LASEMA: kí àwọn ará ìlú tó ba kẹ́fin oníṣẹ́ ibi tètè máa jáde sọ̀rọ̀

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Iná sọ lẹ́yìn táwọn ajépo gbé bẹ́ àgbá epo l'Abule Egba

Ọpọlọpọ padanu mọto lataari ọpa epo rọbi to jona l'Abule Ẹgba nipinlẹ Eko loru oni.

Ajọ LASEMA ti wọn n mojuto iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Eko ni àwọn ti gbe gbogbo awọn to fi ara pa ninu iṣẹlẹ naa lọ fun itọju nile iwosan.

Ogbẹni Tiamiyu Adeṣina to jẹ ọga agba ajọ LASEMA ni awọn oniṣẹ ibi ti wọn n ji epo rọbi lati inu ọpa epo lo ṣokunfa ina to ṣẹ naa.

O ni ko sẹni kankan to sọ ẹmi rẹ nu ninu iṣẹlẹ ọhun ṣugbọn ọpọlọpọ ile lo jona ni Awori ni Abule Ẹgba ti ọpọlọpo si n ṣofọ awọn nkan ti wọn padanu.

Àkọlé fídíò, Buruji Kashamu: Èmi ṣì ni olùdíje PDP ní Ìpínlẹ̀ Ogun
Àkọlé fídíò, Republic of Benin: ìtàn tó bí abẹ́sàn án kọjá bẹ́ẹ̀!

Ọga agba LASEMA gba awọn ara ilu niyanju lati maa tete sọrọ jade ni kete ti wọn ba ti kẹfin ohunkohun ladugbo wọn.

O ni awọn ti ri oriṣii itọni ati awọn igbese to yẹ ki ajọ awọn agbofinro gbe ni eyi ti o fi ṣeeṣe lati fopin siru iṣẹlẹ yii nibi ifọrọwanilẹnuwo ti awọn ti ṣe pelu awọn ara Abule Ẹgba.

ina

Oríṣun àwòrán, @trafficbutter

Àkọlé àwòrán, ọpọlọpọ mọto, ọjà ati nkan amuludun lo jona ni Abule Egba nidaji
Àkọlé fídíò, Seun Kuti: Fela ló n pọ́n gbogbo òǹkọrin Afrobeat lagbaye