Security state of Nation: Ọ̀rọ̀ ààbò kìí se èyí tí a lé fí gbèdéké sí- Femi Adesina

Security state of Nation: Ọ̀rọ̀ ààbò kìí se èyí tí a lé fí gbèdéké sí- Femi Adesina

Oríṣun àwòrán, Channels

Olùbádámọ́ràn pàtàkì fún ààrẹ Muhammadu Buhari, lórí ọ̀rọ̀ tó n lo àti ìpolongo, Femi Adesina tí rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti tẹ́síwájú nínú sùúrù tí wọ́n ni pẹ̀lú ààrẹ Muhammadu Buhari, pàápaá jùlọ lórí ọ̀rọ̀ àbò tó mẹ́hẹ

Adesina sọ ọ̀rọ̀ yìí lásìkò eto kan lórí móhùnmáwòràn Channels lọjọ́ Àìkú. Atọ́kùn ètò bi i pé, ìgbàwo ni kí àwọn penpiypan ni sùúrù dà lórí ọ̀rọ̀ ètò ààbò tó mẹ́hẹ ni Nàìjíríà.

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ ọ̀rọ̀ ètò ààbò kìí ṣe èyí tí à ń fi àsìkò lé lórí, àsìkò tó bá tó ni ìyanjú ni, pẹ̀lú ìgbyànjú gbogbo ìgbà.

"Sùúrù tí kò lópin ló ṣe pàtàkì, kìí ṣe pé ènìyàn yóò de ipò kan yóò sọ pé sùúrù ti pin."

"Ó tẹ̀síwájú pé, àwọn ǹkan wà ti ènìyà kò ni agbára lórí wọ́n, tí ènìyàn kò bá sì yí rí ojútùú ó tímọ̀ sí pé kò sí gbèdéke.

Ààré Muhammadu Buhari gbé ìlérí rẹ̀ le ǹkan mẹ́ta lásìkò ìdìbò 2015, pé kíkojú ètò ààbò, ìwà àjẹbánu àti mímú ìdàgbàsókè bá ètò ọrọ̀ ajẹ́ ló jẹ òun lógún.

Bákan náà ló tún ìlérí náà ṣe lọ́dún 2019, sùgbọ́n lẹ́yìn gbogbo èyí, ètò ààbò kò níyanjú, pàápàá jùlọ ní aríwá orílẹ̀-èdè yìí.

Adesina ni sps ìgbà ni Nàìjíríà tí sùgban sùgbọ́n tó tún dìde, nítori náà ó ṣe pàtàkì láti máá wá ìwájú fún ọ̀nà àbáyọ.

" Bí ìjọ́bá bá subú, ó ṣe pàtàkì gbà pé òun súbu kí í tọrọ afórijì kí ó sì kọ́ ẹ̀kọ́ nínú àṣìṣe wọ́n.

Àkọlé fídíò, 'Pásítọ̀ ló sọ fún mi pé Ọlọ́run pè mí láti di Olokun tó ń bọ omi'