Dead woman bangs on coffin: Bí wọ́n ṣe gbọ́ pé òkú Rosa Isabel ń pariwo látinú pósí ara rẹ̀ rèé

Rosa Isabel

Oríṣun àwòrán, Metro Uk.

Eto isinku kan to n ṣẹlẹ ni ilẹ Peru dede tuka nigba ti eeyan ti wọn gbe sinu posi lati lọ ri bọlẹ dede n kan ilẹkun lati inu posi.

Gẹgẹ bi iwe iroyin Metro ṣe fi fidio naa sita, ẹbi Rosa Isabel Cespedes Callaca ti pejọ pọ ni ilu Lambayeque lati ṣe isin idagbere ikẹyin fun ni ire to lọ amọ to pada wa ni ọjọ Kẹrindinlọgbọn oṣu Kẹrin ọdun 2022.

Rosa ti ṣaaju ni ijamba ọkọ to buru jai kan loju ọna ni ẹkun Chiclayo-Picsi eyi to mu ẹmi àna rẹ lọ ti awọn mọlẹbi rẹ mii ti wọn jọ wa nibẹ si farapa yanayan.

Àkọlé fídíò, 'Gbogbo àgbáyé kódà America ló ń bọ̀ wá sí Omuo-Ekiti láti wá forí balẹ̀ ní Ààfin ńlá tí yóò sọ̀kalẹ̀ látọ̀run'

Lẹyin ijamba yii ni wọn ti kede rẹ pe o ku ti wọn si ti gbe e sinu posi lati lọ ṣe isinku rẹ.

Amọ bi awọn mọlẹbi rẹ ṣe gbe posi oni pako ti wọn fi n gbe e lọ lori ejika ni wọn bẹrẹ si ni gburo nkan abami.

Wọn ba gbe posi silẹ, wọn si ṣi i lati mọ ki lo ṣẹlẹ -

Ibi isinku Rosa

Oríṣun àwòrán, Metro Uk.

Afi ti wọn ri arabinrin wọn bo tilẹ jẹ pe o ti rẹ ẹ gidi gan, oju rẹ la silẹ kedere to si n wo gbogbo wọn loke.

Olutọju ọgba isinku ti wọn wa ṣalaye fun awọn oniroyin pe: "niṣe lobinrin naa la oju rẹ silẹ to n laagun. Lọgan ni mo lọ si ọfiisi mi ti mo si lọ pe awọn ọlọpaa".

Àkọlé fídíò, Wo ohun tí Professor Peller wí tó kó bá a gẹ́gẹ́ bí ìyàwó rẹ̀, Lady Peller ṣe tú u síta

Awọn mọlẹbi ti ọrọ yii jẹ iyalẹnu fun sare gbe Rosa pẹlu bo ṣi ṣe wa ninu posi rẹ lọ si ile iwosan Referential Hospital Ferrenafe ni Lambayeque.

Kete ti wọn de ibẹ, awọn Dokita ri i pe Rosa ni ami eemi iye di diẹ ninu amọ ti ko lagbara rara bẹ si ni wọn sare gbe e sori ẹrọ to n ran eemi lọwọ.

Rosa Isabel

Oríṣun àwòrán, Metro Uk.

Amọ, ọrọ naa buru sii, o si ku lẹyin wakati diẹ si asiko naa.

Ẹwẹ, awọn mọlẹbi rẹ ti wọn ni lati ṣe idagbere lẹmeji ti n beere fun oniruuru alaye ti wọn si ni awọn n fẹ idahun.

Wọn fi ibinu wọn han si awọn alaṣẹ ile iwosan ti wọn wa nitori wọn ti kede rẹ nigba akọkọ pe o ti ku.

Ọkan lara awọn agba ile wọn lobinrin ti ko fẹ darukọ ara rẹ sọ fun awọn oniroyin ilẹ naa pe: "A fẹ mọ ohun to faa ti aburo mi taji lana, nigba ta n gbe e lọ fun isinku rẹ.

'A ni fidio rẹ nibi to ti n gba posi ti a ṣii".

Awọn mọlẹbi Rosa fura pe boya o kan wa ni ipo aimọ nkankan ni lẹyin to ni ijamba ọkọ naa eyi to lee ṣalaye idi ti wọn fi kede rẹ pe o ti ku.

Àkọlé fídíò, Èmi nìkan ni ikú Alaafin dùn jù ní gbogbo ayé yìí torí èmi nìkàn ṣoṣo ni mo mọ̀ ǹkan ... - Baba Kekere

Ileeṣẹ Ọlọpaa orilẹede Peru ni awọn ti n ṣiṣẹ lati ṣewadii ohun to ṣẹlẹ ni ileewosan ẹkun Lambayeque - nibi ti Rosa ti kọkọ gba itọju eyi ti wọn fi ni o ku.

Nibayii, awọn mọlẹbi Rosa mẹta ti wọn jọ wa ninu ijamba naa amọ ti awọn fara pa ni iroyin sọ pe ara wọn ti n ya diẹ diẹ nileewosan amọ ti ipo ti wọn wa buru gidi.

Ki ni awọn eeyan n sọ nipa iku-ajinde-ati iku Rosa?

Rosa Isabel

Oríṣun àwòrán, Metro Uk.

Eeyan kan ni ki wọn to maa kede pe awọn eeyan ku, ayẹwo akọṣẹmọṣẹ ṣe pataki. O ni awọn ọgba isinku to ti ni iriri awọn oku to n gbiyanju ati jade ninu posi amọ ti wọn pada ku iku gbona wa.

Esi

Oríṣun àwòrán, Metro Uk.

Eeyan kan ni oun mọ pe awọn eeyan to ba wa ni ipo aimọ nkankan ṣi maa n mi torinaa, kilode ti wọn o ko firi eleyii.

Eeyan kan ni ko yẹ ki awọn eeyan maa kanju ṣe isinku bo tilẹ jẹ bi ọjọ keji ti ẹni naa ku.

Esi

Oríṣun àwòrán, Metro Uk.