Ibadan clash: Rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ọlọ́kadà àti àwọn òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Ibadan

Rogbodiyan bẹ sile laarin awọn ọlọkada ati awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn n'Ibadan.
Ọrọ di boo lọ ki o ya fun mi lọwurọ ọjọ Iṣegun ni agbegbe gate nilu Ibadan nibi ti rogbodiyan ti bẹ silẹ laarin awọn ọlọkada ati awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn to n bẹ ni Agodi.
Ohun ti o ṣoju mi koro sọ ni pe ọkan lara awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn naa lo ṣekupa ọlọkada kan ti ọṣiṣẹ ọgba ẹwọn naa si fi ara pa ni agbegbe ti wahala naa silẹ.
Ọpọlọpọ awọn awakọ ati awọn eeyan to n fi ẹsẹ rin lo lọri pada si ibi ti wọn ti n bọ lati ti ọrọ naa di wọlukọlu.
Nibayii awọn oṣiṣẹ ọlọpaa ati ileeṣẹ ologun ti duro wamuwamu si gbogbo agbegbe naa titi ti o fi de agbegbe Total Garden.
Lasiko to n fi idi ọrọ naa mulẹ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ,
- Wo ohun mẹ́wàá tó yẹ kí o mọ̀ tí o bá fẹ́ lọ fún ìsinmi lẹ́yìn Covid 19
- Wo bí o ṣe lè ṣe eré ìdárayá tí yóò fún ọ ní adùn àti okun fún ìbálòpọ̀
- Iṣu ata yáan yàan! Iṣẹ́ fẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ọlọ́pàá tó gba N100k lọ́wọ́ awakọ̀ tó gba"One way" l'Eko
- Ìjọba Naijiria faraya nínú lẹ́tà tó kọ sí CNN lórí ìwádìí rẹ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki Toll Gate
Gbenga Fadeyi ṣe alaye pe lootọ ni ifanfa waye ni agbegbe naa, "ṣugbọn awọn ọlọpaa ati ẹṣọ aabo mii ti yọju sibẹ lati le mu ki alafia j'ọba".

Fadeyi fi kun ọrọ rẹ pe ọlọpaa ko yinbọn fun ẹnikẹni nibẹ tako iroyin to gba ori ayelujara kan wi pe ọlọpaa yinbọn nibẹ.

- Omotara pàdánù isẹ́ olówó ńlá nítorí ó fi ọtí ẹlẹ́rìndòdò sódà lá ọmọ alágbe lójú
- Ilé aṣòfin orílẹ̀-èdè UK ti faramọ́ fífí ìyà jẹ àwọn adarí Naijiria tọ lọ́wọ́ nínú rògbòdìyàn ENDSARS
- Jemila dáná sún ilé ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ àti ọ̀rẹ́bìnrin tó bá nílé
- Èyí ni ohun tí Ọọ̀ni sọ nípa Àrẹ̀mọ rẹ àti ètùtù tó ń ṣe lọ́wọ́

















