Lagos Explosion: Ìbúgbàmú ọ̀pá epo béntíróò mú ẹ̀mí lọ ni Eko

Oríṣun àwòrán, LASEMA
Laarọ oni ọjọbọ ni ọpa epo deede gba ina ni Igando ni eyi ti o kere tan awọn meji ti doloogbe.
Bayii awọn eniyan agbegbe Glory ati Diamond Estate ni ijọba ibilẹ Iṣheri ni Igando ni ipinlẹ Eko ti wa ni ipaya ki awọn ileeṣẹ ijọba to de ti wọn dide iranwọ lati pa ina naa.
Ajọ LASEMa to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Eko ṣalaye pe kete ti ọpa epo inu Diamond Estate yii bẹ ni epo bẹntiroo bẹrẹ si ni danu ni eyi to fi wa gbina ni ọna mẹrin ọtọọtọ.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Awọn ti wọn n ṣiṣẹ doola ẹmi awọn eniyan tun ti ri ọkunrion kan gbe lọ sile iwosan ijọba.
Ọkunrin yii lo ti jona kọja aala to to ida aadọrin ninu ọgọrun un.

Oríṣun àwòrán, LASEMA
Lọwọlọwọ, wọn ni wọn ti n ri ojutuu si ọrọ ina naa nitori agbara wọn ti kaa.









