Femi Adesina: Kìí ṣe àwọn ọ̀daràn nìkan ló ń gbọ́ èdè Buhari, ẹgbẹ́ alátakò PDP gan ti di akúrẹtẹ̀

Oríṣun àwòrán, Femi Adesina/Facebook
Oludamọran fun aarẹ Muhammadu Buhari lori eto iroyin, Femi Adesina ti kede pe aarẹ ti binu tan si awọn eeyan to n da wahala silẹ lorilẹede yii.
O ni awọn agbebọn, ikọ mujẹmujẹ, ọdaran, ajinigbe atawọn to n pe fun iyapa Naijiria lo ti n kan ni ẹṣẹ, ti gbogbo wọn si ti n gbe imu ẹlẹjẹ kiri bayii.
Femi Adesina woye ọrọ yii ninu ọrọ apilẹkọ rẹ to kọ nipa ipo ti Naijiria wa, eyi to gbe si oju opo Facebook rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Buhari jọ̀ọ́ dárí jin Sunday Igboho, ohun tó ń ṣe kò ye ni - Oluwo
- Ẹgbẹ́ TAMPAN ti dájọ́ fún Yomi Fabiyi àti igbákejì rẹ̀ lórí fíìmù Oko Iyabo
- "Kò sí Pásítọ̀ tó ṣiṣẹ́ ìyanu, tó lé ẹ̀mí èṣù jáde bíi TB Joshua"
- 'Ariwò tí ẹ̀ ń pa kò lè dóòlà ẹ̀mí Sunday Igboho, kò leè sá mọ́ ìjọba lọ́wọ́'
- Ó tó gẹ́, Sunday Igboho fẹ́ gbé ìjọba lọ ilé ẹjọ́ bí wọn kò bá tú àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀
- Gbogbo ìgbèsẹ̀ tí Sunday Igboho ń gbé ni mo mọ̀ sí gẹ́gẹ́ bí Aare Ona Kakanfo - Gani Adams
- "Gbàjarè! Àwọn èèyàn tí DSS kó nílé Sunday Igboho nílò ìtọ́jú kíámọ́sá"
- "Odeeshi"! Baba Ijesha, Yomi Fabiyi àti gbogbo àwọn tó fẹ́ pa mi, èèyàn lásán niyín o - Iyabo Ojo
O ni ni kete ti wọn fi okun oye ologun tuntun wọ olori ikọ ọmọ ogun ni Naijiria, Farouk Yahaya, lo ti kede pe gbogbo awọn adarugudu silẹ ni Naijiria ni wn n ran lọ sọdọ Ọlọrun lati lọ dahun awọn iwa ọdaran ti wọn hu.

Oríṣun àwòrán, Femi Adesina/Facebook
Adesina ni ọjọ idajọ yii yoo maa tẹsiwaju titi ti orilẹede Naijira yoo fi di afọmọ lọwọ awọn iwa aidaa gbogbo, eyi to tumọ si ede tuntun ti Buhari n fọ jade.
O salaye pe Buhari tẹti bẹlẹjẹ lati gbọ ẹdun ọkan alaga ajọ eleto idibo nilẹ yii, Ọjọgbọn Mahmoud Yakubu, to n gbarata pe bi wọn ba tẹsiwaju lati maa ba awọn ohun eelo idibo jẹ, yoo lewu fun eto idibo lọjọ iwaju.
"Gẹgẹ bii baba ti idunkooko wa fun ile rẹ yoo ti se, o kaanu awọn to n ba nnkan jẹ lorilẹede yii, to si ni awọn ti awọn jagun abẹle fun ọgbọn osu ko ni maa wo wọn niran, ki wn ba orilẹede yii .
Idi ree to fi ni "laipẹ laijinna a ba wọn sọrọ ni ede ti yoo ye wọn."
Ede ti Buhari fi n ba awọn abayejẹ yii sọrọ ti wa di gbas-gbos, ti wọn si n pe aarẹ ni Olori ẹka ẹkọ nipa ede ni fasiti."
Bakan naa ni Femi Adesina ni igun kọọkan ni orilẹede yii lo ti wa n gbọ ede Buhari yekeyeke bayii, o ni kii se awọn ọdaran nikan amọ ẹgbẹ oselu alatako PDP pẹlu, ti n gbọ ede aarẹ yekeyeke.
"Ni ẹka oselu, ẹgbẹ PDP ti n di ahoro, ti ko ba si sọra, ẹgbẹ naa yoo di korofo ko to di ọdun 2023, koroba wọn ti n jo, to si n gba omi gidigidi.
Ni osu diẹ si asiko yii, ẹgbẹ oselu kan yoo maa lagbara siwaju ati siwaju, ti omiran yoo si maa di akurẹtẹ ni ojoojumọ, bi ẹgbẹ oselu kẹta ba tiẹ wa, ko le tii ni ipa kankan."


















