Ilé ẹjọ́ ni Uzor Kalu lu 7.65 biliọnu naira owo ilu ni kumọkumọ pẹlu ọ̀pá jìbìtì

Ile ẹjọ giga ni ipinlẹ Eko lo ni ki gomina ipinlẹ Abia tẹle lọ fi ẹwọn ọdun mejila jura.
Ile ẹjọ lo jẹbi ẹsun mọkandinlogoji ti wọn fi kan an.
Wọn ni laarin ọdun 1999 si 2007 to fi tukọ ipinlẹ Abia bii gomina lo lo jibiti owo to din diẹ ni biliọnu mẹjọ din diẹ.
Ile ẹjọ da ẹjọ fun ile iṣẹ rẹ Slok Nigeria Limited ati oludari eto inawo fun ipinlẹ Abia nigba ti Kalu n ṣe ijọba, Ude Udeogu.
Ile ẹjọ tun ni ki Kalu to jẹ senatọ lọwọ nile igbimọ aṣofin ni Abuja fi gbogbo ohun ini rẹ to jẹ ti ileeṣẹ rẹ Slok silẹ fun ijọba.
Adajọ Mohammed Idris to da ẹjọ naa nipinlẹ Eko gẹgẹ bi ajọ EFCC to n gbogun ti iwa ṣiṣe owo ilu mọkumọku ṣe pee.
Ọkan ninu ẹjọ naa ni Kalu fi Slok Nigeria Limited to jẹ ileeṣẹ oun ati awọn mọlẹbi rẹ to ni to N7, 197, 871, 208.7 owo niara ninu.
Agbejọrọ Rotimi Jacobs to ṣoju ajọ EFCC to jẹ olupẹjọ, ni Kalu tun gba milionu ọta le ni irinwo owo naira ninu asunwọn ipinlẹ Abia laari oṣu keje si oṣu kọkanla, ọdun 2002.
O ṣalaye pe ọdun 2007 ni wọn ti bẹrẹ ẹjọ to wa so eso rere lonii yii.

Kalu atawọn to ku naa ni awọn ko jẹbi ẹsun naa ti wọn fi kan wọn.
Ẹlẹri mọkandinlogun ni awọn olupẹjọ pe ti wọn jẹri nigba ti awọn Kalu jẹri gbe ara wọn.
Kalu jẹ ọkan lara awọn seneta ẹgbẹ PDP tẹlẹ ti wọn ti ya lọ si ẹgbẹ oṣelu APC nile igbimọ aṣofin agba ni Abuja bayii.

Idajọ ati igbẹjọ to waye lawọn ile ẹjọ ni Naijiria lonii jẹ ara ọtọ.
Bi adajọ kan ṣe ran gomina nigba kan ri to tun jẹ senatọ bayii lẹwọn ọdun mejila bẹẹ naa ni omiran paṣẹ pe ajọ DSS ko le lagbara ju ile ẹjọ Naijiria lọ.
O ni ki wọn tu Soworẹ silẹ laarin wakati merinlelogun ti awọn eeyan ti n ka bayii.

DSS, ẹ gbọ́dọ̀ fi Ṣowore sílẹ̀ láàrin wákàtí mẹ́rìnlélógún- Adájọ́
Lọjọ kẹta, oṣu kẹjọ lajọ DSS mu Ṣowore, ti wọn si fẹsun onikoko meje to nii ṣe pẹlu idoju ijọba bolẹ kan an.
Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo sọ pe ile ẹjọ giga ijọba apapọ niluu Abuja ti paṣẹ pe ki ajọ DSS fi Omoyele Ṣowore silẹ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Omoyele Sowore
Adajọ paṣẹ pe ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS fi Ṣowore ati Olawale Bakare silẹ laarin wakati mẹrinlelogun.
Ẹwẹ, aibọwọ fun ofin ijọba ni Naijiria buru julọ labẹ ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari, Ọjọgbọn Wole Ṣoyinka lo sọ bẹẹ.
- Ọwọ́ tẹ àwọn pásítọ̀ oniíṣẹ́ ìyanu èké méji nílùú Eko
- Ọmọ Nàìjíríà yarí lórí àbá láti mójútó ayélujára, ilé aṣòfin láwọn ń tẹ̀síwájú lórí ẹ̀
- Àgbẹdọ̀! Má kọ̀wé fipò sílẹ̀, àwọn àgbààgbà Yorùbá sọ fún Osinbajo
- Wòólì Ajayi kú ní ìlú Àgelú, òkú rẹ pòórá, ìjọ sin pósí lásán!
- Ọwọ́ tẹ àwọn pásítọ̀ oniíṣẹ́ ìyanu èké méji nílùú Eko
Ọrọ Omoyele Ṣowore to ṣagbatẹru iwọde #RevolutionNow, ti ile ẹjọ paṣẹ idasilẹ rẹ lahamọ ajọ DSS ṣugbọn ti ajọ naa kọ lati fi silẹ lo mu Ọjọgbọn woye bẹẹ.
Ijọba Buhari lo buru julọ nipa aibọwọ fun ile ẹjọ́ pẹlu ọrọ Soworẹ- Soyinka
Lọjọ kẹta, oṣu kẹjọ lajọ DSS mu Ṣowore, ti wọn si fẹsun onikoko meje ti niiṣe pẹlu idoju ijọba bolẹ, jibiti ati sisọrọ kobakungbe si aarẹ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Omoyele Sowore
Ṣoyinka ni o dabi ẹni pe awọn ijọba ni Naijiria lati ọdun 1999 to fi di akoko yii n ṣe idije lori aibọwọ fun aṣẹ ile ẹjọ ni.
Ọjọgbọn Ṣoyinka ni iwuwasi ajọ DSS lori ọrọ Ṣowore fihan gbangba pe ijọba n lo oriṣiiriṣii lati tako ofin ile ẹjọ.
Ajafẹtọ Ṣoyinka sọ pe laisi ani-ani ẹka eto idajọ ko lẹnu rara ni ijọba Muhammadu Buhari to wa lode.
Ṣoyinka ni ti awọn ajọ eleto aabo ba le maa ju awọn ajafẹtọ si gbaga, a jẹ wi pe idaji awọn eeyan to wa ni Naijiria le wa latimọle.
O ṣalaye siwaju sii pe aibọwọ fun ile ẹjọ ati iwa jagidijagan, ọmọ iya kan naa ni wọn.














