Lateef and Mo’Bimpe: Adebimpe ní òun kò ní fi iṣẹ́ eré tíátà sílẹ̀ lẹ́yìn ìgbéyàwó òun pẹ̀lú Lateef Adedimeji

Oríṣun àwòrán, Instagram/adedimejilateef
Gbajugbaja oṣere ori itage, Adebimpe Oyebade naa ti sọrọ soke lori igbeyawo rẹ to n bọ lọna pẹlu akẹgbẹ rẹ, Lateef Adedimeji.
Lara awọn nkan ti Adebimpe sọ ni pe ko tii si ọrọ ọfẹ laarin awọn mejeeji nigba ti oun sọ pe Lateef kii ṣe ọrẹkunrin oun.
Ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu iwe iroyin Punch, Adebimpe, sọ pe Lateef ko tii kọ ẹnu ifẹ si oun lasiko ti oun sọ ni gbangba pe kii ṣe ọrẹkunrun oun.
- Wo ohun tí ọkọ àti ìyàwó, Lateef Adedimeji àti Bimpe fi síta fúnra wọn to fihàn pé ọjọ́ ti súnmọ́
- Ẹ wo nkan tí àwọn akẹẹgbẹ́ Lateef Adedimeji sọ nípa f'ọ́tò ìgbéyàwó òun àti Adebimpe tó jáde
- Amẹrika ń fẹ́ ìdájọ́ òdodo lórí ìwàdìí ìṣẹ̀lẹ̀ ìwọ́de #EndSARS ní Lekki toll gate
- Wọ́n ti ń bèrè lọ́wọ́ abúrò ọkọ mi pé èlò ni wọ́n fẹ́ gbà, ẹ ṣàánú wa o! - Ìyàwó Timothy tó kú sí Hilton Hotel Osun figbe ta
- Wọ́n lù mí bíi ẹní máa kú, wọ́n ya aṣọ mọ́ mi lọ́rùn nílé Princess kí n tó dé àgọ́ ọlọ́pàá - Baba Ijesha
- Pásítọ̀ onísọjí tó fí ipá bá olóyún oṣù mẹ́jọ sùn ní Ondo, ohun tí a mọ̀ rèé
- Ìkúnlẹ̀ abiyamọ ò! Wo bí arábìnrin yìí ṣé bínú dá omi gbígbóná s'ará ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀
- Àwọn alamí ìjọba kan ti wà láàrín àwa ajìjàgbara Yoruba Nation tó ń bínú pé Sunday Igboho ti ga ju àwọn lọ - Akintoye
- Wọ́n yọ Nàìjíríà kúrò lára àwọn orílẹ̀èdè alákatakítí ẹ̀sì lágbàáyé, ọ̀pẹ́ Buhari sí Anthony Bliken rèé
''Mi o ro pe o tọna lati maa sọ ọrọ aye mi lori ayelujara de bi ọrọ ọrẹkunrin mi.
Mi o nilko lati ṣe bẹẹ nitori n kii ṣe alafẹyẹyẹ obinrin to maa n gbe ọrọ aye ara rẹ kaakiri, gbogbo eeyan lo si mọ mi bẹẹ.
Iru eeyan ti mo jẹ niyẹn, mo sọ ninu ifọrọwerọ ti mo ṣe nigba naa pe ko si nkankan laarin emi ati Lateef.
Ti o dẹ ṣe ri nigba naa niyẹn, nitori Lateef kii ṣe ọrẹkunrin mi nigba naa,'' Adebimpe lo ṣalaye bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, Instagram/adedimejilateef
Nigba to n sọ nipa ayẹyẹ igbeyawo wọn to n bọ lọna, Adebimpe ni kii ṣe igbeyawo idakọnkọ lawọn fẹ ṣe nitori awọn ti ọpọ ero to fi mọ awọn akọroyin pẹlu.
Bakan naa ni Mo'Bimpe sọ pe oun ko ṣetan lati fi iṣẹ oṣere silẹ nitori oun fẹ ṣe igbeyawo pẹlu akẹgbẹ oun.
O ni ikan ko di ekeji lọwọ, nitori naa igbeyawo ko le ṣe idiwọ fun iṣẹ tiata ti oun yan laayo.
Mo'Bimpe ni oun maa gbiyanju lati ri pe igbeyawo oun kẹsẹ jari, ati pe awọn yoo si jọ wa papọ fun igba pipẹ, bakan naa, oun ko ni dakẹ adura.












