Nigeria Customs: Ẹ̀ṣọ́ asọ́bode yìnbọn pa onífàyàwọ́, èèyàn méjì míì farapa nínú ikọlù Ayetoro

Oríṣun àwòrán, Facebook/Yemi Akintunde
Niṣe ni ibanujẹ gbalẹ kan ni adugbo Kikelọmọ ni ilu Ayetoro ipinlẹ Ogun nibi ti awọn ẹṣọ aṣọbode ti yinbọn pa eeyan kan ti eeyan meji mii si farapa.
Iṣẹlẹ yi ti kii ṣe akọkọ iru rẹ waye laarin awọn ẹsọ asọbode ati awọn kan ti wọn fura si pe wọn n ṣe owo fayawọ lagbegbe naa.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbola Oyeyemi, o fidi ọrọ naa mulẹ pe lootọ ni ikọlu yi waye.
Oyeyemi ni awọn gbọ iroyin pe awọn ẹṣọ aṣọbode nilu Ayetoro pa ọkan lara awọn onifayawọ to doju ija kọ wọn tawọn onifayawọ yi naa si ṣe ẹṣọ aṣọbode kan lese.
''Ọga ọlọpaa Ayetoro ati awọn DPO agọ ọlọpaa to wa lagbegbe naa ni Kọmiṣana ti ni ki wọn da alaafia pada si agbegbe naa''.
Ninu fọnran fidio kan ti ọkan lara awọn ọmọ ilu Ayetoro to si tun jẹ akọroyin pẹlu ileeṣẹ iroyin NTA,Yemi Akintunde pin soju opo Facebook rẹ, a ri ti awọn eeyan kan n gbe ẹnikan to ṣeṣe ku ti wọn si n sọ ninu fidio naa pe ọta ibọn lo ba a lẹsẹ.
BBC Yoruba ba aṣoju ẹkun idibo Imeko Afon/Egbado North Federal Constituency iyẹn aṣofin Jimoh Olaifa sọrọ to si ni lootọ ni iṣẹlẹ ọhun waye.

Oríṣun àwòrán, Google Maps
Olaifa ni awọn eeyan oun nile ti n pe lati fi ọrọ naa to oun leti ati pe iru iṣẹlẹ bayi ko ṣẹṣẹ maa waye lagbegbe naa.
''Nigbakigba ti iru nkan bayi ba ṣẹlẹ, lọpọ igba awọn to maa n farapa a maa wa lọna mejeeji. Fayawọ nibẹ a maa fẹ gbe ẹru wọn wọle lagbegbe naa ti awọn agbofinro yoo si maa kọ di wọn''
Olaifa ni awọn ti parọwa sawọn ọdọ lagbegbe naa pe ki wọn dẹkun fayawọ ṣugbọn nitori ti ọpọ ko niṣẹ lọwọ, eti ikun ni wọn kọ si arọwa yi.
Ayetoro jina si olu ilu ipinlẹ Ogun, Abeokuta ni iwọn kilomita marundinlogoji.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Olugbade Peter Ppex
O jẹ ọkan lara awọn agbegbe ti iṣẹ fayawọ to gbogo nitori pe ko jina si ibode Naijira ati Benin Republic.
Opopona Abeokuta-Imeko jẹ oju ọna kan ti eeyan yoo gba lati fi ja si Imeko lati Ayetoro.
Lẹyin Imekọ eeyan yoo kan Ilara ti ko jina si ala ibode Naijiria si Benin Republic.












