Sunday Igboho: Olùrànlọ́wọ́ Sunday Igboho ní ayédèrú n'ìròyìn tó ní Igboho ṣàbẹ̀wò sí Oluwo

Oríṣun àwòrán, Facabook/Koiki Media
Yoruba bọ, wọn ni eti to ba gbọ alọ, o yẹ ko gbọ abọ.
Ọgbẹni Olayomi Koiki to jẹ oludamọran si Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ti sọ pe iroyin ofege lasan an ni iroyin kan eleyii to ṣafihan bi Igboho ṣe dọbalẹ niwaju Oluwo ti Ile Iwo, Oba AbdulRasheed Akanbi.
Koiki ṣalaye loju opo Facebook rẹ pe Igboho ko ṣe abẹwo si Oluwo gẹgẹ bi fọto to lu ori ayelujara pa ṣe ṣapejuwe.
- 'Nínú ìran, Olúwa sọ fún mi pé èmi ni màá tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ ìráńṣẹ́ Wòlìí TB Joshua, kàyéfì ti ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ mi báyìí'
- Buhari jọ̀ọ́ dárí jin Sunday Igboho, ohun tó ń ṣe kò ye ni - Oluwo
- Wo àwọn òjíṣẹ́ Ọlọrun jàǹkàn ní Naijiria tí kò yọjú síbi ayẹyẹ ètò ìsìnkú TB Joshua
- A ń gbóhùn àdúrà sókè ní orílẹ̀èdè 127 lágbàáyé torí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Baptist tí wọ́n jígbé ní Kaduna -Baptist Convention
- 'Ariwò tí ẹ̀ ń pa kò lè dóòlà ẹ̀mí Sunday Igboho, kò leè sá mọ́ ìjọba lọ́wọ́'
- Gbogbo ìgbèsẹ̀ tí Sunday Igboho ń gbé ni mo mọ̀ sí gẹ́gẹ́ bí Aare Ona Kakanfo - Gani Adams
- Bobrisky fi àwòrán tuntun léde lẹ́yìn tó parí iṣẹ́ abẹ ìdí tó ṣe
Lọjọ Abamẹta, ọjọ kẹsan an, oṣu keje ọdun 2021 yii ni Oluwo fi atẹjade kan sita ninu eyi to ti ṣalaye pe oun ti kọwe ranṣẹ si Aarẹ Muhammadu Buhari pe ko darijin Igboho ki awọn ajọ DSS le dẹyin lẹyin rẹ rẹ.
Ninu ẹda iwe naa ti Oluwo fi sọwọ si BBC Yoruba lo ti salaye pe Igboho bẹrẹ isẹ ijijagbara rẹ gẹgẹ bii olugbeja fun awọn alailagbara ni amọ ilana to n tọ ko ye oun.
Oluwo ni oun ko si lara awọn Ọba to n se atilẹyin fun ijijagbara Sunday Igboho rara bi o tilẹ jẹ pe oun maa n kilọ fun pe ko sọra se nigba ti oun ba gbọ nipa igbesẹ to ba fẹ gbe.
O ni Igboho wa si aafin oun lọdun 2018, ti oun si gba ni imọran lori oun to ba wa amọ o kuna lati mọ iyatọ laarin ijijagbara ati kikọju ija si ijọba.
"Nigba to tiẹ ya, se lo n bu gbogbo alẹnulọrọ, to si n fi oniruuru ẹsun kan wọn, emi si ni ẹni akọkọ to ni mo n kọrin fun isọkan Naijiria.
Gẹgẹ bi baba, mo dari jin, bẹẹ naa ni mo si n rọ aarẹ wa ni Naijiria lati si oju aanu wo ọmọ rẹ, Sunday Igboho."
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Oluwo ni alaimọkan ni Igboho nidi sise akoso awọn nnkan pẹlu ijọba amọ lootọ lo jẹ ẹbun nla fun ilẹ Yoruba.
Oba AbdulRasheed Akanbi ni Igboho ti jẹjẹ bayii lati maa tẹti si awọn agbaagba, ti yoo si maa sọrase lori awọn igbesẹ to ba n gbe lati akoko yii lọ.
Amọ, oludamọran Igboho ti sọ pe ko si otitọ kankan ninu iroyin naa.















