New Variant: Kí ni ìbẹ̀rù tó gbọkàn àwọn èèyàn lágbàáyé nítorí ẹ̀yà ààrùn Covid-19 tuntun?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Kóo tó gbàlejò láti UK, South Africa, wo àwọn kọ̀ndísọ̀n tí ikọ̀ PTF fi lélẹ̀
Ajọ to n ri si igbogun ti aisan lorilẹede Naijiria, NCDC ni irufẹ arun Covid-19 ti wọn ṣẹṣẹ ri lorilẹede Naijiria ko fara jọ awọn eyi to ṣí wọ orilẹede UK ati South Africa.
Torinaa, nibi ipade ikọ amuṣẹya aarẹ lorii Covid-19, PTF, oludari ikọ naa, Sani Aliyu fi alakalẹ ati ilana aatẹle sita fun awọn arinrinajo to ba n bọ lati orilẹede South Africa ati United Kingdom tori awọn ti n ni iriri "new variant" loju paali.
Ofin tuntun fun awọn arinrinajo lati South Africa, UK
1. O ni lati agogo kan oru lọjọ kejidinlọgbọn oṣu kejila, gbogbo arinrinajo to ba n bọ lati orilede mejeeji gbud ṣafihan iwe aṣẹ irina meji ati esi ayẹwo ilera pe wọn ko tii lugbadi arun naa.
2. Wọn gbudọ ri i daju pe wọn forukọ silẹ loju opo ijọba ki wọn si ṣe ayẹwo ẹlẹẹkeji nigba ti wọn ba wọ orilẹede Naijiria.
3. O ni ijọba ti pa aṣẹ fun gbogbo awọn ileeṣẹ ọ̀kọ̀ ofurufu ki wọn ma jẹ ki ẹnikẹni ti ko ba ni awọn iwe yii rinrinajo pẹlu wọn.
- 'Mo máa tó dìde lórí àìsàn', Muyiwa Ademola sọ̀rọ̀ látorí àkéte àìsàn rẹ̀
- Ẹ̀yin ṣọ́ọ̀ṣì àti Mọ́ṣáláṣí, mo wọ́gilé ìsìn àṣálẹ́ àìsùn ọdún àti ìṣọ́ òòru - Sanwo-Olu
- Ohun márùn ún tóo gbudọ̀ mọ̀ nípa ìtàn àti ayẹyẹ ọdún Kérésì
- Àwọn Tíṣà Oyo kó owó tó wà fún àkóso iléèwé jẹ, ni wọ́n fi ń fọwọ́ kọ ìdánwò pẹ̀lú ṣọ́ọ̀kì - Seyi Makinde
4. Ati pe wọn yoo ṣi iwe ọtọ silẹ fun wọn ni papakọ ofurufu ki awọn arinrinajo lati orilẹede mejeeji fi orukọ wọn silẹ ti wọ́n ba ṣe n de ki wọn lee maa foju to wọn lẹyin ayẹwo ẹlẹẹkeji.
5. Ẹnikẹni to ba kọ lati tun ayẹwo ṣe yoo fi ẹwọn oṣu mẹfa jura ijọba yoo si gba iwe irina wọn kalẹ.
O wa fa gbogbo awọn to ba n ṣe ayederu iwe esi ayẹwo Covid-19 pe bi wọn ba gba wọn mu, wọn yoo gba gbogbo iwe irina wọn silẹ.
Oludari patapata ajọ naa, Chigwe Ihekweazu fi ọrọ naa lede pe wọn ri tuntun yii lasiko ti awọn onimọ iwadi ijinlẹ nibudo iwadi ijinlẹ nipa awọn ajakalẹ arun nilẹ Afrika (African Center of Excellence for Genomics of Infectious Diseases, ACEGID) ni fasiti Redemmers University, Ede n ṣe iwadi ijinlẹ kan.
Ṣaaju awọn onimọ yii ti kọkọ sọ ọ ti wọn si fi atẹjade sita ninu oṣu kẹjọ ọdun nigba ti wọn kọkọ ri i ṣugbọn awn eeyan ko fibẹẹ gbagbọ.
Nibayii, Ikekweazu fi aridaju rẹ han ni ọjọ Iṣẹgun nibi ipade ikọ amuṣẹya aarẹ nipa Covid-19, PTF.

Oríṣun àwòrán, PA Media
Ẹ o ranti wipe aarun tuntun yii ti gbilẹ ni orilẹede South Africa to si ti wọ United Kingdom pẹlu.
Ihekweazu ni awọn yoo ṣe iṣẹ pupọ lati wadii sampu tuntun ti wọn gba lati mọ boya eleyii lee fa aranka kiakia lorilẹede Naijiria.
Ni South Africa, wọn ṣi n ṣe ayẹwo boya ọwọ tuntun ti Covid-19 yii n gbilẹ pẹlu arankan amọ wọn ṣaa mọ pe awọn eeyan ti ko dagba lo n ran ju.
