Katsina: Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún ṣalaye ohun ti oju rẹ ri lọwọ awọn ajinigbe

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọkan lara awọn ọmọdebinrin ti awọn agbebọn ji gbe nile keu kan nipinlẹ Katsina ti ṣalaye ohun toju rẹ ri ki wọn to doola wọn.
Ọmọ ọdun mẹrindinlogun naa ti a fi orukọ bo laṣiri ṣalaye pe nigba ti wọn ji wọn gbe tan ni awọn ajinigbe naa gbe wọn lọ si agbegbe kan ti wọn ko mọ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ fun BBC, o ni "wọn ni ki n bọ Hijab mi ṣugbọn mo kọ, lẹyin naa ni wọn lu mi ni ilu bara ti wọn si pe ẹnikan pe ko bọ Hijab mi ṣugbọn mo kọ jalẹ."
"Wọn ti wa sinu koto kan, wọn si halẹ mọ wa pe awọn yoo yinbọn pa ẹnikẹni to ba pariwo."
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Katsina, ASP Isah sọ fun akọroyin BBC pe awọn ajinigbe naa kọkọ ji awọn obinrin mẹrin kan gbe ki wọn to ṣalabapade awọn ọmọ ile keu naa to jẹ ọgọrin.
- Kóníléógbélé ọlọ́sẹ̀ márùn ún gbáko ni ìjọba Nàíjíríà gbé kalẹ̀ fàwọn oṣìṣẹ́ lábẹ́ ìlànà Covid-19 tuntun
- Ìwádìí tú àṣírí Dókítà tó pa ìyàwó rẹ̀, ó fẹ́ pa ọmọ wọn méjì, òun fúnrarẹ̀ tún pokùnso
- Ìjọba àpapọ̀ ti kéde ìsúnsíwájú ọjọ́ ìforúkọsílẹ̀ nọ́mbà NIN
- Kí ló tún ṣe Òṣèré fíìmù Yorùbá míì tó ń gba ẹ̀jẹ̀ àtomi níléèwòsàn?
Isah sọ pe awọn ọmọ naa n bọ lati ibi ti wọn ti lọ ṣe ajọdun kan ni wọn ti ṣagbako awọn ajinigbe ọhun.
O ni kete ti awọn eeyan kan fi iṣẹlẹ naa to ileeṣẹ ọlọpaa leti, ni awọn bẹrẹ iṣẹ pẹlu ajọṣepọ awọn ọmọ ologun, ti wọn si bori awọn janduku ọhun.
Iṣẹlẹ naa lo waye lẹyin ọjọ meji pere ti awọn akẹkọ ọkunrin 344 nile iwe GSS ni Kankara gba itusilẹ lọwọ awọn to ji wọn gbe ni ipinlẹ Katsina yii kan naa.
Àkàrà tú sépo fún àwọn agbébọn tó jí akẹ́kọ̀ọ́ ilé Keu 80 ní Katsina

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Katsina, ti doola akẹkọọ ọgọrin, to jẹ ti ile Keu Hizburrahim Islamiyya nipinlẹ Katsina.
Iroyin sọ pe lasiko ti awọn ọmọ ile Keu naa n pada si abule Mahuta, lẹyin ti wọn kopa nibi ayẹyẹ Maulud kan ni abule Unguwan Alkasim, ni wọn ji wọn gbe ni ọjọ Satide.
Awọn agbebọn naa ti kọkọ gbe obinrin mẹrin ni abule Dan Baure, ki wọn to gbe awọn akẹkọọ naa.
Eyi to mu ki apapọ awọn ti wọn ji gbe jẹ mẹrinlelọgọrin.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Katsina, ASP Gambo Isa sọ fun BBC pe ijọba ibilẹ Funtua ni iṣẹlẹ naa ti waye.
- 'Ìdí tí a ò fi pa àwọn ajínigbé tó gbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Kankara nìyìí'
- Mo gbóríyìn fún Buhari bó ṣe dóòlà ẹ̀mí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jí gbé ní Kankara
- Iléeṣẹ́ ológun ti yabo ibùdó àwọn jàndùkú tó jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbé níléèwé katsina- Garba Shehu
- Òṣèré tíátà Yorùbá yìí la orí mọ́lẹ̀ nígbà tó ń ṣe sinimá lọ́wọ́
- Wo ìdí tí ọmọ ọdún mẹ́wàá ṣe ti àbúrò rẹ̀ ọmọ ọdun kan àbọ̀ sínú kàǹga
ASP Isa sọ pe ni kete ti awọn eeyan kan fi iṣẹlẹ naa to ileeṣẹ ọlọpaa leti, ni awọn bẹrẹ iṣẹ pẹlu ajọṣepọ awọn ọmọ ologun, ti wọn si bori awọn janduku ọhun.
O ni "awọn kan farapa lara awọn agbebọn naa, ti awọn mii si ku, bo tilẹ jẹ pe ao ti i le sọ iye wọn bayii".
"Ẹnikẹni ko kú ni ọdọ wa."
"Ṣugbọn kọmisanna ọlọpaa ti ran awọn ọlọpaa lọ laarọ yii lati mọ iye wọn."
Iṣẹlẹ yii waye lẹyin ọjọ meji ti awọn akẹkọ ọkunrin 344 nile ẹkọ bọdin ni Kankara, gba itusil ẹ lọwọ awọn to ji wọn gbe ni Katsina l'ọsẹ to kọja.















