Endsars Anniversary: Àwọn alátilẹ̀yìn Sunday Igboho darapọ̀ mọ́ ìwọ́de ENDSARS ní ìlú Ibadan

ENDSARS

Nibi iwọde ENDSARS to n lọ lọwọ nilu Ibadan lowurọ Ọjọru ni a ti ri awọn alatilẹyin Oloye Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ eeyan mọ si "Sunday Igboho" to darapọ mọ awọn ọdọ ti wọn n ṣe ifẹhonuhan tako ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ti wọn pe ni "SARS".

ENDSARS

Ọkan lara awọn abẹṣinkawọ Sunday Igboho, Alhaji Yusuf Ajikobi lo gbe aworan ẹni to n pe fun idasilẹ orilẹede Oodua naa lọwọ ti wọn si mu ọkanojọkan orin aro bọ ẹnu.

ENDSARS

Lara akọle ti wọn mu lọwọ n fi ariwo bọ ẹnu pe, "ẹ tu Sunday Igboho silẹ, ki i ṣe ọdaran, ki i ṣe adẹrubalu".

ENDSARS

Lati agbegbe Iwo road ni iwọde naa ti bẹrẹ lowurọ oni, igbagbọ si wa awọn oluwọde naa yoo de ọfisi gomina ipinlẹ Ọyọ ni Agodi lati ṣe ifẹhonuhan.

ENDSARS

Jakejado ni ifehonuhan alalaafia ti n waye lonii ni iranti awọn eeyan ti awọn ọdọ fi ẹsun kan wi pe wọn padanu ẹmi wọn ati awọn to fi ara pa ni ogunjọ oṣu kẹẹwa ọdun 2020 lẹnu iloro "Lekki Toll Gate" nibi ti ifẹhonu han ENDSARS ti waye.

ENDSARS