Yollywood: Saheed Balogun sìnkú ìyá rẹ̀, Ìròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ lágbo òṣèré lọ́sẹ̀ yìí nìwọ̀nyí

Awọn oṣere tiata to gbabọọlu nibi ọjọ ibi Ogogo

Oríṣun àwòrán, ogogo/instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Nnkan kan lagbo awọn oṣere tiata lọsẹ yii.

Latori afihan sinima, de ori ọjọ ibi kan oku arugbo lo waye laarin awọn oṣere tiata Yoruba ti a mọ si Yollywood lọsẹ yii.

O ya ẹ jẹ ki a gbe wọn yẹwo leni eji.

Fẹmi Adebayọ ṣe afihan sinima Survival of Jelili

Aworan sinima mi adebayo tuntun

Oríṣun àwòrán, femi adebayo/Instagram

Gbogbo wa lo fẹrẹ wo sinima apanilẹrin ti Fẹmi Adebayọ ṣe, to pe akọle rẹ ni Jẹlili, nibayii, o ti tun gbe eyi ti a lee pe ni ipadabọ Jẹlili lẹẹkeji jade bayii. Akọle to fun un ni "Survival of Jelili"

Laarin ọsẹ yii naa lo ṣe afihan rẹ ni itagbangba fun igba akọkọ. babi si ni ero pe lọ wo o. Lara awsn oṣere to wa ninu sinima yii ni Toyin Abraham, Dele Odule, Desmond Elliot, Seyilaw, Gbenga Adeyinka 1st, Woli Agba, Arole, Papi Luwe, Aisha Lawal, Rachael Okonkwo and Razak Olayiwola aka ojopagogo, and Bolanle Ninalowo.

Ifẹsẹwọnsẹ bọọlu afẹsẹgba lati sọri ọjọ ibi ọgọta ọdun, Ogogo

Ikọ agbabọọlu ogogo all stars

Oríṣun àwòrán, ogogo/Instagram

Lara awọn eekan oṣere tiata Yoruba to ti ta gbongbo kaakiri agbaye ni Alhaji Taiwo Hassan ti ọpọ eeyan mọ si Ogogo ọmọ kulodo jẹ. Nitori naa ko ya ni lẹnu nigba ti eto loniranran gbode kan fun ayẹyẹ ọjọ ibi ọgọta ọdun to ṣe. Lara awọn eto naa ni ifẹsẹwọnsẹ laarin ikọ ogogo, (Ogogo All stars) ati ikọ to jẹ ti olori ile aṣofin ipinlẹ Eko, ( Obasa All stars).

Nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa yoo fi pari ni papa iṣire agege, goolu meji lawọn ikọ Obasa All Stars fi gbẹyẹ mọ iks Ogogo lọwọ o. BBC ki Ogogo ku ayẹyẹ ọjọ ibi o. Ọdọọdun ni sapo n ruwe o, yoo maa wa bi ẹwa ni. Ojojo kii ṣ'ogun ajinde ara yoo maa jẹ fun Ebony Alhaji ni o.

Saidi Balogun sinku iya rẹ.

Saheed balogun pẹlu Iya rẹ

Oríṣun àwòrán, Saheed Balogun/Instagram

Saheed Balogun gbẹyin iya rẹ Mama Arikẹ Jọlade. Laarin ọsẹ yii naa lo ṣe eto adura fidau ọjọ kẹjọ iya rẹ.

Nibayii, Saheed gangan ti kede pe osu kẹta ọdun to n bọ, iyẹn ọdun 2020 lawọn fi oku Mama si o. Nitori naa, kẹyin ololufẹ rẹ maa mura silẹ. Gbogbo wa la o gbẹyin arugbo wa o.

Folukẹ Daramọla ko awọn agba ọjẹ ere tiata Yoruba lẹnujọ

Aworan awọn agba ọjẹ oṣere to gba amiẹyẹ

Oríṣun àwòrán, foluke daramola/instagram

Ọpọ igba ni iroyin ailera, atọpọ ipenija to n koju awọn agba oṣere tiata maa n jade sita ti o si maa n ba awọn ololufẹ wọn ninu jẹ lọpọlọpọ. Ki iru eyi ma baa ṣẹlẹ ms ni ọkan lara awọn oṣere tiata Yoruba, Folukẹ Daramọla fi dide lati gbe eto kan kalẹ eleyii ti yoo maa ri si bi alaafia ati ilera yoo ṣe maa de ba awọn oṣere nigba ti ọjọ alẹ ba de.

O pe akori eto naa ni 'Nolly veteran SOS Project 2019' lara awọn to ti n janfani eto naa bayii ni Sadiq Daba, Barbara Soki, Kareem Adepoju a.k.a Baba Wande, Kayode Odumosu a.k.a Pa Kasumu, Peter Fatomilola, Lanre Hassan (Iya Awero), Idowu Phillips (Iya Rainbow), Lere Paimo a.k.a Eda Onile Ola ati bẹẹbẹẹ lọ.

Eto idibo ẹgbẹ oṣere tiata Yoruba, TAMPAN ẹka ti ilẹ Gẹẹsi

Laarin ọsẹ yii naa ni wọn ṣe eto idibo fun igbimọ alakoso ẹgbẹ oṣere tiata TAMPAN ni ilu London.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Aarẹ Ẹgbẹ naa kaakiri agbaye, Ọgbẹni Bọlaji Amuṣan ti ọpọ mọ si Mr. Latin wa lara awọn agbaagba ẹgbẹ to lọ ṣe aayan idibo naa.