Muyiwa Ademola: A ó jọ rọ́ọ̀kì ọdún 2021 papọ̀ ni lágbára Ọlọ́run

Muyiwa Ademola

Oríṣun àwòrán, authenticmuy

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ilumọka oṣere fiimu Yoruba, Muyiwa Ademola ti fi ọrọ ranṣẹ si àwọn ololufẹ rẹ ati awọn akẹgbẹ rẹ bo tilẹ jẹ pe o ṣi wa nile iwosan.

O fi akoko ikini rẹ́ ki awọn ololufẹ rẹ kuu ọdun Keresimesi o si ni ki wọn ma binu si oun pe kii ṣe ẹbi oun lati ma jade sọrọ si wọn latọjọ yii ṣugbọn ara n fẹ isinmi.

Muyiwa ni "ẹ ṣeun fun gbogbo ifẹ ti ẹ fi han si mi, ẹ ṣeun fun adura yin ati ọrọ ikini, mo dupẹ gidi gan".

Àkọlé fídíò, 'Mo kàn máa ń lọ́ ayẹyẹ kiri torí ijó láì ṣe pé wọ́n pe mí ló sọ mí di DJ olórin Fuji nìkan'

Muyiwa ni oun ṣeleri pe oun yoo to gbera kuro lori akete aisan ti awọn yoo si jọ ṣe igbadun ọdun 2021 papọ.

To fi mọ awọn mọlẹbi rẹ, ọrẹ ati awọn akẹgbẹ rẹ ninu fiimu Yoruba lo ni wọn ṣeun fun gbobo ẹbun, owo, ọrọ ti wọ́n fi ranṣẹ si oun ni ipo ti o wa.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 1

Laipẹ niroyin gbode kan pe Muyiwa Ademola wa lori akete aisan ti agbẹnusọ rẹ si pada jade wa sọ oju abẹ niko gan lori ohun to ṣẹlẹ.

Awọn ololufẹ rẹ atawọn akẹgbẹ rẹ ti n woye wipe ki lo ṣẹlẹ gangan toripe ọwọ ti wọn n fa diriipu si nile iwosan ni wọn ri wọn ko ri oju rẹ.

Muyiwa Ademola

Oríṣun àwòrán, authenticmuy

Agbẹnusọ rẹ, Wuraola sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pe lootọ ni Muyiwa wa ni ile iwosan to si jẹ wipe wahala iṣẹ ti wọ ọ lara ni.

O ni "o kan rẹ ẹ diẹ ni, kii ṣe aarẹ to buru. O kan ti rẹ ara ni. Gbogbo igba lo maa n ṣiṣẹ bii jaki lo ṣe mu ki aarẹ yẹn sinmi si i lara. Torinaa o nilo isinmi ni".

Àkọlé fídíò, 'Ọ̀lọ́pàá shátà mi láti Mowe dé Magboro dé Shagamu, wọ́n ní ṣé mi ò mọ̀ pé ìjọ́ba ni mo ṣiṣẹ́ fún'

O ni beeyan ba n ṣiṣẹ bii ago ti ko sinmi, yoo pada dẹnukọlẹ ni. Iyẹn lo mu ki Muyiwa Ademola ṣi wa nile iwosan.

"A o tii mọ igba ti wọn yoo ni ko maa lọ ile ṣugbọn a o fẹ ko wa nibẹ fun igba diẹ".

Wuraola ni kii ṣe aisan kan to le koko ṣugbọn awọn mọ pe ko ni sinmi to ba de ile tori gbogbo igba lo maa n wa lorii foonu rẹ to n ṣiṣẹ.

"Aisan yii kii ṣe eyi to lee la ẹmi lọ, o kan jẹ eyi to maan da eeyan lagara ni. Kii ṣabaa rẹ Muyiwa tori aṣiṣẹ-bi-ago ni". Wuraola lo sọ bẹẹ.

