ASUU Strike Nigeria: ASUU ti fòpin si ìyàsẹ́lódì olósù mẹ́sàn-an tí wọ́n gùnlé

Oríṣun àwòrán, Nigeria FEDERAL MINISTRY OF LABOUR
Minisita oṣiṣẹ ati igbanisiṣẹ ni Naijiria, Chris Ngige ti ni oun yoo ṣe ohun gbogbo lati ri i daju pe ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ fasiti Naijiria, ASUU ko tun bẹrẹ iyanṣẹlodi mii.
Lẹyin oloṣu mẹsan gbako ti wọn gunle lati ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹta si ọjọ kẹtalelogun oṣu kejila ọdun 2020.
O ṣalaye pe ọmọ bibi inu oun mẹta tanyanyan lo wa lara awọn akẹkọọ to faragba lara gbogbo nkan ti iyanṣẹlodi ASUU yii fa torinaa oun ni ifarajin funra oun lati yanju ọrọ naa.
"Mi o ni fun ASUU ni anfani lati pada sori iyanṣẹlodi. Toripe mo ni ọmọ mẹta to jiyaa gbogbo ohun taa ba ara wa ninu rẹ yii. Koda nkan bii eeyan mẹẹdogun lo wa lorii eto ẹkọ ọfẹ latọwọ mi ni awn fasiti Naijiria".
O ni awọn ọmọ oun ti di ọmọ Amẹrika labẹ ofin toun si ni ẹtọ lati fi wọn silẹ lati kawe nibẹ ṣugbọn oun ni ki wn wa ka a nile.
Minisita n sọ lẹyin wakati diẹ ti awọn ẹgbẹ ASUU kede siso iyanṣẹlodi naa rọ amọ lorii awọn nkan ti wọn n beere fun lọwọ ijọba.
Kí ló kù lẹ́yìn tí ASUU àti ìjọba fòpin sí ìyan'sẹ́lódì olóṣù mẹ́sàn án?
Ààrẹ ẹgbẹ́ ASUU ní Nàìjíríà Biodun Ogunyemi ti kéde lọ́jọ́ru pé, àwọn ti fòpin sí ìyánṣẹ́lódì tí àwọn ti gùnlé láti inú oṣù kẹ̀ta ọdún yìí.
Ìkéde yìí wáyé lẹ́yìn ìpáde pẹ̀lú àwọn oníròyìn nílùú Abuja, ẹ́yì ti àwọn olóyé ẹgbẹ́ sọ pé ìfẹ̀nukò lẹ́yìn ìpàdé pọ̀ pẹ̀lú ìjọba àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tó kù
ASUU tó jẹ́ ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ní Fásitì Nàìjíríà àti ìjọba Nàìjíríà ti padà gbóra wọn yé lórí àwọn kókó ọ̀rọ̀ tí yóò fòin sí ìyanṣẹ́lódi olósù mẹ́wàá tí wọ́n gùnlé láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdú yìí
Ìdájí ọjọ́rú ni wọ́n pohunpọ̀ lẹ́yìn wákàtí mẹ́jọ tí wọ́n lò nínú ìpàdé ìdákọ́nkọ́, èyí wáyé lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù tí wọ́n ti n ṣe ìpàdé tí ọ̀pọ̀ rẹ̀ sì n forí sánpọ́n
Chirs Ngige tó jẹ́ mínísítà fún ọ̀rọ̀ iṣẹ́, ló sójú ìjọba àpapọ̀ nínú ìpàdé náà tó wáye ni Abuja.
ASUU sàlàyé fún BBC pé, inú àwọn dùn bí ìjọba ṣe mú ọ̀rọ̀ náà àti pé ìjọba tún ṣe ìlérí tuntun, nítori náà ìpàdé yóò wáyé láàrín àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ASUU tí àwọn yóò si jábọ̀ fún ìjọba àpapọ̀ láàrín wákàtì mẹ́rìnlélógún lórí ǹkan ti àwọn bá fẹnukò sí.
Láti ìnú oṣù kẹta ọdún 2020 ni ASUU ti bẹ̀rl ìyanṣẹ́lódí láti mú kí ìjọba ṣe ǹkan ti wọ́n ń fẹ́ nípa àdéhùn wọ́n lọ́dún 2009.
