìn tó pa Ọba aládé

Oríṣun àwòrán, Sang Hyun Cho/Pixabay
Ile ẹjọ giga kan niluu Ado Ekiti ti ni ki wọn lọ yẹgi fun okunrin ẹni ọdun mejilelogogji kan lẹyin to jẹ eṣun ṣiṣekupa ori ade kan.
Nigba to n ṣedajọ naa, adajọ Olukayode Ogundana sọ pe oun kọ lati gba awijare ọdaran naa pe o ni arun ọpọlọ wọle.
O ni "Idajọ ile ẹjọ yii ni pe ki wọn lọ yẹgi fun iwọ Ademola Omoniyi, titi ti ẹmi yoo fi bọ lẹnu rẹ."
- Òkú obìnrin yìí kan ìlẹ̀kùn pósí gbà-gbà-gbà pé òun ò kú lọ́jọ́ ìsìnkú rẹ̀! Kàyéfì tuntun
- Ikú àwọn Sójà tọkọ-taya tí wọ́n gé lórí kò yẹ àwùjọ ọmọ ènìyàn rárá - Ààrẹ́ Buhari
- Kí ló fa gbas-gbos láàrín àwọn òṣèrébìnrin méjì, Laide Bakare àti Eniola Badmus?
- Ọmọ orílẹ̀èdè Lebanon tó gba 'One way' l'Eko fi ọkọ̀ fọ́ ẹsẹ̀ obìrin kan
- Wo ǹkan 21 tó yẹ kí obìnrin mọ̀ nípa ojú abẹ́ rẹ̀, Vagina
- Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá ti sọ ìgbésẹ̀ tuntun tí wọ́n fẹ́ gbé nípa ẹ̀sùn àwọn tó ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ajá
- Ògo Naijiria yóò padà wá tí mo bá di Ààrẹ - Pasitọ Tunde Bakare
- Gueterres, Ìrìn asán ni ìrìn rẹ, tó o bá bẹ àwọn ibi tí Fulani ti n ṣe ọṣẹ́ ní Nàìjíríà- Akintoye
- Fayemi ní òun ṣetán láti gbéná wojú àwọn alágbára tí kò jẹ́ kí Nàìjíríà tẹ̀síwájú
"Ki Ọlọrun ko boju aanu wo ẹmi rẹ."
Wọn pe ọdaran naa lẹjọ lori ẹsun kan ṣoṣo, tii ṣe ẹsun ipaniyan, eyii to ẹsun iwa ọdaran to wa ni abala 316, ti ijiya rẹ si wa ni abala 319 ofin ipinlẹ Ekiti ti wọn gbe kalẹ lọdun 2012.
Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye
Iroyin ni ọdaran naa ṣekupa Ọba Gbadebo Olowoselu keji, to jẹ Onise Odo-Oro Ekiti, logunjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun 2018 ni ilu Odo Oro, to wa ni ijọba ibilẹ Ikole Ekiti.
Ọkan lara awọn oloye ilu naa to jẹri tako Omoniyi ṣalaye bi isẹlẹ naa ṣe waye nile ẹjọ.
O ni "A wa ni aafin lọjọ naa lọhun ti a si n ṣe ipade Onise ni nnkan bi aago meje aarọ."
"Ki ipade naa to bẹrẹ ni Omoniyi wọ inu aafin to si joko soro aga kabiesi, amọ awọn oloye le kuro nibẹ."
"Lẹyin ipade naa, afurasi naa kọlu Onise ati akọwe rẹ lasiko ti wọn n pada si aafin."
"Omoniyi gun oloogbe naa lọbẹ, o si bẹrẹ si n kede ara rẹ gẹgẹ bii ọba."
Lọna ati fidi ẹri rẹ mulẹ, agbẹjọro ijọba, Adegboyega Morakinyo ke si ẹlẹri marun un, o gbe ẹsi ayẹwo dokita kalẹ, ọrọ akọsilẹ afurasi naa ni agọ ọlọpaa ati ọbẹ to fi gun oloogbe naa niwaju adajọ.
Amọ ọdaran naa lasiko to n sọrọ ko pe ẹlẹrii kankan.
Lẹyin awijare agbẹjọro ijọba ati agbẹjọro olujẹjọ, adajọ sọ pe o jẹbi ẹsun ti wọn fi kan, o si ni ki wọn lọ yẹ igi fun.
















