Sex with snake: Pásítọ̀ ní kí n gbé ọwọ́ lé ǹkan ọkùnrin ọ̀un, ní ejò dúdú bá jádé, tó sí bámílòpọ̀

Ejo

Oríṣun àwòrán, Matteo86

Obinrin ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn kan ti jẹwọ lori eto ileeṣẹ redio kan pe lootọ ni oun maa n ba ejo ni ibalopo, ti oun si tun kopa ninu eto ti wọn ti n jẹ ẹran eeyan.

Ninu ifọrọwerọ kan pẹlu Emmanuel Mwashumbe ati Shuga Boy, lori redio kan ni Kenya, obinrin ọhun, Cecilia Wambui, ṣalaye ohun to sun un de idi iwa ara meeriri naa.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, inu iya ati iṣẹ ti wọn bi oun si lo ṣokunfa bi oun ṣe maa n ba oriṣirṣi ọkunrin jade.

Ejo

Oríṣun àwòrán, Twitter

O ni "ọmọ ọdun mẹtadinlogun ni mo wa nigba ti mo pade ọrekunrin mi akọkọ, ọkunrin naa wu mi lori nitori o jẹ awakọ, o ni erọ tẹlifiṣọn pẹlu ohun elo idana gaasi."

Àkọlé fídíò, Ọkọ mi bá àwọn ọmọ wa sọ̀rọ̀ lágo kan kó tó wọ bàálù tó já, àmọ háà! - Ìyàwó Olasunkanmi Olawunmi

"Bo tilẹ jẹ pe aarin oṣu mẹta pere ni a fi ara wa silẹ, o fun mi loyun ṣugbọn mo sẹ oyun naa, mo si tun ṣẹ aimọye oyun lẹyin re."

Cecilia ṣalaye pe laarin igba ti oun wa ni ọmọ ọdun mẹtadinlogun si marundinlọgbọn, oun ṣe igbeyawo pẹlu ọkunrin marun, ti oun si tun ba ọkunrin bii ọgọrun ni ibalopọ.

Ṣugbọn nigba to di ọdun 2019 ni Cecilia ri ẹwọn he.

O ni lara akitiyan oun lati di ẹni igbala lo mu oun darapọ mọ ayederu ijọ kan, nibi ti oun ti maa n ba awọn ẹmi okunkun ni ibalopọ.

Gẹgẹ bii nnkan to sọ, "mo le dede joko soju kan, ki n dẹ dede ri ara mi ni ile igbokusi ati iboji."

Àkọlé fídíò, Ẹ̀yin olórin ẹ̀mí tó ń bóra, lo èékáná gígùn, oò yàtọ̀ sí aṣẹ́wó hòtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n ń gbé bíi súùtì Pepper Menti - Bola Are

Ibalopọ mi pẹlu awọn ẹmi okunkun naa dun mọ mi to bẹẹ ti mi o nifẹsi ati maa ba ọkunrin ni ibalopọ mọ nitori aẉon ẹmi naa maa n tẹ mi lọrun daadaa."

Cecilia sọ siwaju si pe pasitọ ijọ ọhun lo fun oun ni ọkọ lẹyin to sọ pe ọkunrin naa ni ori kọ mọ oun lati ọrun wa.

O tẹsiwaju pe gbogbo igba ni oun maa n ri pasitọ naa loju ala, ti yoo sọ fun oun pe ki oun gbe ọwọ le nnkan ọmọkunrin rẹ, lẹyin naa ni ejo dudu kan yoo jade.

Leyinorẹyin, o ni oun bẹrẹ si n ṣaisan ṣugbọn pasitọ oun yii ko gba ki oun lọ ile iwosan.

Aworan ejo lara eeyan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lọwọ yii, Cecilia ti fi ile ijọsin naa silẹ.

Bo tilẹ jẹ pe o kọ lati fi orukọ ile ijọsin naa lede, Cecilia ti kọ ọkọ rẹ silẹ, ṣugbọn o ni oun ṣi maa n ri ni ojojumọ ti oun ba ji laarin oru ninu ile oun.

Cecilia pari ọrọ rẹ pe oun mọ awọn obinrin marun un miran to jẹ ọmọ ijọ naa, ti wọn si n la irufẹ ohun ti oun la kọja lọwọlọwọ.