Mayowa Ayodele cab driver: Mi ò lè gbà kí ọmọ mi fẹ ọlọ́pàá láí láí

Àkọlé fídíò, 'Ọ̀lọ́pàá shátà mi láti Mowe dé Magboro dé Shagamu, wọ́n ní ṣé mi ò mọ̀ pé ìjọ́ba ni mo ṣiṣẹ́ fún'

"Bi mo ba ri ejo nilẹ ti mo ri ọlọpaa, maa mu ejo maa sa fun ọlọpaa Naijria".

Lẹyin to ni awọn ọlọpaa to ni koun wa gbe wọn lọ si ilu meji ko sanwo fun oun, Mayowa Ayodele ni wọn tun ti oun mọle lori ẹsun yii.

Gẹgẹ bi Mayowa to jẹ awakọ ni gareeji Mowe ṣe sọ fun BBC Yoruba, lọdun 2018 ni awọn ọlọpaa kan wa si gareeji ti wọn si nawọ si ọkọ oun pe oun lawọn fẹ, afi tọrọ di eyi ti Mayowa n kabamọ lonii.

Laipẹ yii, awọn ọmọ Naijiria ti n tu sita lati wa fi ẹsun kan nipa titu aṣiri iwa ibi tawọn ọlọpaa Naijiria hu si wọn lẹyin iwọde ifẹhonuhan #EndSARS to waye.

"Nigba ti mo ni ki wọn mu N4,500 ki n maa lọ, wọn ni ṣe mi o mọ pe ijọba ni mo ṣe iṣ fun ni". Lọrọ ba pesi jẹ lẹnu Mayowa.

O ṣalaye pe bi ọrẹ bi ọrẹ ni ọrọ naa ṣe bẹrẹ amọ bo ṣe wa gbe oun janto de ile ẹjọ ati atimọle so si oun lẹnu o bu iyọ si i.

Koda o ni wọn fi ẹsun kan oun nile ẹjọ, wọn ni oun n ṣiṣẹẹ jiji epo wa.

"Wọn gbe mi lọ ile ẹjọ, wọn ti mi mọle, mo tun pada de wọn ko gbe ọkọ mi silẹ titi ti mi o fi ri nkan fi bọ ẹbi mi mọ".

"Wọn yi oju mi sẹyin ogiri, wọn lu mi, wọn gba ọrọ lẹnu mi ti wọn fi yi ẹsun mọ mi lọrun".

Mayowa ni ọjọ mẹrindinlogun loun kọkọ lo latimọle ki wọn to gbe oun lọ ile ẹjọ ti wọn tun wa ti oun mọle pada toriipe ọkọ oun to dara wọ awọn ọlọpaa loju eyi ti wọn si pada n lo fun iwọde abo ilu lẹnu iṣẹ wọn.

Gbogbo igbiyanju Mayowa lati ba wọn fa ẹjọ́ naa pẹlu adajọ tirẹ, ibi to ja si ree lẹnu ọlọrọ gangan.