Snake Worship in Nigeria: Wo ìlú mẹ́rìn-in tó ń bọ tàbí sin ejò bí ọlọ́run

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ni gbogbo agbaye, awọn eniyan gba wi pe ejo jẹ ẹranko ti eniyan ma n sa fun ti o si yẹ fun pipa ni kete ti eniyan ba fi oju gan an ni rẹ, nitori o ni oro, o si le e bu eniyan san, ti ẹni naa si le gba ibẹ da ero ọrun.
Ni orilẹede Benin Republic, ilẹ ijọsin wa fun ejo, iyẹn ni wọn n pe ni Quidah, ti ọpọlọpọ ẹsin iṣẹṣe ati iṣe abalaye ti ma n waye nibẹ.

Oríṣun àwòrán, Republic of Benin
Amọ ni awọn apa ibikan lorilẹede Naijiria, niṣe ni wọn ri ejo gẹgẹ bi ohun ti a ko gbọdọ fi ọwọ yẹpẹrẹ mu tabi ki a ṣe ni ijamba.
Awọn ilu wọnyii ri ejo gẹgẹ bi ẹranko ti eniyan gbọdọ ṣe itọju rẹ, ti wọn si gbagbọ wi pe ko le e ṣe ẹnikẹni ni ijamba.
- Kí ló ṣe ọkùnrin yìí tó dédé ń sá lọ láàrin ìgboro ní ìhòhò ọmọlúàbí?
- Fayemi ló tó gbangba sùn lọ́yẹ́ láti jẹ ààrẹ Nàìjíríà lọdún 2023- Àwọn lọ́balọ́ba Ekiti
- Glaucoma lè fọ́ gbogbo ènìyàn lójú tán níbí - Dókìtà Nàìjírìà
- Òní ni ìsìnkú àwọn akọni tó bá ìjàmbá ọkọ̀ Bàálù lọ ní Abuja
- Wo àwọn ìlú tó jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ àti èèwọ̀ ni láti kú níbẹ̀
Ni awọn ibo miran, wọn ma n sin ejo gẹgẹ bi ọba ni, ti wọn a si fun ni ọwọ bii ọba to yẹ ki a wari fun.
Lara awọn ilu naa ti wọn ti n bọ ejo ni agbegbe Nembe ni ilu Bayelsa, Idemini ni ipinlẹ Anambra, ipinlẹ Imo ati agbegbe Machina, ni ipinlẹ Yobe.

