Animal accident: Arákùnrin kan dóòlà ẹ̀mí Erin tí alùpùpù gbá lójú pópó

Erin naa lẹyin to gba itọju

Oríṣun àwòrán, Photoshot

Ọmọ Erin kan ti alupupu gba loju titi ti ru u la lẹyin ti arakunrin kan doola ẹmi rẹ.

Ọgbẹni Mana Srivate ṣalaye fun ileeṣẹ akoroyin jọ Reauters pe oniruuru eto adoola ẹmi loun ti ṣe ninu irinajo iṣẹ oun-ṣugbọn oun ko ṣiṣẹ idoola ẹmi erin ri.

Fọnran fidio o to di gbajugbaja lori ayelujara, ṣafihan arakunrin naa nibi ti o ti n fi ọwọ mejeeji tẹ ara erin naa to ṣubu si aarin opopona kan.

Lẹyin iṣẹju marun ni erin naa dide.

Ọmọ erin naa n gbiyanju ati kọja loju opopona naa pẹlu awọn ẹranko ẹgbẹ rẹ kan lagbegbe Chanthaburi lorilẹede lorilẹede Thailand.

Bi awọn akẹgbẹ arakunrin naa ṣe n tọju arakunrin to gun alupupu to gba erin naa ni oun pẹlu n tọju erin ọhun funrarẹ.

Àkọlé fídíò, Justice Osei le dún bíi ẹranko 50
Àkọlé fídíò, Kollington ṣàlàyé bí orin Fuji ṣe bẹ̀rẹ̀ gan an ní Nàiìjíríà