Àkọlé fídíò, 'Pásítọ̀ ló sọ fún mi pé Ọlọ́run pè mí láti di Olokun tó ń bọ omi'

Láàrin ọ̀sẹ̀ kan ṣóṣó Òṣèré fíìmù Yorùbá méjì gorí akéte àìsàn

Loju opo Instagram rẹ, ko fi oju ara rẹ han ṣugbn Muyiwa Ademola fi aworan sita to wa lori ibusun ile iwosan ti wọn si n fa diriipu si i lọwọ.

Ẹ o ba tilẹ ro wipe ori itage ni ṣugbọn pẹlu akọle to kọ sita, ko si ani ani pe o wa lori akete aisan.

Ọrọ ikini si Muyiwa Ademola

Oríṣun àwòrán, authenticmuy

Àkọlé fídíò, 'Pásítọ̀ ló sọ fún mi pé Ọlọ́run pè mí láti di Olokun tó ń bọ omi'

"Mi o tii fi iru atẹjade bayii sita ri ṣugbọn nitori ọpọlọpọ iṣẹ nla ati ifarajin to wa niwaju mi pọ".

Dajudaju awọn akẹgbẹ rẹ ninu ere Yoruba ti kan si i tori ọpọlọpọ wọn lo tu sori ayelujara ti wọn n ki i, ti wọn n rọ ọ ko ṣara giri.

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 2

"Aisan ko ni jẹ ipin rẹ lailai. Piri lologo n ji, a kii bokurun eye lori ite. Ni agbara Ọlọrun, oo ni faisan logba". Eyi ni agba adura ti akẹgbẹ rẹ, Rasaq Olasunkanmi Olayiwola ti ẹ mọ si Ojopagogo ṣe fun un.

Ọrọ ikini si Muyiwa Ademola

Oríṣun àwòrán, authenticmuy

Awọn mii to tun fọrọ ati adura ranṣẹ si Muyiwa ni Aisha Lawal, Kiitan Bukola, Bisola Badmus, Funsho Adeolu, Temitope Solaja ati awọn mii.

Ọrọ ikini si Muyiwa Ademola

Oríṣun àwòrán, authenticmuy

Òṣèré Tíátà Yorùbá yìí la orí mọ́lẹ̀ nígbà tó ń ya sinimimá lọ́wọ́

Aworan Mide Martins

Oríṣun àwòrán, mydemartins

Gbajugbaja osere tiata Yoruba Mide Martins ti n ke irora bo ti ṣe fori janlẹ lasiko to n ṣe ere sinima kan lọwọ.

Ikede yi to fi soju opo rẹ ni Instagram lo sọ pe ara oun ko ti ya daada nitori bi oun ti ṣe fori gbalẹ.

Ninu ọrọ to fi tẹle fnran fidio ati aworan boti ṣe farapa yi han, Mide sọ pe ''Igbesi aye awa oṣere tiata ko dẹrun!''

Àkọlé fídíò, 'Pásítọ̀ ló sọ fún mi pé Ọlọ́run pè mí láti di Olokun tó ń bọ omi'

O ni ''Ara mi ko ti bọ sipo latari bi mo ṣe forigbalẹ. Ki eledua fi oore si igbiyanju gbogbo ni to n wa atijẹ ati mu ''

Lara awọn aworan to fi safihan ipalara yi lo wa ni isalẹ yi:

Aworan Mide Martins

Oríṣun àwòrán, mydemartins

Aworan Mide Martins

Oríṣun àwòrán, mydemartins

Okiki Bakare@kikibakare ti wọn jijọ n ṣe ere naa ti ko ti jade kan sara si Mide Martins bi o ti ṣe fi inira ori to la mọlẹ mọra .

O ni eyi ṣafihan pe ojulowo osere tiata ni Mide n ṣe ti o si ni ki eledua tete mu lara da.

Aworan Mide Martins

Oríṣun àwòrán, mydemartins