Osaremen Okolo: Joe Biden tún yan ọmọbìnrin Naijiria sípò olùbádámọ̀ràn lórí Covid-19

Oríṣun àwòrán, OSAREMEN OKOLO/FACEBOOK
Oju ọjọ bi nkan yoo ti se ri laarin Naijiria ati Amẹrika bi Joe Biden ti wọn dibo yan ba dori oye tunbọ rọsọmu si pẹlu iyansipo ọmọ Naijiria si ikọ isakoso Biden.
Eni ti Biden sẹsẹ tun yan ni arabinrin Osaremen Okolo gẹgẹ bi ọkan lara awọn igbimọ isakoso idoju ija kọ arun Covid-19.
Ilu Massachusetts ni wọn bi Okolo si to si kawe gboye ni fasiti Harvard.
Gẹgẹ bi ohun ti Biden ati igbakeji rẹ ti wọn jijọ yan wọn sipo sọ, igbimọ isakoso idoju ija kọ arun Covid-19 yi yoo yara sisẹ lati se agbekalẹ ilana ti yoo dẹkun itankalẹ arun Covid 19 ti yoo si mu ki ara ilu ni igbagbọ ninu ijọba lẹẹkan si.
Ọmọ ipinlẹ Edo ni Naijiria ni baba Okolo, amọ ilu Massachusetts ni wọn bi si lọdun 1994.
O kawe gboye ni Fasiti Harvard lọdun 2017, lori imọ iṣegun oyinbo, ati imọ nipa awọn ọmọ ilẹ Africa to tun jẹ America.
Saaju ki o to darapọ mọ igbimọ igbejọba fun Biden, Okolo ti sisẹ gẹgẹ bi oludamọran agba lori ọrọ ilera fun asoju Illinois, Jan Schakowsky.
Biden ti yoo sẹ iburasipo logunjọ osu Kini ti saaju yan Adewale Adeyemo sipo gẹgẹ bi igbakeji akọwe ikowopamọ rẹ.
O tẹsiwaju pe "Okolo lo sagbatẹru agbekalẹ ati idunadura awọn aba ofin ti asofin naa fi sọwọ lori ilera araalu paapa julọ eyi to sọ laipẹ yi nipa ajakalẹ Covid-19''.
Kílódé tí Twitter fẹ́ jẹ ojú àwọn tó ń "follow" Trump kí wọ́n tó gbé Twitter ìjọba Amẹ́ríkà lé Biden lọ́wọ́?

Oríṣun àwòrán, Getty
Twitter ti fìdi rẹ mulẹ pe awọn eniyan miliọnu to n tẹle oju opo ile iṣẹ aarẹ ilẹ America lori Twitter kí oun to gbe fun ile aarẹ Joe Biden
Botilẹ jẹ pe ile awọn ile iṣẹ aarẹ ja fitafita lori igbesẹ yii sibẹ oludasilẹ ati oludari Twitter oun ko le yi ìpinnu naa pada.
Igbesẹ yii pẹlu paala laarin ijọba to n lọ ati eyi yo n bọ.
Lasiko ti Donald Trump gba ijọba lọwọ aarẹ tẹlẹ ri Barack Obama, Twitter gbe awon alatẹle kan naa fun Trump lọdun 2016.
Awọn oludibo ilẹ Amẹrika ti fi idi rẹ mulẹ pe alubolẹ ni Biden lu Trump ninu idibo to kọja.
- Ohun tí a mọ̀ nìyí nípa #IGotSurvivalFund owó ìrànwọ̀
- Wo ohun tí Pasuma sọ nípa Opeyemi, ọmọ rẹ tó di ọmọ ogun orí omi l'Amẹrika
- Nítorí COVID-19, Akeredolu, Oyetola, Abiodun, Fayemi wọ́gilé ayẹyẹ ọdún ní ìpínlẹ̀ Ondo, Osun, Ogun
- 'Irọ́ ni aráàlú pa, Amotekun kò yìnbọn pa èèyàn méjì ní Ibadan, a lọ bá wọn mú jàǹdùkú ni'
- Ìrẹsì ọ̀fadà, Ìkọ́kọre, àti àwọn oúnjẹ míì tóo lè fí gbádùn ẹ̀mí rẹ lásìkò Kérésì
"Ni ọdun 2016 ijọba Trump gba gbogbo oju opo twitter ijọba to kuro, iyẹn aarẹ Obama ati gnogbo awọn alatẹlẹ rẹ ni @POTUS ati @WhiteHouse eyi ni @team 44 fi n rọ twitter gẹgẹ bi adari ọrọ ayelujara fun Biden, Rob Flatherty se gbe soju opo rẹ lọjọ aje.
Ni ọdun 2020, Twitter ti fidi rẹ mulẹ pe ijọba Biden yoo bẹrẹ oju opo ile iṣẹ aarẹ tuntun.
E yii yoo kan awọn oju opo ijọba bii @POTUS ati @FLOTUS.
Twitter ni oun yoo jẹ ki awọn to n tẹle oju opo yii mọ layi le maa tẹle oju opo ijọba aarẹ tuntun, oun yoo si ko gbogbo awọn ọrọ wọn pamọ fun iwulo ọjọ iwaju.
Oju opo twitter Biden gan funra rẹ ti ni eniyan mọkanlelogun miliọnu, igbesẹ Twitter ko si ni se akoba fun.
Aarẹ Trump ti lo oju opo twitter lati ṣiṣẹ ijọba ati lati maa ṣiṣẹ ara rẹ ati lati ba awọn oludibo sọrọ
Lasiko to wa nile ijọba laarin ọdun merin rẹ, o ti kọ ọrọ to le ni ẹgbẹrun lọna aadọta soju opo twitter.
Ẹwẹ gẹgẹ bi Factbase se sọ, (oju opo to maa n ka iye ọrọ ti rnoyan ti kọ loju opo twitter) o ti le ni eniyan ẹgbẹrun lọna ọọdunrin ti ko tẹle Trump mọ loju opp Twitter rẹ lati inu osu kọkanla.
Lasiko kan naa ni awọn to bẹrẹ si ni tẹle Biden fi miliọnu meji le si
Ipinu Twitter waye lẹyin ọjọkan ti eeyan nla kan Jack Dorsey ko tẹle awọn oloselu kan mọ loju opo naa, to fi mọ Trump, Biden ati igbakeji aarẹ tuntun Kamala Haris.
" Onimọ nipa isowo ori ayelujara Rebecca Lodge ti ile isẹ Start Up Disruptors, to da si ọrọ naa ni alakatakiti ni ọpọ awọn to n tẹle Trump ati oju opo ile iṣẹ ijọba naa, igbesẹ twitter si dara ati pe eyi yoo mu ki awọn ọrọ ti ko bojumu loju opo naa kuro nibẹ ki aarẹ tuntun to gori alefa".


















