Baba Suwe: Suwebatu sọ ìdí tí wọn kò fi sin olóògbé ní kété tó kú

Posi Baba Suwe

Eto isinku Baba Suwe ti waye nile rẹ to wa nilu Ikorodu nibi ti tẹbi tara ati awọn akẹẹgbẹ rẹ peju si.

Àkọlé fídíò, Àwọn òṣìṣẹ́ Adedoyin jẹ́wọ́ fún wa pé àwọn pa àbúrò mi, ọ̀gá Adedoyin sì mọ̀ síi - Ẹ̀gbọ́n Timothy Adegoke

Ilana ẹsin Islam ni wọn fi sin gbajumọ alawada naa eyi ti awọn agbaagba ninu ẹsin Islam dari rẹ.

Amọ ohun to n ya ọpọ eeyan lẹnu nipa ilana isinku Baba Suwe naa ni bi wọn se gbe oku rẹ sinu posi olowo iyebiye wa sile rẹ.

Posi naa si ni wọn gbe sori tabili kan, ti wọn si siju oku rẹ silẹ nibi ti wọn tẹ ni itẹ ẹyẹ si.

Awọn olorin Brigade si n kọrin fun awọn eeyan lati se ẹyẹ fun oloogbe, gẹgẹ bi awọn onigbagbọ ti maa n se.

Baba Suwe ati Suwebatu

Amọ ọpọ eeyan lo n beere pe ki lo de ti wọn gbe oku oloogbe naa sinu posi nigba to jẹ pe ilana musulumi ni wọn fẹ sin.

Gẹgẹ ba se mọ pe patako gbọọrọ ni wọn maa n fi gbe oku musulumi, ti wọn kii si fi posi sin wọn.

Awọn ọmọ, ẹbi ati akẹẹgbẹ Baba Suwe lo fẹ ki wọn fi posi sin:

Aya akọfẹ Baba Suwe, Ayọdele, ti oun naa si jẹ osere tiata, ti ọpọ eeyan mọ si Suwebatu salaye fun BBC Yoruba idi ti eyi fi ri bẹẹ.

Ayodele ni lootọ ni awọn fẹ fi posi sin ọkọ oun, Baba Suwe, bi o tilẹ jẹ pe musulumi ni ko to jade laye.

"Posi la fẹ fi sin Baba Suwe, bi awọn ọmọ ati ẹbi rẹ se fẹ niyẹn.

Olorukọ ati olokiki ni Baba Suwe, awọn ọmọ ati ẹbi ko si fẹ ki wọn sin bii aja.

Idi ree ta se fẹ se ẹyẹ nla fun gẹgẹ bii eeyan pataki to jẹ ni awujọ."

Àkọlé fídíò, Baba Suwe: Bi eto isinku Babatunde Omidina se lọ ree

Alaye ree ti a ko fi sin Baba Suwe ni kete to ku:

Nigba to n salaye idi ti wọn ko se sin Baba Suwe ni kete to ku, ti wọn si fi ọjọ mẹta silẹ lẹyin to ku, ki wọn to sin.

Aya akọfẹ oloogbe naa ni ọmọ oloogbe meji lo wa lẹyin odi, ti wọn si nilo akoko diẹ ki wọn to de lati wa se ẹyẹ ikẹyin fun baba wọn to lọ.

Idi si ree ti wọn ko fi le sin oloogbe naa ni kete to ku gẹgẹ bi ẹlẹsin Islam.

Ayodele ni Baba Suwe bi ọkunrin ati obinrin, ti oun pẹlu Moladun, to jẹ osere tiata ati awọn mii si bimọ fun.

O ni itọju gbogbo wọn si wa lọwọ oun bayii, bẹẹ lo n rawọ ẹbẹ si Ọba Oke pe ko ba oun tọju gbogbo wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

ba saare Omoladun ni wọn sin Baba Suwe si:

Bakan naa ni aya akọfẹ Baba Suwe tun salaye lori saare to wa lẹba ibi ti wọn sin ọkọ rẹ si.

Ayodele ni saare osere tiata mii to jẹ aya Baba Suwe, eyiun Omoladun ni iboji naa.

O ni Omoladun bimọ fun Baba Suwe, awọn mejeeji si ti fi iku se agba, idi ree tawọn se n sin wọn papọ.

Amin iyasọtọ kan

Bí ètò ìsìnkú Baba Suwe yóò ṣe lọ rèé, bó ṣe ń wọ ilẹ̀ sùn lónìí

Babatunde Omidina, Baba Suwe

Oríṣun àwòrán, Omidina Family

Yoruba ni awaye ku ko si, ko si ẹni ti ko ni ku, ko si si ẹni ti oko baba rẹ ko ni di igboro.

Bo se ri gan ree fun gbajumọ osere tiata to jade laye, Babatunde Omidina ti ọpọ eeyan mọ si Baba Suwe.

Ọjọ Aje, ọjọ Kejilelogun, osu Kọkanla, ọdun 2021 ni Baba Suwe dagbere faye lasiko aisan ọlọjọ pipẹ lẹni ọdun mẹtalelọgọta.

Nibayii na, awọn ẹbi oloogbe ti fi ikede sita lori bi eto isinku Baba Suwe yoo se lọ ni Ọjọbọ, ọjọ Kẹẹdọgbọn osu Kọkanla ọdun 2021.

Atẹjade kan ti ọmọ oloogbe, Adesola Omidina fisita loju opo Instagram rẹ ni oni Ọjọbọ ni wọn yoo gbe oku oloogbe naa wọ kaa ilẹ nilana ẹsin Islam.

Ohun ti Adesola Omidina kọ soju opo Instagram rẹ

Oríṣun àwòrán, omo_omidina/Instagram

Atẹjade naa ni ile oloogbe to wa ojule Kẹrindinlgbọn, opopona Oluwatimiro, ibudokọ Ewu-Elepe, ni opopona Ijede nilu Ikorodu, ni wọn yoo ti sin Baba Suwe.

Deede aago mẹwa owurọ ni eto isinku naa yoo bẹrẹ́

Adesola Omidina ni awọn mọlẹbi oloogbe yoo kede ayẹyẹ isinku nigba to ba ya.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bi gbogbo eto isinku Baba Suwe ba si se n lọ, nileesẹ BBC Yoruba yoo maa mu wa fun yin, ẹ ku oju lọna.

Ọjọ Aje, ọjọ Kejilelogun osu Kọkanla ọdun 2021 ni agba osere tiata naa, tii tun se adẹrinposonu ti ọpọ eeyan mọ si Baba Suwe ki aye pe o digbose.

Ọdun mẹtalelọgọta ni alawada naa lo loke eepẹ, ko to dagbere faye lasiko aisan ọlọjọ pipẹ to ba finra.

Àkọlé fídíò, Murphy Afolabi: Kò dùn mí tí wọn bá ṣe yẹ̀yẹ́ mi torí mò fi sí pe ṣí, èdè Osogbo ìlú mi ni