Timothy Adegoke: Agbẹjọ́rò ẹbí olóògbé ń bèèrè fún ẹ̀rọ ayàwòrán CCTV nílé ìtura Hilton

Rahman Adedoyin ati Timothy Adegoke

Oríṣun àwòrán, Rahman Adedoyin

Agbẹjọro ẹbi akẹkọọ fasiti OAU, Timothy Adegoke to ku si ile itura Hilton Hotel ni Ile-Ife, Kayode Ajulo, ti bu ẹnu atẹ lu Ọmọọba Rahmon Adedoyin to ni ile itura naa, lori bi o ti n sọrọ sita lakata awọn ọlọpaa to wa.

Ninu atẹjade to fi sita, Ajulo ni o ṣe ni laanu pe ileeṣẹ ọlọpaa to yẹ ko ṣe iwadii lai ṣegbe fun ẹnikan, ni wọn wa gba fun afurasi lati maa ṣọrọ sita nigba ti iwadii si n lọ lọwọ.

Agbẹjọro to tun jẹ ajafẹtọ ẹni naa tun ni o yẹ ki ileeṣẹ ọlọpaa gbaju mọ iṣẹ wọn, lai fi ti iru eeyan ti ọrọ kan ṣe, ti ko si y ko fi aaye gba ahamọ rẹ lati di ibudo igbohunsilẹ lori afẹfẹ.

Bakan naa ni Ajulọ ni ko si ani ani pe fọnran ohun afurasi naa to jade sori ayelujara wa lati da rugudu silẹ ni, ko si pagidina eto idajọ.

O fikun pe ba ba wo iru iku abami ti Timothy ku, se lo yẹ́ kileesẹ ọlọ̀paa sisẹ bii akọsẹmọsẹ, ki wn si se iwadi wọn lọna to ba ofin mu, lai naa ni bi ẹni ti ọrọ kan se kanka to lawujọ wa.

Àkọlé fídíò, EndSARS Victims: Ìyá méjì nínú mẹ́ta ti kú nínú àwọn ọmọ tí ọlọ́pàá gbé àmọ́ torí ìwọ́de

"Otitọ ni pe a ko le ba awọn ọlọpaa ṣiṣẹ wọn, ṣugbọn ṣe awọn ọlọpaa pese aabo to peye sibi ti oku Ọgbẹni Timothy wa?

Ko si ohun ti ko le ṣẹlẹ si oku arakunrin yii papaa julọ pẹlu bi iwadii ṣe n lọ lọwọ lori rẹ.

Awọn ibeere to ruju nipa oku Timothy ti agbẹjọro rẹ n wa idahun si:

Lati igba ti wọn ti hu oku Timothy nibi ti wọn gbe sọnu si, se ileesẹ ọlọpaa pese aabo to peye si ayika ibi ti wọn gbe oku rẹ pamọ si?

O ni o daju pe oku Timothy kii se akọkọ ti yoo ko agbako nile itura naa, yoo si dara ki wsn maa lo ẹrọ kan to pe ni Ground Penetrating Radar (GPR) lati maa se awari oku ti wọn ba bo mọlẹ.

Awọn ibeere ti a fẹ ki ileeṣẹ ọlọpaa tun wa idahun si ni pe ṣe kamẹra CCTV wa ni ile itura ti Adegoke ku si yii?

Ti ko ba ri bẹẹ, ọrọ naa mu ifura dani nigba naa, ati pe ṣe awọn ọlọpaa ti ṣe ayẹwo ile ọkunrin to ni ile itura yii lati igba ti iṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ?

Lai fi akoko ṣofo rara, gẹgẹ bi agbẹjọro ẹbi Adegoke, a n beere pe ki ileeṣẹ ọlọpaa jọwọ oku oloogbe naa fun ẹbi rẹ lati le sin in ti ayẹwo ti wọn n ṣe lori rẹ lati mọ bi o ṣe ku ba ti pari.

Bakan naa la fẹ mọ boya awọn ọlọpaa ti se ọfintoto ayika ile itura naa nipa fifi imu finlẹ lati wa awọn eroja to se pataki nipa iku oloogbe.

