Daddy Freeze: Ọmọ Oyedepo gbọdọ̀ ṣàlàyé ìdí tó fi ri bíbélì 15 mọ́lẹ̀ nínú ṣọ́ọ̀ṣì Winners l'Amerika

Daddy Freeze ati Isaac Oyedepo

Oríṣun àwòrán, Daddy Freeze

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Sọrọsọrọ ori redio ati ayelujara, Ifedayo Olarinde, ti ọpọ mọ si Daddy Freeze, tun ti sọrọ tako ijọ Living Faith Church, Winners ti o jẹ ijọ Biṣọọbu David Oyedepo.

Amọ, kii ṣe Biṣọọbu Oyedepo ni Daddy Freeze n ba wi lọtẹ yii, ọmọkunrin rẹ, Pasitọ Isaac Oyedepo to jẹ pasitọ ijọ Winners to wa ni Maryland l'Amẹrika, lo n baa wi.

Daddy Freeze sọrọ yii lẹyin ti Pasitọ Isaac Oyedepo naa sọ ninu iwaasu rẹ kan to wa lori ayelujara pe, ijọ naa ri bibeli mọlẹ si òpó igun ile mẹẹdogun to gbe sọọsi wọn ni Amẹrika duro, gẹgẹ bi opo ti ijọ naa duro le lori bii ọrọ Ọlọrun.

Pasitọ Isaac sọ pe akori iwaasu rẹ fun oṣu yii lo da lori bi bibeli tii ṣe ọrọ Ọlọrun ṣe jẹ opomulero awọn kristẹni.

O sọ ninu iwaasu naa pe ibi gbogbo ti opo wa ninu gbọngan ṣọọṣi to wa ni Maryland ni awọn yọ kuro ti awọn si fi bibeli rọpo wọn.

Àkọlé fídíò, Adejare Adeboye: Olúwa yóò dá gbogbo ohun ta sọnù ní 2020 padà ní ilọ́po méje fún wa

Amọ, Daddy Freeze tu itọ soke, o si fi oju gbaa lori ọrọ naa, o ni ko tọna rara.

Daddy Freeze ni ọrọ dabi ẹni ti ebi n pa ti o wa n fi gaari ra ara, dipo ki o mu un.

Daddy Freeze tun sọ pe ohun ti ọmọ Biṣọọbu Oyedepo sọ dabi ẹni ti ebi n pa ti o wa n fi elubọ pa ara rẹ.

Sọrọsọrọ naa ṣalaye pe, inu ọpọlọ oun, ni oun ri bibeli mọ kii ṣe inu ilẹ nitori o lodi si ọrọ Ọlọrun.

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

O ni kika ni bibeli wa fun, ko wa fun riri mọlẹ ninu ṣọọṣi.

''Idi gan an niyii ti mo fi kepe pasitọ Isaac lati wa ṣalaye oun to ri, ti wọn fi ri bibeli mọlẹ ninu ṣọọṣi.

Nitori ohun to sọ yii tako ohun ti emi mọ nipa ọrọ Ọlọrun,'' Daddy Freeze lo sọ bẹẹ.

Odu ni Daddy Freeze nipa titako awọn ojiṣẹ Ọlọrun, kii ṣe aimọ fun oloko.

Koda o ti figba kan tabuku oludasilẹ ijọ Winners gan an, Biṣọọbu Oyedepo fun ra ri.