Wòólì Alfred kú lọ́dún 1964, ó tún padà wà sí ìlú Agelu f'ọ́jọ́ mẹ́rìnlá!

Àkọlé fídíò, Wòólì Alfred kú lọ́dún 1964, ó tún padà wà sí ìlú Agelu f'ọ́jọ́ mẹ́rìnlá!

Ara mee riri lọrọ Wooli A-gbọ-ti-Jesu-ma-gbọyinbo!

Kayeefi BBC Yoruba toṣu yii gba ọna ọtọ yọ, bi àwọn kan ṣe ṣe ni pe wooli yii ku ti wọn ko ri oku rẹ sin.

Bẹẹ naa ni awọn mii ni niṣe lo poora ti wọn si tun rii.

Ohun kan ti a mọ ni pe iwadii yii da le ọrọ Wooli Saint Alfred Akintobi Ajayi to gbe iṣẹ iranṣe lọ si Agelu niwaju Isẹyin nipinlẹ Oyo ti wọn ko ri oku rẹ sin lẹyin to papoda.

Awọn bii Alagba Moses Amọo, Sunday Akintobi àti iyawo Wooli laiyọ awọn ara ilu silẹ ti BBC Yoruba ba ṣalaye kikun nipa ohun to ṣoju wọn lori iṣẹlẹ.

Bakan naa ni ọrọ kan itan ori oke kan lẹyin Odo Awaye nibi ti ẹbọra kan ti maa n lu agogo ni wakati wakati.

Wọn mẹnuba asọtẹle Wooli ṣaaju iku rẹ, bo ṣe bẹrẹ iṣẹ iranṣẹ rẹ lati ilu Eko ati awọn iṣẹlẹ kayeefi to ba irinajo Alagba naa rin.

Ojiṣẹ Ọlọrun Femi Aladelola ti ijọ World Mission for Souls International ṣalaye lori idán, agbara okunkun ati agbara Ọlọrun alaaye to fidi iru iṣẹlẹ bayii mulẹ.