Amotekun news: Báwo lọ̀rọ̀ ṣe jẹ́ tí wọ́n fi ní ikọ̀ tó ń dáàbò bo ìlú yìnbọn pa èèyàn méjì n'Ibadan?

Aworan awon asofin Oyo

Adari ikọ Amotekun ni ẹkún Guusu-Iwọ Oorun ilu Ibadan sọ fun BBC Yoruba pe ohun tawọn n lọ mọ awọn lẹsẹ ko ri bẹẹ bi ko ṣe pe wọn kan fẹ ba wọn lorukọ jẹ.

Adari ikọ Amotekun ipinlẹ Oyo, Olayinka Olayanju sọ pe lootọ ni awọn oṣiṣẹ Amotekun gbọ pe rogbodiyan kan bẹ silẹ lagbegbe Born Photo si Isale Osi, ti awọn ọmọ ẹgbẹ OPC n gbiyanju lati pari.

Àwọn eeyan kan lo fẹsun kan ikọ Amotekun ni ipinlẹ Oyo pe awọn oṣiṣẹ wọn yinbọn pa eeyan meji lagbegbe Asaka, ni ilu Ibadan.

Àkọlé fídíò, 'Mo kàn máa ń lọ́ ayẹyẹ kiri torí ijó láì ṣe pé wọ́n pe mí ló sọ mí di DJ olórin Fuji nìkan'
Àkọlé fídíò, 'Ọ̀lọ́pàá shátà mi láti Mowe dé Magboro dé Shagamu, wọ́n ní ṣé mi ò mọ̀ pé ìjọ́ba ni mo ṣiṣẹ́ fún'

Gẹgẹ bi ohun ti a gbọ, wọn ni iṣẹlẹ naa waye ni orita Ike-Olu l'Ọjọbọ to kọja, lẹyin ti ọgbẹni kan to jẹ ọmọ ẹgbẹ Oodua Progressive Congress, OPC to tun ṣẹṣẹ darapọ mọ ikọ Amotekun yinbọn lu eeyan meji nitori aawọ kan to waye laarin wọn.

Ṣugbọn atẹjade kan lati ọdọ Amotekun ti sọ pe oṣiṣẹ awọn kọ lo yin ibọn ọhun.

Àkọlé fídíò, 'Pásítọ̀ ló sọ fún mi pé Ọlọ́run pè mí láti di Olokun tó ń bọ omi'
Amotekun

Oríṣun àwòrán, @Slaypappii

O ni asiko ti wọn de ibẹ ni wọn ṣakiyesi pe awọn janduku kan atawọn ọmọ OPC naa ti n kọlu ara wọn, ti wọn si yinbọn lemọlemọ, ṣugbọn o ni Amotekun lo pana aawọn ọhun, ti wọn si fi ṣikun ofin mu awọn afurasi kan ti wọn fa le awọn agbofinro Operation Burst lọwọ.

Àkọlé fídíò, 'Pásítọ̀ ló sọ fún mi pé Ọlọ́run pè mí láti di Olokun tó ń bọ omi'

Adari Amotekun naa sọ siwaju si pe lẹyin ti awọn pana rogbodiyan naa tan ni awọn janduku ọhun lọ kọlu ọmọ ẹgbẹ OPC kan to tun jẹ oṣiṣẹ ikọ Amotekun.

Olayanju sọ pe o ṣeni laanu pe awọn ileeṣẹ iroyin kan ti gbe iroyin jade lara oṣiṣẹ ikọ Amotekun yinbọ pa awọn eeyan kan, ṣugbọn iwadii ti bẹrẹ lati yanju ọrọ naa.

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti sọ pe ikọ Amoteku ko lọwọ ninu iku ẹnikẹni lagbegba ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Oyo, Olugbenga Fadeyi ni wọn fi iṣẹlẹ naa to agọ wọn to wa ni Mapo leti.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni awọn meji ti wọn padanu ẹmi wọn ni Asaka ku lẹyin ti awọn kọlọrọsi kan ṣakọlu si wọn nitori wọn kọ lati darapọ mọ ẹgbẹ OPC.

Lẹyin naa lo ni iku wọn ko ni nnkankan ṣe pẹlu ikọ Ametekun.

Àkọlé fídíò, Kí lo tíì rí nípa Amotekun? Ẹ sùnmọ́bí, ẹ wo gbankọgbì!