2nd wave of Covid-19: Sanwo-Olu késí àwọn adarí ẹ̀sìn láti wọ́gilé ìsìn àṣálẹ́ àìsùn ọdún àti ìṣọ́ òòru

Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, @followlasg

Ijọba ipinlẹ Eko ti ke si awọn ṣọọṣi ati Mọṣalaṣi lati wọgile gbogbo iṣọ oru ati isin aṣalẹ ọdun tuntun.

Ikede yii lo n wa nitori isin ọlọdọdun to maa n waye lawọn ile ijọsin ṣaaju ọjọ kinni ọdun tuntun.

Gomina ipinlẹ naa, Babajide Sanwo-Olu lo fi ikede naa sita lẹyin to jajabọ lọwọ arun Coronavirus nile ijọba to wa ni Marina, ni ilu Eko.

O ni awọn yoo kan igbele ti ijọba apapọ gbe kalẹ lati aago mejila oru si aago mẹrin idaji nipa fun awọn eeyan.

Sanwo- Olu ṣalaye pe igbesẹ ati kawọ ipadabọ Covid-19 ko ni faye gba awọn ipade ọlọpọ ero, paapaa lasiko pọpọṣinṣin ọdun.

Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, @followlasg

O ni "kaakiri agbaye ni asiko ọdun Keresimesi jẹ asiko ti ọpọ ero maa n korajọ, ti awọn miran si maa n rinrinajo, eyii to le ran Coronavirus lọwọ lati ran ọpọ eeyan."

"A ni lati din awọn nnkan bayii ku, ẹ jẹ ka lo asiko Keresimesi ọdun yii lati gbadura s'Ọlọrun."

Àkọlé fídíò, 'Mo kàn máa ń lọ́ ayẹyẹ kiri torí ijó láì ṣe pé wọ́n pe mí ló sọ mí di DJ olórin Fuji nìkan'

Sanwo-Olu ni ti awọn eeyan ba le pawọpọ pẹlu ijọba lati kapa Covid-19 lasiko ọdun Keresimesi, nnkan ko ni nira lọdun 2021 bo ṣe ri lọdun 2020.

Yatọ si itakete siraẹni, Sanwo-Olu tun gba awọn eeyan nimọran lati má rinrinajo ti ko ṣe koko lasiko yii.

Lẹyin naa lo paṣẹ fun gbogbo ileeṣẹ lati gbe ofin kalẹ pe ẹnikẹni ti ko lo ibomu ko gbọdọ wọle sinu ileeṣẹ wọn.

Ẹnikẹ́ni tó bá ṣe "Carnival" lòdì sí òfin Covid-19 tuntun yóò fi ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà jura - Ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun

Dapo Abiodun

Oríṣun àwòrán, Prince Dr. Dapo Abiodun - MFR

Ijọba ipinlẹ Ogun ti sọ pe ẹnikẹni to ba tapa si ilana tuntun ti awọn gbe kalẹ lati dena ipadabọ arun Covid-19 yoo fi ẹwọn oṣu mẹfa jura.

Bakan naa lo tun sọ pe irufẹ ẹni bẹẹ le san owo itanra ti ko din ni ẹgbẹrun lọna ogun naira dipo ko lọ si ọgba ẹwọn.

Kọmiṣọna fun eto ilera ipinlẹ naa, Dokita Tomi Coker lo fi ọrọ naa lede ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba.

Àkọlé fídíò, 'Mo kàn máa ń lọ́ ayẹyẹ kiri torí ijó láì ṣe pé wọ́n pe mí ló sọ mí di DJ olórin Fuji nìkan'

Ṣaaju ni gomina ipinlẹ ọhun, ọmọ Ọba Dapo Abidun ti kọkọ fofin de gbogbo ohun to jọ mọ ipade ita gbangba, kanifa aarin oju popo ati ode faaji ọlọpọ ero nipinlẹ naa.

Abiodun fi kun un pe ero ti yoo wa nile ijọsin loju kan naa ko gbọdọ ju ida aadọta iye ero to yẹ ko wa nibe lọ.

Dapo Abiodun

Oríṣun àwòrán, @fact_print

Nigba to n kin ọrọ gomina ọhun lẹyin, Coker sọ pe "ida aadọta eeyan ni yoo wa ninu ṣoọṣi ti awọn to ku yoo si wa ni ita."

Kọmiṣona naa fi kun pe awọn igbimọ amuṣẹwa yoo wa ni igboro lati kan nipa fun awọn ara ilu lati tẹlẹ ilana tuntu naa.

