T.B. Joshua: S.K. Abiara sọ̀rọ̀ nípa ìgbésí-ayé T.B. Joshua níbi ìsìn ìdúpẹ́

TB Joshua ati SK Abiara

Oríṣun àwòrán, TB Joshua Ministries

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Bi a ba ku laa dere, eniyan ko sunwọn laaye.

Isin idupẹ waye ni ijọ Synagogue Church of All Nations, SCOAN lẹyin isinku oludasilẹ ijọ naa, TB Joshua.

Lara awọn ojiṣẹ Ọlọrun jankan jankan to wa nibi isin idupẹ ọhun ni Alufa ijọ CAC, S.K. Abiara.

Alufaa Abiara sọ ọrọ idupẹ nipa igbesi aye TB Joshua to di oloogbe lẹni ọdun mejidinlọgọta.

Lopin ọsẹ to lọ ni wọn sin oku oludasilẹ ijọ Synagogue Church of All Nations, SCOAN, Wolii Temitope Balogun Joshua.

Ni nkan bi aago mẹta ọsan kọja iṣẹju diẹ ni wọn gbe ara rẹ sinu iboji.

Nibi eto isinku naa to waye ni inu ọgba ijọ rẹ to wa ni adugbo Ikotun nipinlẹ Eko lati ri gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, ati aya Ooni Ile-Ife, Olori Naomi Silekunola Ogunwusi.

Eto isin idagbere lo kọkọ waye ninu ṣọọṣi Synagogue, ko to o di pe wọn gbe oku rẹ lọ si ile ikẹhin ti wọn ṣe si abala kan ninu ṣọọṣi naa.

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

Nigba to n sọrọ nibi isin idagbere, Gomina Rotimi Akeredolu sọ fun awọn eniyan ilu Arigidi to jẹ ilu abinibi oloogbe, lati mase fi oju ọmọ ilu lasan wo o.

Bakan naa ni ojiṣẹ Ọlọrun kan to wa nibẹ, Bisọbu Steven Ogedengbe lati ipinlẹ Ondo sọ pe ko si pasitọ to ṣe iṣẹ àmì, to si tun le ẹmi eṣu jade bii TB Joshua.

Ẹgbẹ akọrin ile ijọba ipinlẹ Ondo kọ orin idaraya nibi eto isinku Wolii TB Joshua.