Noah's Ark replica: Wọ́n dá Ọkọ̀ Noah dúró sí èbúté nítorí pé kò dá pé

Wọn ti tọka si ọkọ oju omi kan to dabi ọkọ Noah, pe ko koju oṣuwọn to lati rin lori òkun.
Koda, wọn ti da a duro sibi ebute to duro si.
Ọdun 2019 ni ọkọ naa, ti wọn ti sọ di ibudo nkan iṣẹnbaye ori omi, de si Ipswich.
- ''Ìròyìn òfegè ni! Olóyè Sunday Igboho kò ṣàbẹ̀wò sí Ọba Oluwo''
- 'Nínú ìran, Olúwa sọ fún mi pé èmi ni màá tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ ìráńṣẹ́ Wòlìí TB Joshua, kàyéfì ti ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ mi báyìí'
- Buhari jọ̀ọ́ dárí jin Sunday Igboho, ohun tó ń ṣe kò ye ni - Oluwo
- Àbúrò mi TB Joshua ló ń darí gbogbo ayé wa bó tilẹ̀ jẹ́ àbúrò kẹta si mi - Àkọ́bí ìdílé TB Joshua
- Wo àwọn òjíṣẹ́ Ọlọrun jàǹkàn ní Naijiria tí kò yọjú síbi ayẹyẹ ètò ìsìnkú TB Joshua
- A ń gbóhùn àdúrà sókè ní orílẹ̀èdè 127 lágbàáyé torí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Baptist tí wọ́n jígbé ní Kaduna -Baptist Convention
- 'Ariwò tí ẹ̀ ń pa kò lè dóòlà ẹ̀mí Sunday Igboho, kò leè sá mọ́ ìjọba lọ́wọ́'
- Gbogbo ìgbèsẹ̀ tí Sunday Igboho ń gbé ni mo mọ̀ sí gẹ́gẹ́ bí Aare Ona Kakanfo - Gani Adams
Awọn alasẹ to n sa mojuto irinajo ori omi sọ pe ọkọ naa ko le kuro nibẹ nitori pe ko gbadun.
BBC ba awọn to ni ọkọ naa sọrọ.
Miliọnu mẹta Pọun ni wọn ra ọkọ oju omi naa.
Ẹni to ni, Aad Peters, to tun jẹ Olootu ere itage ati tẹlifisan ti kọkọ sọ pe oun fẹ ẹ ṣe nkan ti yoo mu ki oniruuru eniyan rí ọ̀rọ̀ sọ.

Oríṣun àwòrán, Bigship BV
Oriṣiriṣi nkan lo wa ninu 'Ọkọ Noah' ọhun.
Awọn ere onigi to n sapejuwe àwọn ìtàn inu Bibeli, to fi mọ Adamu ati Efa, Kaini ati Abeli. Koda, ti ọgbà Edeni wa nibẹ.
Agbenusọ fun ajọ to n mojuto irinajo ori omi sọ pe "o di igba ti wọn ba ṣe àtúnṣe awọn abawọn ara Ọkọ̀ Noah, ko to o le kuro nibẹ."

Oríṣun àwòrán, Bigship BV
O ni àwọn to ni i si gbọdọ ránṣẹ si awọn oṣiṣẹ ajọ naa lati ṣàyẹ̀wò rẹ pe o ti dara.
Sugbọn, ko sọ àwọn aleebu to wa lara ọkọ naa.
Ọdun 2010 ni Ọgbẹni Peters ra ọkọ naa. Oṣu marun-un si ni awọn akọṣẹmọṣẹ fi sọ ọ di ibudo nkan abalaye 'museum', ti igbagbọ wa pe o to ilaji ọkọ Noah ninu Bibeli












