Yomi Fabiyi Oko Iyabo: Ẹgbẹ́ TAMPAN ti dá Yomi Fabiyi dúró lẹ́yìn tó gbé fíímù Oko Iyabo jáde

Oríṣun àwòrán, yomi fabiyi
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe apapọ ẹgbẹ awọn oṣere tiata ni Naijiria, TAMPAN ti fofin de Yomi Fabiyi pe ko lọ rọọkun nile na.
Ninu atẹjade ti ẹgbẹ naa fi sita lọjọ Ẹti lo ti kede pe igbesẹ naa waye nitori iwa abuku ati eyi ti ko ba oju mu gẹgẹ bi oṣere ti Fabiyi hu nipa fiimu Ọkọ Iyabọ to gbe jade laipẹ yii.
Fiimu naa to gbe jade ni ọjọ Aiku to kọja da lori ọrọ ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan osẹre miran, Baba Ijesha.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo àwọn òjíṣẹ́ Ọlọrun jàǹkàn ní Naijiria tí kò yọjú síbi ayẹyẹ ètò ìsìnkú TB Joshua
- A ń gbóhùn àdúrà sókè ní orílẹ̀èdè 127 lágbàáyé torí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Baptist tí wọ́n jígbé ní Kaduna -Baptist Convention
- Buhari jọ̀ọ́ dárí jin Sunday Igboho, ohun tó ń ṣe kò ye ni - Oluwo
- Buhari bínú tán, àwọn tó ń yọ Nàíjíríà lẹ́nu wọ wàhálà - Femi Adesina
- "Kò sí Pásítọ̀ tó ṣiṣẹ́ ìyanu, tó lé ẹ̀mí èṣù jáde bíi TB Joshua"
- 'Ariwò tí ẹ̀ ń pa kò lè dóòlà ẹ̀mí Sunday Igboho, kò leè sá mọ́ ìjọba lọ́wọ́'
- Ó tó gẹ́, Sunday Igboho fẹ́ gbé ìjọba lọ ilé ẹjọ́ bí wọn kò bá tú àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀
- Gbogbo ìgbèsẹ̀ tí Sunday Igboho ń gbé ni mo mọ̀ sí gẹ́gẹ́ bí Aare Ona Kakanfo - Gani Adams
- CAN faraya lórí ikọlù agbofinro sàwọn ajàfẹ́tọ̀ bí Sunday Igboho
TAMPAN sọ pe igbesẹ naa waye lẹyin ti oun gbọ awijare Yomi Fabiyi to jẹ olukọtan, olootu ati oludari fiimu naa, ati oludari keji, Ọgbẹni Dele Matti.
"A ri pe wọn jẹbi hihu iwa ti ko bojumu fun akọṣẹmọṣẹ oni tiata.
Awọn alaṣẹ TAMPAN sọ pe botilẹ jẹ pe Ọgbẹni Fabiyi taku pe ẹtọ oun gẹgẹ bi eniyan, ni lati gbe fiimu jade, eyi ti yoo sọ bi nakn ṣe ri gan-an lori iṣẹlẹ ọrọ Baba Ijesha, wọn ni alajọṣiṣẹpọ rẹ gba pe oun jẹbi, to si kabamọ ipa to ko ninu ṣiṣe fiimu naa.
Ninu atẹjade ti ẹgbẹ naa fi si ori Instagram rẹ ni ikede naa ti jade.
Awọn abajade iwadii ati idajọ ẹgbẹ TAMPAN nipa Yomi Fabiyi:
Ọgbẹni Yomi Fabiyi mọọmọ ṣe fiimu naa lai bọwọ fun ilana to de fiimu ṣiṣe, eyi to tumọ si pe o sẹ isẹ naa pẹlu erongba lati da wahala silẹ laarin ilu.
Ti iṣẹ naa (fiimu) kii ba ti i ṣe ti ile Sinima, ẹnikẹni ko ni ẹtọ lati lo orukọ eeyan ti iṣẹlẹ ṣẹlẹ si ninu fiimu. "Nitori naa, iwa aibikita ni bi Fabiyi ṣe lo orukọ, ati awọn iṣẹlẹ to waye loju aye, lai gba aṣẹ lọwọ awọn ti ọrọ kan.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Ìtàn, agbekalẹ itan, ohùn, ọrọ, akori, orukọ, ati gbogbo nkan to nii sẹ pẹlu fiimu "Ọkọ Iyabọ" jẹ awsn nkan to ṣẹlẹ, eleyi to le mu ki ojuṣaaju waye lori ẹjọ naa to ti wa ni ile ẹjọ.
Iwa aibikiti to hu ti tabuku si orukọ ẹgbẹ wa.
Ẹni ti wọn jọ dari ere naa, Ọgbẹni Dele Matti, ti fihan pe oun jẹbi, o ti ronu piwada, a si daa duro fun oṣu mẹta pere.
A paṣẹ ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ wa to kopa ninu fiimu naa yọju siwaju igbimọ to wa fun yiyanju aawọ ati ilana isẹ wa, ni ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keje, ọdun2021.
- "Odeeshi"! Baba Ijesha, Yomi Fabiyi àti gbogbo àwọn tó fẹ́ pa mi, èèyàn lásán niyín o - Iyabo Ojo
- Olórí Eléégún, Ìmáàmù àti èèyàn márùn-ún míì dèrò àtìmọ́lé l‘Osogbo
- Iléeṣẹ́ DSTV àti GO TV rugi òyin lọ́dọ̀ ìjọba àpapọ̀
- Hàà! Yomi wàá ṣẹ̀wọ̀n o! Oò ṣe bí ọlọ́pọlọ rárá, ò kàn ń fi àṣírí Baba Ijesha àti Iyabo Ojo gòkè ni - Femi Branch
Lakotan, ẹgbẹ TAMPAN sọ pe ẹgbẹ awọn eeyan to jẹ ọmọluabi ni oun, ti ko si ni ṣe atilẹyin fun ohunkohun to ba le da wahala silẹ ni awujọ.


