Àkọlé fídíò, 'Ọ̀lọ́pàá shátà mi láti Mowe dé Magboro dé Shagamu, wọ́n ní ṣé mi ò mọ̀ pé ìjọ́ba ni mo ṣiṣẹ́ fún'

Coker fi kun un pe ile ẹjọ alagbeka yoo wa ni ikalẹ lati gbọ ẹjọ ati lati ṣe idajọ ẹnikẹni ti aje ọrọ naa ba ṣi mọ lori.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, "ijọba ko sọ pe ki awọn eeyan ma ṣe isin, ṣugbọn ohun ti ijọba sọ ni pe ki wọn ma jẹ ki iye ero ti yoo wa ninu ile ijọsin wọn ma ju ida aadọta lọ."

Coker pari ọọ rẹ pe awọn ti ba awọn adari ẹsin ṣe ipade losi bi eto isin yoo ṣe maa waye, nitori naa awọn olori ẹlẹsin naa mọ gbogbo awọn nnkan to yẹ ki wọn ṣe.

Nítorí COVID-19, Akeredolu, Oyetola, Abiodun, Fayemi wọ́gilé ayẹyẹ ọdún ní ìpínlẹ̀ Ondo, Osun, Ogun

Aworan Gomina Oyetola

Oríṣun àwòrán, OsunCPS/photos

Gẹgẹ bi ara ọna lati dẹkun arankalẹ ọwọ keji ajakalẹ arun COVID-19, awọn gomina ipinlẹ Ogun, Ondo ati Ọṣun ti fagile gbogbo ipejọpọ to lee fẹ waye lasiko pọpọṣinṣin ọdun yii.

Ni tirẹ, Gomina Rotimi Akeredolu ti ipinlẹ Ondo fagile gbogbo ipejọpọ wẹjẹwẹmu ọlọdọọdun eyi ti gomina Akeredolu funrarẹ maa n ṣe agbatẹru rẹ ni ọjọọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kejila.

Amugbalẹgbẹ Gomina Akeredolu, Tosin Ogunbọdede salaye ninu atẹjade kan pe igbesẹ naa waye lati fi seranti awọn eekan ọmọ ipinlẹ naa to jade laye laipẹ yii ati lati tẹle awọn ilana igbogun ti aarun COVID-19 ti o tun burẹkẹ si lagbaye bayii.

Gomina Akeredolu ko ṣai rọ awọn eeyan ipinlẹ naa lati yọ ayọ ọdun ni iwọntunwọnsi.

Bakan naa gomina Gboyega Oyetọla ni ipinlẹ Ọṣun ti wọgilẹ gbogbo ayẹyẹ ọdọ ladugbo si adugbo ti a mọ si Youth Carnival kaakiri ipinlẹ naa.

Ẹwẹ, o ni ayẹyẹ kiki wakati wọnu ọdun tuntun ti a mọ si New year countdown ti ijọba ipinlẹ naa maa n ṣe ni aṣalẹ aisun ọdun wọnu ọdun tuntun atawọn ipejọpọ nlanla ko ni lee waye.

Akọwe ijọba ipinlẹ Ọṣun, Wọle Oyebamiji ṣalaye pe ilana tuntun ti wa nikalẹ bayi fun awọn egbejẹgbe ati araalu lati tẹle lọna ati dẹkun itankalẹ ajakalẹ aarun naa.

Aworan Gomina Akeredolu

Oríṣun àwòrán, rotimiaketi

Lara awọn ilana tuntun naa ni pe iwọnba eeyan perete ni o gbọdọ maa wa ni gbogbo awọn ile ijo, ile itura awọn ile igbafẹ ati ile itaja nlanla ni ipinlẹ naa.

Gomina Oyetọla wa rọ awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun lati din pọpọsinsin ayẹyẹ, ikomọ, isinku atawọn ayẹyẹ miran ku ki wọn maa baa lugbadi akoran aarun naa.

Bakan naa lo ni awọn ileejọsin gbọdọ pada sori ilana ipejọpọ to wa nilẹ tẹlẹlori didena ajakalẹ aarun COVID-19.

Igbesẹ yii n waye lẹyin ti ibudo iwadii aarun ACEGID ni fasiti Redeemers RUN to wa nilu Ede ti firoyin sita laipẹ yii pe afaimọ ki ẹya tuntun kokoro aarun COVID-19 to n ṣọṣẹ lawọn orilẹede kan lagbaye o maa ti wọ ipinlẹ Ọsun.