Bi wsn ko ba tii se eleyi, o yẹ ki wsn ti gba asẹ lati lọ wa ayika naa wo, ki wsn le sawari awsn eroja ọhun fun ẹri to daju.

A si tun kepe ọga agba ọlọpaa ni Naijiria lati ri pe idajọ ododo waye lori ọrọ yii.

Ile iṣẹ ọlọpaa ni lati ṣiṣẹ lori awọn akiyesi wa yii gẹgẹ bi agbẹjọro ẹbi oloogbe Adegoke.

Amin iyasọtọ kan

Ikú ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Timothy kú ní Hilton Hotel ní Ile-Ife - Agbẹjọ́rò Adedoyin

Ramon Adedoyin ati timothy Adegoke

Oríṣun àwòrán, timothy adegoke/others

Agbẹjọro fun oludasilẹ ile itura Hilton Hotel and Resort, Ile-Ife, nibi ti akẹkọọ Fasiti OAU, timothy Adegoke ku si, ti sọ pe iku ati ọdọ Ọlọrun lo pa a.

Amofin Williams Abiodun sọ pe kii ṣe pe awọn oṣiṣẹ ootẹli naa tabi ọga wọn, Ramon Adedoyin, lo pa oloogbe, ati pe ibẹru ki ọlọpaa mase mu wọn lo jẹ ki wọn ju oku Timothy danu nigba ti wọn ri i.

Ọsẹ to kọja ni iroyin jade pe wọn ri oku Timothy nitosi ootẹli ọhun, lẹyin ti ẹbi rẹ kede pe o di awati.

Idanwo to n ṣe fun iwe ẹri imọ ijinlẹ keji, MBA, lo gbe lati ilu Abuja to n gbe, wa si Ile-Ife, to si gba yaara si ootẹli ọhun.

Ninu ọrọ to ba ileeṣẹ iroyin The Nation sọ, Ọgbẹni Abiodun sọ pe "iku lati ọdọ Ọlọrun ni akẹkọọ naa ku" ni alẹ ọjọ to de si Hilton Hotel and Resort.

Amofin naa sọ pe onibaara oun, Adedoyin, kọkọ sọ pe oloogbe ko gba yara nile itura rẹ, nitori pe ko si akọsilẹ kankan ninu apo asunwọn ootẹli naa pe Timothy san owo fun yaara.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, inu apo asunwọn oṣiṣẹ ootẹli naa kan, Adesola Tobiloba, to jẹ olugbaniwọle (Receptionist) ni otẹẹli naa lo san owo si.

"Tobiloba si ti jẹwọ fun awọn ọlọpaa pe oun ati akẹẹgbk oun kan ni awọn jọ pin owo naa, ti wọn o si kọ sinu iwe akọsilẹ ileeṣẹ".

Abiodun sọ pe ibẹru pe awọn ọlọpaa yoo mu wọn lo jẹ ki wọn o ju oku Timothy sinu igbo nitosi ootẹli naa nigba ti wọn ri.

O tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe, gbogbo awọn oṣiṣẹ ootẹli naa ti ọlọpaa mu lo jẹwọ pe lootọ ni Timothy sun sibẹ, ṣugbọn o ku loju oorun.

Bakan naa lo sọ pe awọn agbẹ to ni ilẹ oko ti wọn ju oku Timothy ni oju ọna Ife si Osogbo, si sọ fun awọn ọlọpaa pe kii ṣe pe wọn sin oku rẹ.

Àkọlé fídíò, Àwọn ọ̀dọ́ opó l'obìnrin sọ ìrírí wọn l'awùjọ

Adegoke ni ẹya ara oloogbe kankan ko di awati nigba ti awọn ọlọpaa ri oku naa.

"Iku lati ọdọ Ọlọrun lo ku, nitori pe o fi ọwọ rọ ori ni, to si ya ẹsẹ rẹ mejeeji bi ẹni to rẹ.

"Ko si apẹẹrẹ pe wọn fi ohunkohun ṣe e ko to o ku. Ẹṣẹ kan ṣoṣo ti awọn eniyan yii ṣẹ ni pe wọn fọwọ kan oku naa, ti wọn si ju u sọnu."

Amofin naa tun ni irọ ni iroyin pe Adedoyin ran oun si ẹbi oloogbe lati fun wọn ni owo ẹyin.