Christmas: Ohun márùn ún tó yẹ kóo mọ̀ nípa ìtàn Kérésì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ayẹyẹ dun Keresi jẹ asiko ti wọn n ṣe ajọyọ ibi Jesu Kristi gẹgẹ bo ṣe jẹ iṣe gbogbo ẹlẹsin Kristẹni.
Bo tilẹ jẹ pe itakurọsọ wa lori boya ọjọ kẹẹdọ̀gbọn oṣu kejila gangan ni ọjọ ti wọn bi i ṣugbọn ọpọlọpọ gbagbọ pe lọjọ yii gan ni wọn bi Jesu pẹlu bi wọn ṣe maa n yọ.
Ọjọ taa bi Jesu
Awọn to gbagbọ pe ọjọ yii ni wọn bi Jesu fi ẹsẹ Bibeli gbe e lẹsẹ.
Iwe Mattheu 2:11 ati Luuku 2:8-18 sọrọ lẹkunrẹrẹ nipa itan ibi Jesu.
Ẹwẹ, ṣiṣe ajọyọ ọdun keresi bẹrẹ lati ọdọ awọn Angẹli pẹlu iroyin ayọ ibi Jesu ninu iwe Luuku ori keji.
"8: Àwọn olùṣọ́-àgùntàn ń bẹ tí wọ́n ń gbé ní ìlú náà,
wọ́n ń ṣọ́ agbo àgùntàn wọn ní òru ní pápá tí wọ́n ń gbé.
9: Angẹli Olúwa sì yọ sí wọn, ògo Olúwa sì ràn yí wọn ká".
- Ẹ̀yin ṣọ́ọ̀ṣì àti Mọ́ṣáláṣí, mo wọ́gilé ìsìn àṣálẹ́ àìsùn ọdún àti ìṣọ́ òòru - Sanwo-Olu
- Nàìjíríà ti ní Covid-19 variant - NCDC
- Ohun tí a mọ̀ nìyí nípa #IGotSurvivalFund owó ìrànwọ̀
- Wo ohun tí Pasuma sọ nípa Opeyemi, ọmọ rẹ tó di ọmọ ogun orí omi l'Amẹrika
- Àṣírí tú! Afurasí márùn ún pa Memunat Ẹlẹ́ja àti ọlọ́kadà, wọ́n pín ẹran ara wọn sí yẹ́lẹyẹ̀lẹ
O jẹ ọjọ ayọ
Nigba ti awọn Angẹli gan tun ṣe ikede yii, wọn bẹrẹ si ni ṣe ajọyọ, wọn n kọrin ayọ lati mọ ẹni naa ti yoo wa si aye fun alafia gbogbo eeya, ggẹ bo ṣe wa ninu ẹsẹ ikẹẹdogun ati ikẹrindinlogun Luuku keji.
"Bi awọn Angẹli ba lee ṣe eyi lati ṣe ajọyọ lori ẹni ti ko ni ẹṣẹ, tani ko ba tun maa yọ bi ko ṣe awọn eniyan lojoojumọ", Alufaa Murtala Mati Dangora to jẹ igbakeji aarẹ ẹgbẹ CAN ni ipinlẹ Kano.
Nitorinaa, idunu ati ayọ ṣe pataki fun gbogbo ẹda alaye lati ṣe ajọyọ ninu igbala Jesu Kristi.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọjọ ipinfunni
Ọjọ yii, gbogbo eeyan mọ wipe fifi ifẹ han si ara ẹni maa n waye.
O jẹ ọj to ṣe wipe bi oo ba tilẹ ni lati fun eeyan, gẹgẹ bii Kristẹni, o gbudọ hu iwa ifunni.
"Idi ni wipe ni ọjọ naa, Jesu Kristi jẹ ẹbun fun gbogbo araye to ta ẹjẹ rẹ silẹ fun ẹṣẹ wa".
Awọn amoye tu baagi wọn wọn si mu ẹbun oriṣiriṣi - Wura, Fadaka ati Ojia to jẹ ẹbun iyebiye gidi gan nitorinaa lasiko yii, a maa n ṣe ẹda iru iwa yii," Alufaa Alex Garba Shekau to jẹ Pasitọ ijọ kan ni Kano sọ bẹẹ.
Ọ̀rọ̀ dá lórí ogo Ọlọ́run
Ninu iwe Matthew 2:11 awọn amoye wolẹ niwaju ọm naa taa bi wn si fori balẹ fun un, oun lo tun jẹ awokọṣe fun wa.
Nitorinaa, o jẹ ọjọ fifi ogo Ọlọrun han ati gbigbe orukọ rẹ ga, ọjọ ti o yẹ ki gbogbo Kristẹni lọ si ṣọọ̀ṣi lọ sin Ọlọrun ni.
Eyi yoo jẹ apẹrẹ fun awọn ọmọlẹyin ati lati gbadura fun idariji ẹṣẹ gbogbo agbaye.
"10: Angẹli náà sì wí fún wọn pé, Má bẹ̀rù: sá wò ó, mo mú ìhìnrere ayọ̀ ńlá fún yín wá, tí yóò ṣe ti ènìyàn gbogbo".
O jẹ ọjọ alafia ati aiṣe ẹlẹyamẹya
Eyi kii ṣe asiko lati maa sọrọ ṣiṣe inunibini si awọn Kristẹni ati awọn ti kii ṣe ẹlẹsin Kristẹni, nitoripe igbala ti Jesu mu wa lọjọ naa, ko si ẹni to ṣe ininibini si i.
Torinaa, ọjọ ifẹ ati fifi ifẹ igbala han si ọmọlakeji ni ọjọ ayẹyẹ keresi.
Awọn adari ẹsin Kristẹni lo ba BBC sọ awọn ọrọ yii.















