Anthoy Bliken: Buhari gbàlejò akọ̀wé Amẹ́ríkà, ọ̀rọ̀ wọn lórí yíyọ Nàìjíríà kúro ninu akatakítí ẹ̀sìn

Ipade Akọwe ilẹ Amẹrika, Anthony Bliken pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, TOLANI ALLI

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti ṣe àpèjúwe yíyọ Nàìjíríà kúrò lára àwọn orilede tí kò ní òmìnira ẹṣin tí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà gẹ́gẹ́ bí nnkan tó dára fún ilosiwaju Naijiria.

O tun soro lori ijabọ àwọn ìgbìmọ̀ tó gbejọ ifiyajeni ọlọpaa Endsars to waye ni ìpínlẹ̀ eko èyí tí aje ibajẹ sì sí mọ àwọn ọmọ ológun àti ọlọ́pàá lórí fún ẹ̀sùn ipaniyan nipakupa.

Aare naa sọrọ nigba ti o gbalejo Akowe ilẹ AMẸRIKA, Anthony Blinken, ni ile ìjọba l'Abuja l'Ọjọbọ.

Lásìkò to ń dúpẹ́ lórí yiyọ Naijiria kuro ninu awọn orilẹ-ede ti o lodi si ominira ẹsin, Buhari ṣe akiyesi pe ominira ẹsin wa ni l'orilẹ-ede yìí ati pe “ko si ẹnikan ti a ṣe idẹyẹ si nítorí igbagbọ tàbí ẹṣin rẹ.

Atẹjade

Oríṣun àwòrán, US Mission in Nigeria

Gege bi o se sọ, ẹkọ jẹ pataki ni orilẹ-ede tí Naijiria "nitori nigbati a ba kọ awọn eniyan kan, awọn ipele kan wa ti wọn kii yoo ṣubu kọjá rẹ lai."

Bakan naa ni aarẹ dupẹ lọwọ orilẹede Amẹrika fun gbigba orilẹ-ede Naijiria laaye lati ra awọn ohun elo ogun lati gbogun ti ìgbésùmọ̀mí ni orilẹ-ede yii, ati lati fi se nnkan ikẹkọ fun awọn ọmọ ogun Naijiria.

“O n ṣe iranlọwọ fun wa lati mu Àlãfíà jọba ní ìhà Ariwa-ila-oorun, ati pe a ti ni ilọsiwaju pupọ lati ọdun 2015.

“A n gbìyànjú pupọ lori aabo, ati pe awọn eniyan ti o kan mọ riri awọn akitiyan wa,” bí o ṣe sọ.

US Secretary of State visit to Nigeria: Anthony Bliken meeting wit Buhari inside fotos

Oríṣun àwòrán, TOLANI ALLI

Àkọlé àwòrán, US secretary of state Anthony Bliken wit Nigeria Vice President Professor Yemi Osinbajo for di State House, Abuja

Washington yọ Naijiria kuro ninu akojọ awọn orilẹ-ede ti o ni awọn ifiyesi ominira ẹṣin ní Ọjọ́rú, ṣaaju ki Akowe ti ilẹ̀ Amẹrika Antony Blinken to wá sí orilẹ-ede gẹgẹ ètò irin-ajo tí ó pinu lati ṣe sì àwọn ilẹ̀ Afirika.

Blinken ṣe ìkéde yìí gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe má ń ṣe lọdọọdún l'Ọjọro ti awọn orilẹ-ede ti o tún wa nibẹ tí jẹ́ Myanmar, China, Eritrea, Iran, North Korea, Pakistan, Russia, Saudi Arabia, Tajikistan ati Turkmenistan gẹgẹbi awọn orilẹ-ede ti o nílò amojuto pataki.

Bakan naa lo tún fi Algeria, Comoros, Cuba ati Nicaragua sinu atokọ yìí fun ailominira ẹsin, ati pe o yan awọn ẹgbẹ alakatakiti tí wọ́n sì tún pẹka kaakiri àwọn awọn ibòmíràn pẹlu, I èyí jẹ́ ọ̀kan pàtàkì tí a wò.

Akọwe ilẹ Amẹrika, Anthony Bliken pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, TOLANI ALLI