Ekiti Shooting: A ò ni farapamọ́ fún ará ìlú lórí ìwádìí ọlọ́pàá to pa ènìyàn ni Ekiti

Oríṣun àwòrán, Police
Kíni àjọ ọlọ́pàá ń ṣe lórí ìpànìyan ojoojúmọ́?
Agbẹnusọ ọlọ́pàá sàlàyé pé gbogbo ọ̀nà ni àjọ ọlọ́pàá ń gbà láti ri dájú pé, ìpànìyàn dínkù láàrín àwọn kọ̀lọ̀rọ̀sí láàrín àwọn ọlọ́paàá.
Ó fi kun pé, gbogbo ìgbà ni ọlọ́paàá ń se ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí bí wọ́n ṣe ńlo ìbọn àti àwọn ǹkan èlò míràn.
Lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, agbẹnusọ ọlọ́paàá sàlàyé pé, kò sí ǹka ti àjọ ọlọ́pàá yóò fi pamọ́ fún ará ìlú.
A ò ni farapamọ́ fún ará ìlú lórí ìwádìí ọlọ́pàá to pa ènìyàn ni Ekiti
Àwọn lánàá, àwọn lónìí bí ẹkún apọkọjẹ, bí a ṣe ń pàkan ní ọ̀kán ń rú ni ọ̀rs àwọn ọlọ́pàá orílẹ̀ -èdè Nàìjíríà.
Nínú ọ̀ṣẹ̀ tókọjá ni òkíkí kan pé ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀ṣọ́ tó ń tẹ̀lé abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin l'Abuja, Femi Gbajabiamila yìnbọn pa fẹ́dọ̀ kan ni Abuja.
Tuntun tó tún wáyé nínú ọ̀ṣẹ́ yìí ni ọlọ́pàá kan tó tún lọ yìnbọn pa ọ̀dọ́mọkunrin kan Olaoye Abayomi àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ Idris Adebayo tó n muti nílé ìtura kan nílùú Ado Ekiti.
Àsìkò yìí gan ni àwọn ọlọ́pàá mẹ́rin kan dé sí ọgbà ilé ìtura náà pẹ̀lú ọkọ̀ ọlọ́pàá tó ni Nọ́mbà PF 600- WSH.
Ọ̀kan nínú àwọn ọlọ́pàá náà sọ̀kalẹ̀ nínú ọkọ̀ wọ́n tó sì yìnbọ́n síbi táwọ̀n ènìyàn péjọ sí., Ọgbni Abayomi ni ìbọ́n ba ní ikùn nígbà tí ìbọ́n ba Adebayo ni ẹsẹ̀.
Ojú ẹsẹ̀ ni Adebayo kú gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ọ̀rọ̀ náà sojú wọ́n ṣe sọ, sùgbọ́n àwọn ọlọ́pàá tó kù sáré gbé Adebayo lọ sí ilé ìwòsàn, bẹ́ẹ̀ ni ọlọ́pàá tó yìnbọn na pápá bora.

Oríṣun àwòrán, others
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpińlẹ̀ Ekiti, ASP Abutu Sunday sàlàyé pé, ọlọ́pàá to ṣe iṣẹ́ aburu náà ti wa lagọ̀ọ́ ọlọ́pàá báyìí.
ASP, Sunday ni gẹ́gẹ́ bi ibi ti ìwádìí dé, kò sí ìja tàbi rgbòdìyàn tó le mú kí ọlọ́pàá náà yìnbọ̀n sùgbọ́n ìwádìí ṣi n lọ lọ́wọ́ láti mọ pàtó ìdí ti ọlọ́pàá náà fi yìnbọ̀n.


















