Sunday Igboho: DSS bẹ ilé ẹjọ́ láti gbà òun láàyè kó gbé Igboho wá sí Nàìjíríà kúrò ní Cotonou

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Sunday_igboho1/Instagram

Ajọ ọtẹlẹmuyẹ Naijiria, DSS ti rọ ile ẹjọ giga to wa niluu Ibadan wi pe ko so aṣẹ to pa pe oun ko gbọdọ fọwọ kan Sunday Igboho rọ.

Ajọ DSS sọ fun ile ẹjọ pe ti Igboho ba pada si Naijiria, ni awọn yoo to ni lanfani lati pe ẹjọ kotẹmilọrun.

Agbẹjọro Igboho, Yomi Aliu, SAN to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe, igba akọkọ ree ti DSS yoo tu asiri pe awọn lo ti Igboho mọle ni lorilẹede Benin Republic.

Lori ogun biliọnu naira owo gba ma binu ti ile ẹjọ paṣẹ tẹlẹ pe ki ajọ DSS san fun Igboho, lori bi wọn ṣe se ikọlu si ile rẹ niluu Ibadan, DSS ni owo naa pọ ju ohun ti awọn le san lọ.

Wọn ni sisan aduro owo yii fun Igboho le ṣakoba fun ọrọ aje orilẹede Naijiria niroti owo naa pọ lapọju.

Idajọ ile ẹjọ giga

Oríṣun àwòrán, Yomi Aliyu

Amọ, agbẹjọro Aliu sọ fun ile ẹjọ pe, o lodi sofin lati ju Igboho si atimọle lẹyin igba ti ile ẹjọ ti paṣẹ pe wọn o le mu un tabi ṣe ohun kan si i.

Bakan naa ni agbẹjoro Igboho sọ fun ile ẹjọ pe ẹgbẹlẹgbẹ tiriliọnu ni eto iṣuna orilẹede, nitori naa sisan ogun biliọnu naira fun Igboho ko le ṣakoba fun ọrọ aje Naijiria.

Lẹyin atotonu ajọ DSS ati agbẹjọro Igboho, adajọ paṣẹ pe ki banki apapọ Naijiria, CBN san ogun biliọnu naira to sọ tẹlẹ fun Igboho, o pẹ tan ninu oṣu kinni ọdun 2022 to n bọ.

Adajọ wa sun igbẹjọ siwaju si ọjọ kejila oṣu kinni ọdun 2022.

Amin iyasọtọ kan

Ilé ẹjọ́ sún ìgbẹ́jọ́ ọmọlẹ́yìn Sunday Igboho méjì síwájú torí kò sí atúmọ̀ èdè Yorùbá sí Gẹ̀ẹ́sì

Sunday Igboho: Àwọn ẹgbẹ́ alárikwo tó gbvìyànjú láti fún mi ówó gan, mo kọ̀ọ́- Agbẹ́jòrò Suunday Igboho

Ile ejọ giga ijọba apapọ niluu Abuja ti sun igbẹjọ ọmọlẹyin Sunday Igboho meji to yẹ ko waye lọjọ Aje, ọjọ kejilelogun oṣu kọkanla siwaju nitori ko si ẹni to le tumọ ede Yoruba fun wọn.

Jamiu Oyetunji ati Amudat Babatunde wa lara eeyan mejila ti ajọ DSS gbe lọ nigba ko ṣe ikọlu si ile Igboho lọjọ kinni oṣu keje.

Ẹsun onikoko marun un to da lori igbesunmọmi ni ajọ DSS ṣẹṣẹ fi kan awọn mejeeji.

Ninu ẹjọ ti ajọ DSS ṣẹṣẹ pe, ajọ naa sọ pe ibọn ati awọn nkan ija oloro fun igbesunmọmi wa lọwọ, Oyetunji.

Bakan naa ni DSS sọ pe Amudat to jẹ ẹnikeji lo oju opo Facebook rẹ fun ipolongo igbesunmọmi.

Laipẹ yii ni ile ẹjọ paṣẹ pe ki ajọ DSS fun awọn ọmọlẹyin Igboho mejila ti wọn ju si atimọle wọn niluu Abuja ni ominira.

Ti ẹ ko ba gbagbe, agbẹjọro DSS, I. Awo, sọ fun ile ẹjọ lọjọ kẹjọ oṣu kẹsan an pe oun wọ ọkọ awọn ole ti wọn n pe ni ''One Chance.''

Àkọlé fídíò, Timothy Adegoke: Màmá olóògbé ní ògó ilé àwọn ni wọ́n pa, ikú rẹ̀ kò gbọdọ̀ já sásán

O sọ fun ile ẹjọ pe awọn ọdaran to wa ninu ọkọ naa ja faili ẹjọ awọn ọmọlẹyin gba lọ.

Nigba ti asiko to fun ẹjọ naa lọjọ Aje, agbẹjọro wọn, Pelumi Olajengbensi, sọ fun ile ẹjọ pe awọn onibara oun ko gbọ ede oyinbo.

Gbogbo igbiyanju lati ri ẹni to le ṣe ongbufọ fun wọn, pabo lo ja si.

Eyi lo jẹ ki adajọ, Obiora Egwuatu, sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹrinlelogun oṣu kinni ọdun 2022.

Eeyan meji lo jẹ Ọlọrun ni pe lasiko ti ajọ DSS ṣe ikọlu si ile Igboho lagbegbe Soka ni Ibadan.

Lẹyin naa ni Igboho fun ra rẹ fi Naijiria silẹ ti o si mori le orilẹede Germany.

Ṣugbọn awọn agbofinro mu un pẹlẹ iyawo rẹ lọna ajo wọn niluu Cotonou nibi ti Igboho ti wa lẹwọn lati igba naa.

Àkọlé fídíò, EndSARS Victims: Ìyá méjì nínú mẹ́ta ti kú nínú àwọn ọmọ tí ọlọ́pàá gbé àmọ́ torí ìwọ́de