Oyo: Ṣeyi Makinde yan ọmọ Hausa gẹ́gẹ́ bíi olùrànlọ́wọ́ pàtàkì

makinde

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán, Ṣeyi Makinde yan ọmọ Hausa gẹ́gẹ́ bíi olùrànlọ́wọ́ pàtàkì

Gomina Seyi Makinde yan Dokita Olufunmilayọ Salami ati Alhaji Ahmed Murtala pẹlu awọn miran gẹgẹ bi oludamọran tuntun.

Ta ni Dokita Olufunmilayọ Salami ti Makinde yan?

Iṣẹ ikọṣe iṣegun itọju awọn ọmọde ni onimọ iṣegun Olufunmilayọ Salami kọ jade ni fasiti Benin.

O n ṣiṣẹ itọju ọmọde ni Atlanta ni Georgia ni orilẹ-ede America.

O din diẹ logun ọdun lo ti n ṣiṣẹ iṣegun to ti n tọju ọmọde.

Funmilayo ti gba ọpọlọpọ ami ẹyẹ to fihan pe o dantọ lẹnu iṣẹ to yan laayo lati maa tọju awọn ọmọde.

Àkọlé fídíò, Yoruba language: Àmì ohùn ṣe pàtàkì nínú èdè Yorùbá

Ta ni Alhaji Ahmed Murtala?

A bi Ahmed Murtala ji ijọba ibilẹ Nasarawa to wa ni ipinlẹ Kano ni ariwa Naijiria.

O lọ sile iwe St Brigid Boys ni Mokola nilu Ibadan fun ẹkọ alakọbẹrẹ ati ti Community Grammar School ni Mọkọla fun girama.

Ahmed ni Gomina Makinde ni ko maa ṣiṣẹ bii alagata laarin ijọba ipinlẹ Oyo ati awọn Hausa / Fulani ti wọn fi ipinlẹ Oyo ṣe ibujoko wọn.

Àkọlé fídíò, 'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'

Oun naa ni yoo maa ṣoju gbogbo ọmọ ilẹ Hausa to fọnka kaakiri ipinlẹ Ọyọ paapaa julọ lori ọrọ ija awọn agbẹ ati awọn darandaran.

Ṣeyi Makinde yan ọmọ Hausa gẹ́gẹ́ bíi olùrànlọ́wọ́ pàtàkì

Dokita Olufunmilayọ Salami lo fun ni olubadamọran pataki lori eto ilera nigba ti o fun Alhaji Ahmed Murtala ni olubadamoran pataki lori ọrọ awọn agbegbe ti hausa pọ si.

makinde

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán, Alhaji Murtala ọmọ ipinlẹ Kano gba ipo tuntun lọwọ Seyi Makinde ni ipinlẹ Oyo

Alhaji Ahmed yii ni o jẹ olubadamọran kinni fun gomina Seyi Makinde lori ọrọ awọn Arewa to jẹ iran Hausa ni ipinlẹ Oyo.

Bakan naa lo yan Oloye Jacob Adetoro gẹgẹ bii alaga ẹka ti yoo maa mojuto Federal Constituency Liason Officers.

Àkọlé fídíò, Kini Yoruba n pe ni "pen"?

Seyi Makinde tun darukọ awọn aṣoju mẹrinla ti yoo maa ṣoju ẹkun kọọkan ni ipinlẹ Oyo nile ijọba apapọ.

Arabinrin Olubamiwo Adeosun to jẹ akọwe agba ipinlẹ Oyo lo buwọlu lẹta awọn ti Makinde ṣẹṣẹ yan sipo naa.

Ninu atẹjade ti olubadamọran fun Seyi Makinde lori iroyin iwe iroyin, Moses Alao fi sita lo ti fidi ikede yii mulẹ.

Awọn mẹrinla to yan ni Alhaji Ajibike Osuolale Lateef (Iseyin, Itesiwaju, Kajola and Iwajowa); Alhaji Salami Lukman Adisa (Saki East, Saki West and Atisbo); Alhaji Afees Tijani (Orelope, Irepo and Olorunsogo).

Àkọlé fídíò, Yoruba language: Àmì ohùn ṣe pàtàkì nínú èdè Yorùbá

Hon. Ganiyu Laaro (Oriire, Ogbomoso North and Ogbomoso South); Mr. Sanjo Akintola (Ogo-Oluwa and Surulere); Mr. Wale Ogunmola (Afijio, Oyo West, Oyo East and Atiba); Hon. Monsuru Oduola (Ibarapa North and Ibarapa Central) naa tun wa nibẹ.

Gomina Makinde tun yam Honọrebu Femi Josiah gẹgẹ bii olubadamọran keji ti yoo maa mojuto ọrọ awọn agbegbe to ku yatọ si ti Hausa ti Alhaji Ahmed.

Saaju ni Gomina Makinde ti kọkọ ṣeleri fun awọn ọdọ ipinlẹ Niger fun un ni ami ẹyẹ gomina to dantọ julọ loṣu kẹfa to gori aleefa.

Makinde ni oun yoo yan agbenusọ kan ti yoo ma ri si ọrọ awọn iran Hausa ati fulani to fi ipinlẹ Oyo ṣe ibugbe nigba naa.

Àkọlé fídíò, UI graduation: Fasiti Ibadan ló fún mi ni ẹ̀bùn ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ tí mo fi kàwé síi- Habibat