Ogun Killing: Àṣírí tú! Afurasí márùn ún pa obìnrin àti ọlọ́kadà, wọ́n pín ẹran ara wọn sí yẹ́lẹyẹ̀lẹ

Àdá, àáké, ati fila pupa jẹ́ diẹ lara ami idanimọ awọn ẹgbẹ okunkun ni Naijiria
Àkọlé àwòrán, Àdá, àáké, ati fila pupa jẹ́ diẹ lara ami idanimọ awọn ẹgbẹ okunkun ni Naijiria

Awọn afurasi apaayan marun kan ni ọwọ ti tẹ nipinlẹ Ogun nibi ti wọn ti pa iyawo ile kan ati ọlọkada to gbe e.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun fi panpẹ ọba mu awọn maraarun ti Babalawo jẹ ọkan lara wọn fun ẹsun pe wọn pa Arabinrin kan, Memunat Akinde ati ọlọkada, Ibikunle Ajose.

Ni agbegbe Ado-Odo ni a gbọ pe nijọba ibilẹ Ota la gbọ pe o ti ṣẹlẹ lẹyin ti ikede gbode kan wipe awọn mejeji di awati ladugbo ni ọjọ kini oṣu kẹwa ọdun 2020.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi lo fi eyi hande ninu atẹjade rẹ l'Ọjọru ọsẹ.

Oyeyemi sọ pe lẹyin ti ọwọ tẹ awọn afurasi ọhun ni ọlọpaa tu aṣiri ohun to ṣẹlẹ gangan ti awọn oloogbe mejeji fi di awati.

Àkọlé fídíò, 'Mo kàn máa ń lọ́ ayẹyẹ kiri torí ijó láì ṣe pé wọ́n pe mí ló sọ mí di DJ olórin Fuji nìkan'

Agbẹnusọ ọlọpaa tun fi kun un wipe arabinrin Memunat to jẹ oniṣowo ẹja ati Ajose Ọlọkada gbera kuro ni ile Memunat ni agbegbe Idoleyin, Ado-Odo lati lọ si ọja kan nitosi lọ ra ẹja.

Gẹgẹ bi Oyeyemi ṣe sọ, Memunat pe Ajose ọlọkada pe ko wa gbe oun lọ si ọja ṣugbọn ko si eyi to pada sile ninu awọn mejeji.

O ni "eyi lo mu ki ọkọ arabinrin naa lọ fi ẹjọ sun ni agọ ọlọpaa Ado-Odo nibi ti wọn ti kọ akọsilẹ nipa iṣẹlẹ naa.

Nigba to ya ni wọn gbe ẹjọ naa lọ si ẹka ọtẹlẹmuyẹ aṣewadii eyi to si so eso rere nigba ti wọn ri ọkan lara awọn afurasi ọhun mu ni Badagry ti wọn si mu u.

Bi wọn ṣe ri i mu lo fa sababii mimu awọn mẹta mii, Akewusola Wajud, Ajaoba Monday ati Nupo Pona.

Àkọlé fídíò, 'Pásítọ̀ ló sọ fún mi pé Ọlọ́run pè mí láti di Olokun tó ń bọ omi'

Oyeyemi ni awn afurasi naa jẹwọ pe awọn pa Memunat ati Ajose, awọn si tu gbogbo paati ara wọn gẹgẹ bi Ọgbẹni Lebo kan ṣe pa wọn laṣẹ.

O fi kun un pe ile babalawo ni wọn ti ri ori arabinrin naa ti wọn ti ge e.

Agbẹnusọ ọlọpaa sọ fun awọn oniroyin pe awọn afurasi apaayan mẹrẹẹrin jẹwọ pe awọn n ṣiṣẹ fun ogbontarigi adigunjale kan ni ti wọn n pe ni Lebo.

Wọn sọ nipa awọn ara ilu kan ti wọn jigbe lọ sinu ile kan ti wọn ko tii kọ tan, so wọn mọlẹ ti wọn si pe ọga wọn pe iṣẹ ọhun ti jẹ..

Awọn afurasi maraarun naa ti wa ni atimọle ọlọpaa bayii ti wọn si ti kan lu agbami iṣẹ lati wa Lebo, ẹni ti wọn pe ni ọga wọn.

Oyeyemi jẹ ko di mimọ pe kọmisọna ti paṣẹ pe wn gbudọ gbe awọn afurasi ọhun de ile ẹjọ ki wọn si ri i daju pe wọn mu Lebo ati gbogbo awọn to ku ti wọn ba jọ lọwọ ninu iwa yii.

Àkọlé fídíò, 'Ọ̀lọ́pàá shátà mi láti Mowe dé Magboro dé Shagamu, wọ́n ní ṣé mi ò mọ̀ pé ìjọ́ba ni mo ṣiṣẹ́ fún'