Lateef Adedimeji: Nkan tí a mọ̀ nìyíì nípa ìgbéyàwó tí Lateef àti Adebimpe Oyebade

Lateef ati Adebimpe

Oríṣun àwòrán, Instagram/adedimejilateef

Àkọlé àwòrán, Ìgbà akọkọ kọ niyii ti aworan igbeyawo ti jade nipa awọn mejeeji
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Bẹẹni, bẹẹkọ lariwo to gba ori ayelujara lopin ọsẹ to kọja lori gbajugbaja oṣere tiata, Lateef Adedimeji pe o ti ṣe igbeyawo.

Eyi ko ṣẹyin bi fọto 'igbeyawo' oun ati arẹwa oṣerebinrin, Adebimpe Oyebade, ṣe jade sori ayelujara.

Eyi lo mu ki awọn ololufẹ wọn o maa beere pe, ṣe o ṣeeṣe ko jẹ pe wọn ti ṣe igbeyawo ni tootọ?

Eyi waye nitori kii ṣe igba akọkọ niyii ti wọn fi iru fọto bẹẹ sita.

Lateef ati Adebimpe

Oríṣun àwòrán, Instagram/Lateef Adedimeji

Awuyewuye ti waye lori awọn mejeeji ri pe, wọn n fẹ ara wọn.

Fọto imurasilẹ fun igbeyawo, 'pre-wedding shoot' awọn mejeeji jade sori ayelujara lọdun to kọja.

Ṣugbọn, awọn mejeeji pada sọ pe, sinima kan ni wọn ya aworan naa fun.

Lateef ati Adebimpe

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Lateef Adedimeji ati Adebimpe Oyebade ti jọ fi aṣọ igbeyawo ya fọto ri.

Lẹyin ti eruku ẹjọ lọ ọ lẹ lori fọto naa, ni Adebimpe sọ nigba naa pe, Lateef kii ṣe iru ọkunrin ti oun le fẹ.

O ni ọrẹ timọtimọ ni awọn.

Kii ṣe Adebimpe nikan ni iroyin jade pe oun ati Lateef n fẹra.

Iroyin ti jade laimọye igba pe, Lateef ati oṣerebinrin miran, Bukunmi Oluwashina, n fẹ ara wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lọtẹ yii, o dabi ẹni pe ọrọ ẹnu Bimpe yatọ si awọn aworan tuntun yii.

O kọ sabẹ awọn aworan naa to fi sita lori ayelujara Instagram rẹ pe "Adedimeji Lateef, mi o nilo alujanna, nitori pe mo ṣawari rẹ.

Eyi si ti fa ariyanjiyan laarin awọn ololufẹ wọn.

Awọn kan tilẹ sọ pe, o sẹeṣe ko jẹ pe ileeṣẹ to n da awọn aṣọ igbeyawo naa ni wọn n ba polowo ọja.

Akiyesi BBCnipa aworan igbeyawo Lateef ati Adebimpe:

  • Lateef kii lo yẹti tẹlẹ, nitori pe musulumi ododo ni. Ṣugbọn ninu aworan yii, o lo yẹti, eyi to jẹ ọkan lara awọn idi ti o fi ṣoro lati gbagbọ pe fọto igbeyawo gidi ni
  • A tun ṣakiyesi pe, ko si ẹnikẹni ninu awọn akẹẹgbẹ wọn ninu isẹ tiata, to ki wọn ku oriire ayẹyẹ igbeyawo
  • Eyi jẹ nkan to ṣe ajeji lagbo Yollywood. Arire ba ni se ni wọn, wọn kii si fi bo
Àkọlé fídíò, Mama Arsenal: Màmá àgbà yìí máa ń lọ sí ìbùdó tí wọ́n ti ń wo bọ́ọ́lù láti wòran
  • Lara akiyesi wa tun ni pe, ko si oruka igbeyawo lọwọ Adebimpe tabi Lateef ninu fọto tuntun naa. Kayeefi nla miran tun ni eyi jẹ
  • Bakan na ni ko si aworan awọn ẹbi wọn, eyi ti a gbagbọ pe ko ṣeeṣe ki wọn o se igbeyawo lai si pe awọn ẹbi wọn kopa nibẹ
  • Irun ori Lateef naa tun tọka si pe, o ṣeeṣe ko jẹ pe sinima kan ni wọn ya awọn fọto naa fun.
  • Irun ori rẹ dabi ti Dada, eyi ti awọn oloyinbo n pe ni rough curls. Lateef kii ge iru irun yii loju aye
  • Ara awọn nkan mirian tun ni ọrọ ti awọn akẹẹgbẹ wọn bi Bimbo Oshin, ati Debo, a.k.a, Mr. Macaroni sọ lori awọn fọto naa ti Lateef si sita.

Diẹ lara awón to ti ki wọn:

Bimbo Oshin sọ pe "Ẹ ku oriire o, ṣugbọn bawo ni mi o se gbọ nipa igbeyawo naa?

Lateef ati Adebimpe

Oríṣun àwòrán, Screenchot/@adedimejilateef

Mr Macaroni sọ pe "Ẹ mura si..."

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Ju gbogbo rẹ lọ, to ba jẹ pe igbeyawo tootọ ni, tabi ayederu, ọrọ yoo to fi oju han.