Nibi ipade itagbangba ikọ PTF, oludari wọn, Sani Aliyu sọ alakalẹ tuntun fun awn arinrinajo to n bọ lati UK ati South Africa wa si Naijiria.
Ṣé lóòtọ́ ni ẹ̀yà kòkòrò àrùn COVID-19 ti wọ ìpínlẹ̀ Osun?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni bayii ti gbogbo agbaye n pariwo lori ọwọ keji ajakalẹ arun COVID-19 to n gbalẹ kan bayii kaakiri gbogbo agbaye, ibẹru bojo lori bi agbara kokoro arun naa tun ṣe n gbilẹ sii ko yee ọpọ paapaa julọ awọn alakoso eto ilera lagbaye, ti wọn si n woye ọna abayọ.
Ohun kan ti ọpọ awọn onimọ n sọ bayii ni pe ẹya kokoro arun COVID-19 to tun gbaye kan bayii gẹgẹ bi a ti ṣe rii ni awọn ilu agbaye bii ilẹ Gẹẹsi fẹ tun yatọ si eyi to gbilẹ tẹlẹ ni ibẹrẹ ọdun 2020.
- Àìsàn Muyiwa kò lè la ẹ̀mí lọ - Agbẹnusọ Òṣèré, Muyiwa Ademola
- Joe Biden náà ti gba abẹ́rẹ́ àjẹsara Covid-19
- Kóníléógbélé ọlọ́sẹ̀ márùn ún gbáko ni ìjọba Nàíjíríà gbé kalẹ̀ fàwọn oṣìṣẹ́ lábẹ́ ìlànà Covid-19 tuntun
- Àwọn tó jí wa gbé fi tìpá-tìkúùkù bọ́ Hijab mi, wọ́n lù mí ní ìlù bàrà - ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún
Amọṣa, awọn onimọ iwadi ijinlẹ nibudo iwadi ijinlẹ nipa awọn ajakalẹ arun nilẹ Afrika, African Center of Excellence for Genomics of Infectious Diseases, ACEGID ni fasiti Redemmers University to wa nilu Ẹdẹ ṣalaye pe ninu iwadi wọn, o fihan pe ṣaaju akoko yii ni ẹya kokoro arun COVID-19 to wa ni orilẹede Naijiria ti yatọ si COVID-19 to wa nilẹ tẹlẹ.
Nigba to ba BBC News Yoruba sọrọ lori atẹjade kan ti wọn fi sita ninu eyi ti wọn ti yannana rẹ pe ẹya arun COVID-19 kan wa to ti n ja ranyinranyin nilẹ lorilẹede Naijiria fun oṣu diẹ sẹyin bayii eleyii to yatọ si akanṣe kokoro arun naa to kọkọ gbilẹ.
Gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe sọ, lootọ o le ni ẹgbẹrun kan ẹya kokoro arun naa to wa lode, ṣugbọn eyi to wa ni Naijiria, paapaa julọ ipinlẹ Ọṣun nitosi ibi ti ibudo iwadi naa kalẹ si yatọ si eyi.
Ọmọwe Johnson Okolie, alakoso iṣẹ gbogbo ni ibudo iwadi ijinlẹ nipa awọn ajakalẹ arun nilẹ Afrika, African Center of Excellence for Genomics of Infectious Diseases, ACEGID ni fasiti Redemmers University, RUN ṣalaye fun BBC News pe ọpọlọpọ awọn ayẹwo kokoro arun naa ti wọn ṣe lagbegbe ipinlẹ Ọṣun lo fihan pe ẹya kokoro arun COVID-19 to n farahan julọ nibẹ atawọn agbegbe miran lorilẹede Naijiria fihan pe eyi to yatọ gedegbe si ẹya kokoro arun naa to gbilẹ kariaye ni.
Ọmọwe Okorie wa fi kun un pe awọn ṣi n ṣe iwadii lati mọ boya ẹya kokoro arun naa dọgba pẹlu ẹya tuntun ti wọn pe o n ṣe ọṣẹ lorilẹede Gẹẹsi atawọn orilẹede miran bayii.

Oríṣun àwòrán, EPA
Ibẹrubojo ni ọpọ orile-ede lagbaye nitori ẹya aarun Coronavirus tuntun to tun bẹ silẹ ni Ilẹ Gẹẹsi ti ọpọ orileede si ti n fi ofin de irinajo lati ilẹ okere .
O le ni orile-ede ogoji to ti fofinde awọn olugbe UK, bi awon EU se n pinu lati se agbekale ilana kan lasiko yii.
Sweden ti fofin de awon arinrinajo lati ilẹ okere lẹyin to ri ẹya Covid-19 tuntun nibẹ
Ẹya tuntun tun yara tan ka laarin awọn eniyan ju ti akọkọ lọ ṣugbọn ko si aridaju pe o yara paniyan ju ti akọkọ lọ.
Bi awọn orileede to n fofin de UK lati ma rinrin ajo wa ilu wọn se n peleke sii ajọ isọkan agbaye (WHO) n gbiyan lati se afiwe iru ewu to wa nibẹ.