Oríṣun àwòrán, David Sacks
Agbonda, Kwara
Ni ẹya igbomina nipinlẹ Kwara, ilu Yoruba kan wa to jẹ wipe ninu itan adayeba, ejola ni Ọba wọn.
Ninu iwadii ẹkọ fasiti kan ti akọroyin BBC kan ṣe nigba to wa nile ẹkọ, o fihan wipe ni igba iwasẹ, nkankan ṣẹlẹ nilu Agbonda eyi to mu ki Ọba wọn parada di ejola to si wọ lọ sinu igbo.
Gẹgẹ bi ọmọ ilu Agbonda yii, akọroyin BBC ni agba ile awọn jẹ ko di mimọ pe loore koore ni ejola yii maa n ṣe abẹwo si ilu paapaa bi eeyan kan ba ti bimọ tuntun.
Lati fi aridaju han, titi di oni, ko si bi ẹran igbẹ ṣe wu wọn jẹ, eewọ ni fun gbogbo ọmọ ilu Agbonda ni ipinlẹ Kwara lati jẹ ẹran ejola ni pato.
Nembe, Bayelsa
Laarin awọn araalu Nembe, ni ipinlẹ Bayelsa, wọn gba ejo gbọ gẹgẹ bi ọlọrun ati oosa wọn ti wọn n bọ ni ọsan ati ni oru.
Wọn fẹran ejo to bẹ ẹ gẹ wọn ki n fi ọwọ kan an lati pa abi ṣe ni ijamba, nise ni wọn n bọ ọ, ti yoo si ma a rin laarin wọn lai farapa.
Ti ejo ba wa si agbegbe wọn,tabi ile wọn, wọn ma n pe orukọ rẹ ni ti wọn a si fi ọwọ kan an. Ejo naa a ka jọ, ti wọn a si gbe kuro ni agbegbe naa lọ si ibomiran.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Idemili, Anambra
Ni ipinlẹ Anambra, awọn ara ariwa ati guusu ni kii pe ejo ni orukọ rẹ, 'Eke Idemili'ni wọn ma n pe e ni agbegbe yii, nitori iwariri ti wọn ni fun un.
Ọpọlọpọ ninu awọn eniyan wọn ni wọn dagba pẹlu ejo nla 'python' ti yoo ma rin kaakiri inu ile wọn.
Ohun ti won le ṣe ti ejo ba wọ inu ile ni lati fi igi le e sita. Ohun ti wọn gbagbọ ni wi pe ti ejo naa ba bu enikan san, to ba si pariwo 'Eke' ejo naa yoo wọṣe'hiss', oro rẹ ko si ni ni ipalara fun ẹni naa.
Amọ, ẹni naa yoo fi ọwọ yọ ẹyin ejo naa to wa ni ara rẹ kuro.
Iyalẹnu nipe ko si ẹni to mọ bi awọn eniyan ṣe bẹrẹ si ni sin ejo, amọ awọn babanla wọn ba bẹ ẹ ni, ti awọn naa si tẹlẹ iṣe naa.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ipinlẹ Imo
Bi o ṣe ri ni ipinlẹ Anambra naa ni o ri ni ipinlẹ Imo, pẹlu bi awọn eniyan ṣe fẹran ejo ti wọn si ri gẹgẹ bi ẹranko to ṣọwọn.
Awọn eniyan agbegbe yii ri gẹgẹ bi oluranlọwọ fun wọn, paapaa lasiko ogun abẹle ni agbegbe naa.
Ni agbegbe Mgbidi, ni ijọba ibilẹ Oru, nipinlẹ Imo ni awọn eniyan ṣi ni igbagbọ wi pe ọkan lara ọlọrun wọn ni ejo, ti wọn si n sin ni oju mejeeji.
Ti awọn eniyan ba pa ejo laimọ, o ni awọn etutu ti ẹni oun gbọdọ ṣe abi ko fi oju wina oosa.
Machina, Yobe
Ni ilu Machina, nipinlẹ Yobe, ejo kii ṣe ẹranko nikan ni ọdọ wọn, amọ o jẹ ọkan lara awọn mọlẹbi idile ọba nibẹ.
Awọn ejo yii si n gba ohun gbogbo ti wọn ni etọ si gẹgẹ bi ọkan lara awọn ọmọọba ni agbegbe naa.
Awọn ejo naa ni ẹtọ bii ọmọ eniyan si igbeaye lai si ipalara, ẹtọ lati rin bi o ṣe wu wọn ati ẹtọ lati dọrẹ pọ pẹlụ awọn eniyan to wa ni agbegbe naa.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Lara awọn itan abalaye ni wi pe obinrin to pẹlu awọn oludasilẹ ilu Machina naa bi ejo, eleyii to mu ki wọn ma a bọ lara awọn ejo tabi ẹya ejo ti wọn di idile ọba mu naa.
Ni ọdọdun ti emir ilu naa ba n ṣe ọdun, awọn olutọju awọn ejo nlanla yii ma n gbe wa lati wa ki ọba nitori ọkan lara awọn mọlẹbi ọba ni wọn.
Nigba ti awọn ejo yii ba wa si afin nitori ori oke ti aafin ọhun wa, wọn ma n lọ si abẹ ododo lati lọ ba sibẹ, nitori ibẹ tutu, wọn ki n sa fun awọn eniyan.
Amọ, ti wọn ba wọ yara pẹlu awọn eniyan, awọn agbagba ile ni yoo lọ mu wọn jade si ita.
