Ǹkan tó ṣe pàtàkì jùlọ nínú atótónu wọ́n ni pé kí ìjọba àpapọ̀ san owó tí wọ́n fi ń sàkòso ètò ẹ̀kọ́ ni fásitì, kí wọ́n sán àwọn àjẹmọnú kí wọ́n yọ wọ́n kúrò nínú ètò sísan owó oṣù IPPIS, kí wan sì àwọn owó oṣù tí wọ́n jẹ wọ́n.
Ìjóba gba pé òun yoo san ogójì bílíọ̀nù owó àjẹmọ́nu, àti ọgbọ̀n bílíọ̀nù owó ìsàkóso .
Bákan náà ni ìjọba gbà láti ṣe agbéyẹ̀wò ìlànà tí wọ́n gbékalẹ̀ láti fi máa san owó oṣù wan yàtọ̀ sí IPPIS ti wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ni UTAS

Oríṣun àwòrán, FESTUS KEYAMO/TWITTER
Títí dí ọjọkejìlélógún inú oṣù kejìlá, ìjọba ti san owó oṣù méjì lára owó tí wan jẹ wọ́n, àti ogójì bílíọ̀nù owó àjẹmónú wọ́n
Owó ìsàkoso ètò ilé ìwé nìkàn lókùn ti wọ́n kò ti san.
Kíni àdéhùn tuntun ti wọn ṣe?
Lẹ́yìn ìpàdé bònkẹ́lẹ́ tó fẹ́ wọ wákàtì mẹ́jọ tí wọ́n ṣe, àti mínísítà ọ̀rọ̀ iṣẹ́, Chris Ngige sàlàye pé ìpàdé náà so èso rere, àti pé òun ni ìgbàgbọ́ pé, lẹ́yìn ti wọ́n bá ti ṣe ìpàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọ́n, wọ́n yóò fòpin si ìyanṣẹ́ lódì wọ́n.
Ààrẹ ẹgbẹ́ ASUU Biodun Ogunyemi ni lóòtọ́ ni àwọn rí ìmọ́lẹ̀ tuntun nínú ìpàdé tí àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀ bá ìjọba ṣe, sùgban àwọn yóò lọ ṣe ìpàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tó kù láàrin ọjọ́ kan lórí ìpinu wọn làti fòpin si ìyanṣẹ́lódí
Ìròyìn tuntun lórí àsìkò ìwọ́lé ASUU ni Nigeria
Ààgo mẹ́jọ àbọ owúrọ̀ òní ọjọ́rú ni wọ́n ni àwọn yóò fẹnukò láti fòpin sí ìyánṣẹ́lódì náà
Báwò ni ìyànṣklódì ASUU ṣe bẹ̀rẹ̀?
Ní ọja kẹsàn oṣù kẹta ọdún 2020, ní ẹgbẹ́ ASUU gpunlẹ́ ìyásẹlódì láti kìlọ fún ìjọba láti fẹ̀hónú han fún owó osù tí wọ́n kọ̀ láti san nítorí wọ́n kọ̀ láti darapọ̀ mọ́ ètò ìsànwó oṣù IPPIS.
Wọ́n ni IPPIS kò lé ṣiṣẹ́ dáada fún àwọn olùkọ́ Fásìtì, nítori wan kọ̀ láti rí àrà ọ̀tọ̀ tí Fásitì ń gbà ṣiṣẹ́.
Ìjọ́ba tí gbé ìlànà IPPIS kalẹ̀ láti tanmalẹ̀ sí snà ti àwọn ilé ẹ̀kọ́ fásitì ń gbà náwó tí ń wọlọ́ sí ọ̀dọ̀ wọ́n
Àwọn Kọ̀ndísọ̀n ti ASUU yóò fi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́
Bí ASUU àti ìjọba ṣe tí dúró sí apá ibikan báyìí, ǹkan kan tó le dá ìwọlé dúró ni ọ̀rọ̀ Covid-19 pàápàá jùlọ tí ọwọ́jà ààrùn Covid-19 ṣe tún padà dé báyìí.
Gbogbo àwọn aláṣẹ ilé ìwé gbọdọ ṣètò láti rí dájú pé, wọ́n gbé àwọn ìlànà tí ààrùn Covid-19 kò fi ni tànkálẹ̀ sílẹ̀, èyí ni láti rí dájú pé, àtí àwọn olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ wà lábẹ́ ààbò tó péye.
Bí ọdún ṣe ń lọ sọpin báyìí, kò ti dájú bọóyá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yóò le padà sí ilé ìwé tàbí ó di ọún tó n bọ̀.




















