Prophet TB Joshua: 'Nínú ìran, Olúwa sọ fún mi pé èmi ni màá tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ ìráńṣẹ́ Wòlìí TB Joshua - Moses Awe

Àkọlé fídíò, 'Nínú ìran, Olúwa sọ fún mi pé èmi ni màá tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ ìráńṣẹ́ Wòlìí TB Joshua, kàyéfì ti ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ mi báyìí'

"Mo tẹ́nu mọ́ ọ nígbà tí Oluwa fihan mi pé oloogbe TB Joshua yoo dagbere faye laipẹ".

Wolii Moses Awe o kan sọ ọrọ to sọ yii o lai ṣe pe o mọ Oloogbe Wolii TB Joshua ri, o ni oun ti ba TB Jsohua pade nipa ti ara loju koroju.

Moses Awe sọ fun BBC Yoruba pe lọdun 2013 loun atawọn eeyan Wolii TB Joshua foju kan ara wọn lẹyin ti Oluwa ti ba oun sọrọ tan.

"Lọjọ naa, oloogbe fun mi ni ẹgbẹrun mẹsan naira ninu apo iwe funfun, mo si sọ pe Wolii ko ki n fun awọn eeyan ni owo ni iru ọna yii, mo wa sọọ ninu ẹmi pe o n sọ fun mi pe lẹyin ọdun mẹsan ni iṣẹ iranṣẹ mii yoo gbera".

Moses Awe ni oun tun ti pade Wolii TB Joshua ni ijọ rẹ to wa ni ilu Eko nibi to ti fẹ ṣe isin kan pẹlu awọn ọmọlẹyin rẹ ti ko si lee sọrọ si ẹrọ gbohungbohun mọ koda isin naa o ṣeeṣe mọ nigba to foju gaani oun to si wa duro ti oun fun iṣẹju marun.

Wolii yii ni Oluwa sọ fun oun ni ọdun mẹsan sẹyin ọhun pe Wolii TB Joshua yoo jade laye.

Nigba ti ọdun yii bẹrẹ o ni oun sọ fun awọn eeyan oun pe lọdun yii ni nkan nla maa ṣẹlẹ ti ami rẹ si bẹrẹ si ni han.

"Dajudaju Oluwa lo mu Wolii nni lọ gẹgẹ bi o ṣe sọ fun wa ni ọdun mẹsan sẹyin".