- Joe Biden náà ti gba abẹ́rẹ́ àjẹsara Covid-19
- Àwọn tó jí wa gbé fi tìpá-tìkúùkù bọ́ Hijab mi, wọ́n lù mí ní ìlù bàrà - ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún
- Kóníléógbélé ọlọ́sẹ̀ márùn ún gbáko ni ìjọba Nàíjíríà gbé kalẹ̀ fàwọn oṣìṣẹ́ lábẹ́ ìlànà Covid-19 tuntun
- Ìwádìí tú àṣírí Dókítà tó pa ìyàwó rẹ̀, ó fẹ́ pa ọmọ wọn méjì, òun fúnrarẹ̀ tún pokùnso
- Ṣé lóòtọ́ ni Bimpe Oyebade lóyún fún Lateef Oladimeji?
Asoju WHO fun iṣẹlẹ pajawiri Mike Ryan salaye pe iha tuntun ti aarun Coronavirus gbe jade kii se nkan ajoji si ajakalẹ aarun, a ti pe kii se nkan ti oju o riri ki si se pe 'apa o ka' eyi tako ọrọ minisita eto ilera UK Matt Hancock to so pe ọrọ ẹya Coronavirus tun yii ri kọja agbara lọjọ Aiku.
Ni iha keji ẹwẹ, awọn arinrinajo lati South Africa naa nkoju iru kan naa lẹyin ti eya Covid-19 yii jẹyọ nibẹ pẹlu eyi si yatọ si iru eyi ti wọn ri ni UK.
Kilo n ṣẹlẹ ni Europe?
Ọpọ orileede agbaye lo tin fi ofin de awọn arinrin ajo lati UK lojuna ati fopin si ẹya tuntun ti Coronavirus gbeyọ
Orile-ede France fofin de awọn ero ati eru oju omi lati to n bọ lati UK, eyi si ti fa rukerudo ni awon enu ibode ori omi ni iha Guusu ile Geesi ti won pe ni 'British port of Dover'.
Asoju ijọba ilẹ Gẹẹsi Boris Johnson ṣalaye pe oun ati aarẹ France Emmanuel Macron n siṣẹ pọ lati bẹrẹ owo pada, ati pe igbagbọ wa pe ọrọ naa yoo yanju laipẹ yii.
Minisita eto irina Clément Beaune sọ pe oni ni oun yoo sọ igbesẹ ti orile-ede oun yoo gbe nipa nkan ti wọn yoo ṣe lori fifofinde igbokegbodo ero ati awọn ọkọ nla to n kẹru.
Ni Brussels awọn igbimọ ijọba ti n fikulukun lojuna ati gbọ esi ti yoo ṣe anfani fun awọn ọmọ ẹgbẹ EU metadinlọgbọn to ku.
O ni ni igbimọ yoo sọ ipinu wọn, ṣugbọn nkan eyọkan to daku ju ni pe, ọmọ ilẹ Gẹẹsi kọọkan gbọdọ se ayẹwo ki o si ma ni aarun. Coronavirus ki o to kuro lorileede rẹ.
Ati ni gbogbo agbaye?
Ọpọ awọn orileede to ku, lati India si Iran lọ si Canada lo ti fofinde awọn ara UK lati ma wa si ilu wọn.
Botilẹ jẹ pe orile-ede Amerika ko ti tọ ilana yii, sibẹ ọkọ ofuru British Airways ati Delta yoo maa di aaye gba awọn ti ayẹwo fi han pe ko ni aarun Covid-19 nikan ki wọn to le fo lọ si papakọ ofurufu John Kenedy ni New York.
Saudi Arabia, Kuwait ati Oman naa ti ti ẹnu Ibode wọn nitori ki awọn ara ita ma baa wọ ilu.
Ẹya Covid-19 tuntun ti jẹyọ ni Demark bakan naa ni wọn ri ni Australia, Italy ati Netherlands.
Iwọnba eyi ti wọn ri ni Demark yii lo mu ki Sweden naa tilẹkun ibode rẹ mọ wọn, eyi ni igba akọkọ ti Sweden yoko tilẹkun mọ aladugbo rẹ.
"Gbogbo ọna lo n tọka si pe awọn ara Demark yoo kọja si Sweden lati lọ ra awọn nkan keresimesi, minisita to n ri si ọrọ idile Mikael Damberg lo sọ be gẹgẹ bi iroyin AFP.
Awọn onimọ gbagbọ pe ẹya Coronavirus tuntun yii ti tan ka kọja awọn ibi ti wọn ti kede pe o de, won gboriyin fun ilẹ gẹẹsi to kọkọ mọ.
"Mo nigbagbọ pe laipẹ yii o ri pe ọpọ awọn orileede miran ti ni ẹya Covid-19 tuntun yii," Marc Van Ranst to jẹ onimọ nipa itankalẹ aarun lati ile iwe Raga Institute for Medical Research ni Belgium lo sọ bẹ fun oniroyin.




















