Fibroid: Ǹjẹ́ o mọ pé o le ní oyún ìju tí o kò bá tètè bímọ?

Aworan oyun iju

Oríṣun àwòrán, Bsip

Àkọlé àwòrán, Aworan oyun iju
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Iwadii imọ ijinlẹ kan ti fi han pe obinrin mẹta ninu mẹwaa, ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mẹẹdọgbọn si ọgbọn ọdun, lo ma n ni oyun iju ni Naijiria.

Awọn ile iwosan ikọṣẹ iṣegun oyinbo to wa ni ilu Calabar, Port Harcourt ati Enugu, ni wọn ṣe iwadii naa.

Dokita agba ni ẹka ti wọn ti n mojuto awọn ẹya ara ti obinrin fi n bimọ, Obstetrics and Gynaecology, ni Ile iwosan ẹkọṣẹ iṣegun Fasiti Calabar, Ugwu Brown, sọ fun BBC pe, ìju lo wọpọ ju ninu awọn nnkan to ma n wu ninu ikun obinrin, ni Naijiria.

Awọn nnkan to le fa oyun ìju ninu ikun obinrin:

  • Ko si ẹni to mọ nkan to n fa a ni pato, ṣugbọn awọn onimọ sọ pe awọn nkankan wa to le fi obinrin sinu ewu rẹ
  • Ẹya: Awọn obinrin to jẹ alawọ dudu lo wa ninu ewu ju lati ni oyun iju, ju awọn obinrin to jẹ alawọ mii
  • Ajogunba: Obinrin ti iya tabi ẹgbọn tabi aburo rẹ obinrin ba ni oyun iju, wa ninu ewu lati ni i
  • Awọn ọmọbinrin to tete bẹrẹ nkan oṣu: Awọn obinrin to ba bẹrẹ nkan oṣu ki wọn o to o pe ọmọ ọdun mọkanla, lo ṣe e ṣe ko ni oyun iju, ju awọn akẹẹgbẹ wọn to bẹrẹ nkan oṣu lẹyin ti wọn pe ọmọ ọdun mẹtala
Dokita n lo ẹrọ Ultrasound lati mọ boya obinrin ni oyun iju

Oríṣun àwòrán, other

Àkọlé àwòrán, Dokita n lo ẹrọ Ultrasound lati mọ boya obinrin ni oyun iju
  • Sisanra ju boṣeyẹ lọ: Oyun iju ma n mu ki eroja ara 'estrogen' pọ si ninu ara, to si ma n mu ki ọra pọsi ninu ikun
  • Obinrin ti ko loyun ri: Obinrin ti ko ba tete bimọ wa ninu ewu lati ni oyun iju
  • Itọ ṣuga: Obinrin to ba ni aisan itọ ṣuga wa ninu ewu nla, lati ni oyun iju
Dokita Brown sọ pe adinku le ba bi awọn obinrin ṣe n ni oyun iju, ti wọn ba le mojuto ilera wọn, nipa mimu adinku ba bi wọn ṣe n jẹ awọn ounjẹ to ni caffeine; tabi dena itọ ṣuga ati ẹjẹ riru, to fi mọ sisanra ju . O si tun ni ki obinrin tete bimọ le ran lọwọ.
Àkọlé àwòrán, Dokita Brown sọ pe adinku le ba bi awọn obinrin ṣe n ni oyun iju, ti wọn ba le mojuto ilera wọn, nipa mimu adinku ba bi wọn ṣe n jẹ awọn ounjẹ to ni caffeine; tabi dena itọ ṣuga ati ẹjẹ riru, to fi mọ sisanra ju . O si tun ni ki obinrin tete bimọ le ran lọwọ.
  • Ẹjẹ riru: Obinrin to ba ni aisan ẹjẹ riru naa le ni oyun iju
  • Awọn obinrin to ba ni aisan PCOS: Aisan to l'agbara ni PolyCystic Ovarian Syndrome (PCOS) fun awọn obinrin kan

Awọn ami oyun iju:

Bi oyun iju naa ba ṣe tobi to, iye to jẹ, ati ibi to wa ninu ile ọmọ, ni yoo sọ ami ti obinrin yoo ri.

Ṣugbọn Dokita Brown sọ pe ọpọlọpọ obinrin to ni oyun iju kii ri ami kankan.

Awọn ami to wọpọ ni:

  • Ẹjẹ to ba n jade lasiko nkan oṣu yoo pọ ju bo ṣe yẹ. Ọjọ ti obinrin naa fi n ṣe nkan oṣu yoo pọ, yoo si maa ni irora inu rirun lasiko nkan oṣu
  • O ma n buru debi pe obinrin naa yoo nilo ki wọn fa ẹjẹ si lara
  • Oyun yoo ma a bajẹ mọ obinrin naa lara.
  • Inu rirun ati inira ni isalẹ ikun
Aworan oyun iju

Oríṣun àwòrán, other

Àkọlé àwòrán, Aworan oyun iju
  • Kindinrin obinrin naa yoo wu, tabi ki inu rẹ kún
  • Inira lasiko ti obinrin ba ṣẹṣẹ loyun
  • Obinrin naa yoo ma a tọ loorekoore, inira lasiko to ba n tọ tabi ṣe igbọnsẹ.

Bi o sẹ le tọju oyun iju:

Awọn to n ṣe iṣẹ abẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Itọju ti wọn yoo fun obinrin to ba ni oyun iju nii ṣe pẹlu ọjọ ori, to ba ṣi fẹ ẹ bimọ, bi iju naa ṣe tobi si, ati ibi to wa ninu ile ọmọ.

Itọju gboogi to wa fun ni 'hysterectomy'; eyi ni ilana ti wọn n gba lati yọ ile ọmọ obinrin kuro ninu ara.

Ṣugbọn, itọju naa yoo jẹ nipa oogun lilo tabi iṣẹ abẹ.